Idibo abẹle: APC Ekiti fọwọ si saa keji Buhari

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ekiti, ti dibo maa-ṣe-e-lọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣoju wọn ninu idibo aarẹ loṣu keji, ọdun to n bọ.

Kaakiri wọọdu mẹtadinlọgọsan-an (177) to wa nipinlẹ Ekiti nidibo itagbangba naa ti waye lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, nigba tawọn ti wọn yan lati ṣeto naa ko esi wa si sẹkiteriati ẹgbẹ to wa niluu Ado-Ekiti lọjọ keji ti i ṣe Satide.

Ibo abẹle taara, nibi ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ to ni kaadi idanimọ ti dibo, ni wọn ṣe, ọrọ ẹnu ni wọn si fi n sọ boya wọn fẹ Buhari lẹẹkeji abi bẹẹ kọ.

Nigba to di ọjọ Satide ni wọn bẹrẹ si i ka awọn ti sọ ‘bẹẹ ni’, o si pẹ ki wọn too ka a tan lọjọ naa, bo tilẹ jẹ pe o han gbangba pe ẹgbẹ naa ti fọwọ si Buhari.

Ọgbẹni Paul Ọmọtọṣọ to jẹ alaga ẹgbẹ naa l’Ekiti ati Ọgbẹni Ade Ajayi to jẹ alukoro sọ pe eto naa waye nirọwọ-rọsẹ, o si mọnyan lori.

Ọmọtọṣọ ṣalaye pe bi awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe tuyaaya jade lati dibo fun Buhari fi han pe wọn fẹ ko lo kọja ọdun 2019 nile ijọba, ati pe awọn ti ṣetan lati gba gbogbo aga to wa nile igbimọ aṣofin.

Awọn obinrin ti wọn yan ni: Oludamọran pataki lori eto ipawowọle tẹlẹ, Abilekọ Bunmi Adelugba (Emure); Oludamọran pataki fun iyawo gomina tẹlẹ, Abilekọ Yẹmisi Ayọkunle (Guusu Iwọ-Oorun Ekiti Kin-in-ni); Oludamọran pataki fun igbakeji gomina tẹlẹ, Abilekọ Kẹmi Balogun (Ado Keji); ati amugbalẹgbẹẹ igbakeji gomina tẹlẹ, Ọmọọba-binrin Tẹju Okuyiga (Gbọnyin).

Awọn mi-in ni: Amugbalẹgbẹẹ agba fun gomina lori iwadii ati akọsilẹ, Ọgbẹni Hakeem Jamiu (Irẹpọdun/Ifẹlodun Keji); akọwe agba feto ile ijọba tẹlẹ, Ọgbẹni Akin Ọṣọ (Ido/Osi Keji); alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Lateef Akanle (Ila-Oorun Ekiti Keji), ati alaga afunṣọ ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Tajudeen Akingbolu (Iwọ-Oorun Ekiti Kin-in-ni).

Awọn to ku ni: Ọgbẹni Oluwatoyin Lucas (Ado Kin-in-ni), Ọgbẹni Babatunde Lawrence (Ikẹrẹ Keji), Ọgbẹni Reuben Awoyẹmi (Ọyẹ Kin-in-ni), Ọgbẹni Yẹmi Ọṣuntuyi (Ọyẹ Keji), Ọgbẹni Adeoye Aribasoye (Ikọle Keji), Ọgbẹni Abiọdun Fawẹkun (Ido/Osi Kin-in-ni), Ọgbẹni Adejuwa Adegbuyi (Ila-Oorun Ekiti Keji), Ọgbẹni Johnson Adeoye (Iwọ-Oorun Ekiti Keji), Ọgbẹni Ọlatunji (Guusu Iwọ-Oorun Ekiti Keji), Ọgbẹni Adeyẹmi Ajibade (Mọba Kin-in-ni), Ọgbẹni Michael Arubu (Mọba Keji), Ọgbẹni Dele Ajayi (Isẹ/Ọrun), Ọgbẹni Tọpẹ Ogunlẹyẹ (Ilejemeje), Ọgbẹni Ademọla Ojo (Ijero) ati Ọgbẹni Fẹmi Akindele (Irẹpọdun/Ifẹlodun Keji).

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.