Idibo 2019: Ẹgbẹ PDP fẹẹ lo inagijẹ mi ‘MM’ lati tan awọn araalu jẹ ni -Moshood Mustapha

Spread the love

Ondupo gomina labẹ ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara, Moshood Mustapha, ti awọn ololufẹ rẹ tun mọ si ‘MM’, ti sọ lọsẹ to kọja pe oun ko mọ nipa posita oludije gomina  PDP, Rasak Atunwa, ti wọn kọ orukọ inagijẹ  oun ‘MM’ si.

Moshood ni awọn alatilẹyin oun jẹ ko ye oun pe ọkọ Sienna kan wa nigboro ti wọn lẹ posita Atunwa si, eyi ti wọn kọ ọ sara rẹ pe ‘MM’ lo ṣagbatẹru ọkọ ipolongo naa.

O ni ko si ariyanjiyan kan nibẹ pe oun nikan lawọn eeyan mọ si MM kaakiri gbogbo Kwara.

“Mo n lo anfaani yii lati sọ fun gbogbo araalu pe mi o ṣagbatẹru ọkọ ipolongo kankan ti wọn kọ MM si, ti aworan oludije PDP, Rasak Atunwa ati Rasak Lawal to n dije sile igbimọ aṣoju-ṣofin wa lara rẹ tawọn kan n gbe kiri igboro.

“Nitori naa, mo tun kede atilẹyin to gbopọn fun ẹgbẹ APC ati Aarẹ Muhammadu Buhari, oludije fun ipo gomina ẹgbẹ wa, Alhaji Abdulrahman Abdulrasaq, atawọn oludije wa yooku ninu eto idibo gbogboogbo ọdun 2019.

“Ohun to daju ni pe ẹni to ṣeru nnkan bẹẹ mọ-ọn-mọ ṣe e ni lati da ọkan awọn alatilẹyin mi ru, paapaa julọ awọn araalu to n reti lati lọ sipele giga (Next Level), lọdun 2019, lasiko ti ẹgbẹ APC ba gbajọba”.

O ke si awọn to wa nidii ẹtan yii lati jawọ ninu lilo apele oun, ‘MM’, lati maa da ọkan awọn araalu ru.

 

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.