Idibo abẹle ẹgbẹ PDP Kwara daru patapata

Spread the love

Nitori eto idibo abẹle ẹgbẹ PDP to daru nipinlẹ Kwara, Dokita Bukọla Saraki ni oun ko gbe lẹyin oludije kankan bawọn eeyan kan ṣe n sọ  kiri.

Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin Aarẹ ile-igbimọ aṣofin agba naa, Ọgbẹni Yusuph Ọlaniyọnu, gbe jade lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, lẹyin ti idibo naa daru lo ti ṣalaye bi nnkan ṣe ṣẹlẹ.

Atẹjade naa sọ pe Dokita Saraki ti jẹ ko ye gbogbo awọn oludije funpo gomina nibi ipade to ba wọn ṣe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, pe oun ko fa oludije kankan kalẹ, bẹẹ loun ko ṣatilẹyin fun ẹnikankan lati jawe olubori ninu idibo abẹle naa.

O ni Saraki nigbagbọ ninu ẹni to ba kunju oṣuwọn, tawọn araalu si gba tiẹ lati bori idije ọhun. “Nitori bi Dokita Saraki ṣe ri i pe ọpọlọpọ awọn oludije naa lo ni awọn ohun amuyẹ lati ṣe gomina lo ṣe ni ki ẹgbẹ fun gbogbo wọn lanfaani lati kopa ninu idibo abẹle.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘Lẹyin tawọn ijọba ibilẹ meji ti dibo tan, tawọn ijọba ibilẹ kẹta n dibo lọwọ lawọn kan fẹdun ọkan wọn han tako ilana ti eto naa gba, ṣugbọn awọn to n ṣakoso sọ pe ki wọn dibo tan, awọn maa yanju ẹ. ṣugbọn ki wọn too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn janduku kan ti ya bo gbọngan ti idibo naa ti n lọ, ti wọn si da gbogbo ẹ ru patapata.

“Dokita Bukọla Saraki ti loun maa gba awọn aṣoju laaye lati yan ẹni to ba wu wọn to maa dije funpo gomina. Idi niyi to fi duro siluu Abuja lasiko ti eto idibo naa n lọ lọwọ. Kete to gbọ pe wọn ti da kinni naa ru lo gbera lati ilu Abuja ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Sannde naa lọ si Ilọrin”.

Eto idibo abẹle lati yan oludije funpo gomina l’ẹgbẹ PDP nipinlẹ Kwara daru lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, nigba tawọn aṣoju to wa lati ẹkun Ariwa Kwara fẹdun ọkan wọn han si ilana eto idibo naa.

Ṣeni gbogbo inu gbọngan ile ijọba, Banquet Hall, ti eto naa ti waye daru, tawọn aṣoju naa si n pariwo, “ole, ole, a o ni i gba” le awọn to n ṣakoso eto idibo naa lori.

Iwadii fi han pe awọn aṣoju to fibinu wọn han naa ti ri i pe awọn aṣaaju ẹgbẹ yii ti ṣe eto kan lati jẹ ki oludije kan to wa lati Aarin-Gbungbun Kwara jawe olu bori ninu idibo naa.

Titi di asiko ta a fi n kọ iroyin yii, awọn alakooso eto idibo naa ṣi n wa ọna lati pẹtu sawọn to n fapa janu ninu. Ju gbogbo rẹ lọ, ko ti i si esi kankan tabi oludije kan ti wọn kede pe o jawe olubori.

caption:Awọn aṣoju lasiko ti idibo n lọ lọwọ; Gbọngan ti idibo ti waye lẹyin ti wọn da a ru

 

 

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.