Idibo 2019: Ki Buhari ati ẹgbẹ APC maa palẹmọ lati gba ile wọn lọ -PDP

Spread the love

Awọn adari ẹgbẹ PDP lapapọ ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ APC lati palẹmọ ile wọn, nitori asiko ti to fawọn araalu lati paarọ ijọba lọdun 2019.

Ipe ọhun waye lọsẹ to kọja nigba ti ẹgbẹ naa ṣe ifilọlẹ ipolongo ibo aarẹ niluu Ilọrin.

Sẹnẹtọ Bukọla Saraki to jẹ adari igbimọ ipolongo ibo fun oludije PDP, Alhaji Atiku Abubakar, alaga apapọ ẹgbẹ naa, Uche Secondus, igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku  atawọn mi-in lo fi ipe naa ranṣẹ.

Saraki ke si awọn araalu lati fibo wọn le Buhari ati ẹgbẹ APC lọ, o ni ẹgbẹ naa ti ja awọn araalu kulẹ nitori gbogbo ileri ti wọn ṣe lọdun 2015 ni wọn ko mu ṣẹ.

“Ọ̣pọlọpọ ileri lẹgbẹ APC ṣe fun wa. Wọn lawọn maa pese aabo lasiko ti aabo mẹhẹ, ṣugbọn aisi aabo to peye tun ti waa tan kaakiri, o si ti tun buru ju ti tẹlẹ lọ.

“Ebi n pa araalu nitori ọrọ aje wa to ti dẹnukọlẹ. Wọn tun ti ja awọn araalu kulẹ nipa gbigbe ogun ti iwa jẹgudujẹra. A nilo aarẹ to le mu atunṣe ba orilẹ-ede yii”.

Bakan naa ni Atiku Abubakar ni orilẹ-ede Naijiria ti bajẹ kọja afẹnusọ lọwọ ijọba APC. Idi niyi tawọn araalu fi nilo ijọba ti yoo mu aye rọrun, ti yoo si mu igba ọtun ba wọn.

Oludije fun ipo aarẹ ni asiko ti to fawọn araalu lati pada sẹgbẹ PDP, nitori pe lasiko ti ẹgbẹ naa n ṣejọba lorilẹ-ede yii dara.

Alaga apapọ PDP, Uche Secondus, ni awọn orilẹ-ede yii ti n jiya tipẹ lọwọ APC to gbajọba lọdun 2015. O ni apẹẹrẹ ni bi wọn ṣe pa awọn eeyan nipinlẹ Benue ati Plateau, to si jẹ pe wọn ko ri afurasi kankan mu.

Secondus ni Atiku loye to fi le tukọ orilẹ-ede yii de ebute ogo to yẹ ko wa, ati lati mu ọrọ-aje rẹ gberu si i.

Alaga naa ni ajọ INEC yoo da wahala silẹ to ba gbiyanju lati yi esi idibo 2019. O nitori ọgbọn ti ẹgbẹ APC maa n da ni lati da wahala silẹ bi wọn ṣe ṣe nipinlẹ Ọṣun lati lo anfaani naa yi ibo.

Nibi eto naa ni wọn ti gbe asia ẹgbẹ fun oludije gomina nipinlẹ Kwara, Rasak Atunwa, atawọn ẹgbẹ rẹ lati awọn ipinlẹ mi-in.

 

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.