Idi ti ọrọ oluṣiro owo agba to fẹyinti l’Ọṣun ṣe da awuyewuye silẹ

Spread the love

Ki i ṣe tuntun fun oṣiṣẹ ijọba lati fẹyinti, bẹrẹ lati igba to ba ti pe ọmọ ọgọta ọdun lẹnu iṣẹ, ṣugbọn ọrọ ifẹyinti oluṣiro owo agba funjọba ipinlẹ Ọṣun, Akintayọ Kọlawọle, ti di eyi ti awọn araalu, paapaa, awọn oloṣelu n gba bii ẹni gba igba ọti kaakiri bayii.

Ọjo kọkanla, oṣu karun-un, ọdun yii, la gbọ pe Kọlawọle kọwe si olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinle Ọṣun, Olowogboyega, pe oun ti pinnu lati fẹyinti pẹlu alaafia, bẹrẹ lati oṣu kẹjọ, ọdun yii, nitori ọjọ kọkanla, oṣu to kọja, naa loun yoo pe ọmọ ọgọta ọdun, ati pe oun ti lo ọdun mọkanlelogun lẹnu iṣẹ ọba.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu lẹta naa, inu oṣu keje, ọdun 1987, lo wọṣe ijọba labẹ ipinlẹ Ọyọ nigba naa, gbogbo wọn ni wọn si ko wọnu ijọba ipinlẹ Ọṣun nigba ti wọn kuro l’Ọyọọ. Ọdun 2012 ni Gomina Arẹgbẹṣọla yan an gẹgẹ bii oluṣiro owo agba funjọba, ko too kọwe ifẹyinti loṣu karun-un, ọdun yii.

Olowogboyega gba iwe ifẹyinti Kọlawọle yii, o si fi ṣọwọ si gomina ninu oṣu kẹfa, ṣugbọn a gbọ pe dipo ki gomina buwọ lu oṣu kẹjọ ti ọkunrin yii fẹ, ṣe ni gomina sọ pe anfaani tun wa fun Kọlawọle lati ba ijọba ṣiṣẹ di inu oṣu kẹwaa, ọdun yii, gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba to mọṣẹ doju amin.

Bo ṣe di ọjọ Tọsidee to kọja ni Kọlawọle digba-dagbọn, o palẹ ohun to jẹ tiẹ ninu ọfiisi mọ, bẹẹ lo kọ lẹta si gbogbo awọn banki tijọba ipinlẹ Ọṣun n lo patapata pe, bẹrẹ lati ana Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan-an, wọn ko gbọdọ san owo fun iwe sọwedowo kankan ti ẹnikẹni ba mu wa lorukọ oun, nitori oun ki i ṣe oluṣiro owo agba fun ijọba mọ.

Ọrọ yii lo da wahala silẹ, ti onikaluku si bẹrẹ si i sọ ero ọkan wọn lori ohun ti ọkunrin yii le ri lọbẹ to fi waro ọwọ. Gbogbo igbiyanju wa lati ba baba yii sọrọ ni ko so eso rere, ko gbe foonu Glo rẹ bi a ṣe pe e to titi ti ilẹ fi ṣu lọjọ Sannde, nọmba MTN rẹ o kan tiẹ lọ rara, bẹẹ ni ko fesi si atẹjiṣẹ ti a fi ranṣẹ sori foonu rẹ.

Ṣugbọn iwadii wa fi han pe ọrọ naa le ni nnkan an ṣe pẹlu owo to le ni biliọnu mẹrindinlogun Naira ti aṣiri tu laipẹ yii pe ijọba apapọ dọgbọn ko fun ipinlẹ Ọṣun ninu owo Paris Club lai jẹ ki awọn gomina to ku mọ.

A gbọ pe ṣe ni Aarẹ Buhari fẹẹ fi owo naa bo Gomina Arẹgbẹṣọla laṣiiri lati le fi san obitibiti gbese owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn nigba ti Kọlawọle ri i pe idibo gomina nijọba ti pinnu lati na owo ọhun le lori lo ṣe tete gbe ori rẹ sa.

Gẹgẹ bi ẹnikan to sunmọ ọkunrin oluṣiro owo agba naa, to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣe sọ, o ni ki i ṣe igba akọkọ niyẹn tijọba ipinlẹ Ọṣun yoo lo owo to yẹ fun iṣẹ kan fun omi-in lai gba imọran awọn akọṣẹmọṣẹ nidii eto owo ti wọn n ba a ṣiṣẹ.

Ẹni naa fi kun ọrọ rẹ pe owo to de yii yoo di wahala nla ti oludije fẹgbẹ oṣelu APC ko ba rọwọ mu ninu idibo gomina to n bọ lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, yii, idi niyẹn ti oluṣiro owo naa fi gba imọran kaakiri, ti awọn mọlẹbi rẹ si sọ fun un pe ti ko ba fẹẹ maa fi irun funfun pooyi kootu, ko tete kọti ikun si anfaani ‘arumọjẹ’ ti gomina gbe siwaju ẹ.

Bi awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun naa ṣe gbọ nipa igbesẹ oluṣiro owo agba yii ni wọn ti kede pe ki iyanṣẹlodi tawọn figi gun bẹrẹ lọtun lana-an, ọjọ Aje. Wọn ni niwọn igba to jẹ pe tori awọn nijọba apapọ ṣe fun Ọṣun lowo Paris Club, Arẹgbẹṣọla gbọdọ san gbogbo gbese owo-oṣu ati ajẹmọnu to jẹ awọn ki wọn too dibo.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni tiwọn sọ pe iwa ọdaju ni bi Gomina Arẹgbeṣọla ṣe fẹẹ lo owo to tọ si awọn oṣiṣẹ naa fun ipolongo ibo gomina.

Gẹgẹ bi atẹjade kan lati ọwọ alukoro ipolongo ibo gomina fẹgbẹ naa, Bamidele Salam, ṣe sọ, o ni bii igba teeyan n ko pankẹrẹ bo ẹṣin to ti ku ni ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun jẹ. O ni ko si iye owo ti wọn le na lori idibo yii ti yoo mu kawọn araalu dibo fun wọn.

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.