Idi ti ọpọ aboyun Naijiria ṣe n ku lọjọ ikunlẹ- NURHI

Spread the love

Ni Naijiria lonii, awọn aboyun to n ku sori ikunlẹ ko din ni ọtalelẹẹdẹgbẹta ati mẹwaa (570) ninu ẹgbẹrun mẹwaa aboyun to n gbiyanju lati bimọ.

Àdaadatan ẹjẹ atawọn sábàbí mi-in to maa n ran aboyun lọ sọrun lọjọ ikunlẹ lo n fa a. Bẹẹ ni ile ọmọ obinrin mi-in n bẹ bii ọra burẹdi ti wọn fẹ atẹgun to pọ kọja agbara ẹ si ninu.

Iwọnyii di mimọ nibi idanilẹkọọ ti ajọ to n ri si ifeto-sọmọ-bibi (NURHI) ni ipinlẹ Ọyọ ṣe fawọn oniroyin nipa ọna ti wọn le maa gba fọnrere pataki ifeto-sọmọ-bibi fawọn eeyan orileede yii, eyi to waye nileetura kan nitosi Mọkọla, n’Ibadan, laipẹ yii.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin wa lẹyin idanilẹkọọ ọlọjọ mẹta ọhun, Ọgbẹni Tunji Samuel to jẹ alakooso agba lori awọn eto gbogbo fun ajọ naa ni ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe, ”A gbe NURHI dide nitori pe iku obinrin lasiko ti wọn n bimọ lọwọ pọ ju. Ta a ba ri awọn obinrin ti wọn n bimọ leralera ti wọn ko fi alafo si i, o lewu.”

Lara nnkan to sọ pe o tun le ṣokunfa iku obinrin lọjọ ikunlẹ ni ki eeyan fi ọmọ kekere ara bimọ, awọn majeṣin bii ọmọọdun mejila mẹtala; ki obinrin maa bimọ leralera lai fi alafo silẹ to laarin ọmọ kan si ikeji.

O ni apọju ọmọ, iyẹn ki eeyan ṣaa maa pa ọmọ jọ sile ṣaa bii eku ẹdá lewu pupọ, nitori iru nnkan bẹẹ le ba ile ọmọ obinrin jẹ. Bẹẹ lo ni ko daa to lati maa fi arugbo ara bimọ.
Ọmọbonikẹẹ Adebayọ to jẹ alamoojuto alakooso eto iroyin ajọ NURHI ipinlẹ Ọyọ gba pe wahala lẹni ti ko feto sọmọ bibi n fa sinu aye ara ẹ nitori ọna kan ṣoṣo lati fun idile ẹni lalaafia ni lati ni eto fun bi wọn ṣe n bimọ, nitori ọmọ bẹẹrẹ, oṣi bẹẹrẹ ni.
O ṣalaye pe oriṣiiriṣii ilana ifetosọmọbibi lo wa. Ko si ẹni kan laye yii ti ọkan ninu awọn ilana yii ko ni i ba lara mu. Eeyan si le pa ilana ifetosọmọbibi to ba yan laayo ti nigbakuugba ti oyun ba tun n wu u lati ni, ki ẹni yẹn si tun tẹsiwaju pada to ba ti bimọ tan. O ni eleyii maa n gba eeyan silẹ lọwọ oyun itiju, ki i jẹ ki eeyan ṣeesi loyun lasiko ti oyun ko wu u ni. O ni awọn to n feto sọmọ bibi ni ipinlẹ Ọyọ ti pọ si i lati igba ti NURHI ti de ipinlẹ Ọyọ.

Adari ajọ NURHI ni ipinlẹ Kaduna, Mallam Kabiru Muhammad Abdullahi fi oju ẹsin Islam wo ifetosọmọbibi ninu ifọrọwerọ tiẹ naa pẹlu akọroyin wa, o ni eto naa ki i ṣe ohun ti ẹsin Islam lodi si gẹgẹ bii igbagbọ awọn eeyan kan, paapaa awọn ẹya Hausa ati Fulani.
O ni nnkan ti Islam ko kan faramọ ni ki eeyan fẹẹ fi gbedeke si i pe iye ọmọ bayii pato ni mo fẹẹ bi lai si ohun pataki kan to fa a. Ọna ti Islam gba faaye silẹ fun eeyan lati da ọmọ bibi duro ni ti eeyan ba ri i pe o lewu fun obinrin lati maa bimọ. Bii apẹẹrẹ, obinrin to jẹ pe iṣẹ abẹ ni wọn n ṣe fun un to ba fẹẹ bimọ, o yẹ ki iyẹn da ọmọ bibi duro.

Abdullahi ni ki awọn adari ẹsin ba awọn ọmọ ijọ wọn sọrọ pe anfaani wa ninu ifetosọmọbibi. Obinrin to ba jẹ pe gbogbo igba to ba n bimọ lo maa n kan iyọnu kan tabi omi-in, to jẹ pe Ọlọrun lo maa n pada doola ẹmi wọn. Iru wọn ni lati feto sọmọ bibi.

(55)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.