Idi ti a fi gbe ipade itagbangba kalẹ fawọn oludije l’Ọṣun – Ọlọfinṣawo

Spread the love

Olootu agba fun ileeṣẹ BBC Yoruba lorilẹede yii, Temidayọ Ọlọfinṣawo ti sọ pe lati le mu ki awọn araalu fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu awọn oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun lede abinibi ni awọn ṣe ṣagbekalẹ eto ipade itagbangba to waye lopin ọsẹ to kọja

Nibi ipade naa ni mẹrin ninu awọn oludije marun-un ti wọn fiwe pe ti yọju. Awọn mẹrin ti wọn wa ni Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore to n ṣoju ẹgbẹ oṣelu SDP, Alhaji Fatai Akinade Akinbade, ti ẹgbẹ oṣelu ADC, Alhaji Moshood Adeoti, ti ADP, ati Alhaji Isiaka Adegboyega Oyetọla, ti ẹgbẹ APC fa kalẹ, nigba ti oludije fẹgbẹ PDP, Ademọla Adeleke ko wa.

Gbogbo awọn oludije naa ni awọn atọkun eto ọhun, eleyii to waye ninuu gbọngan Ọlagunsoye Oyinlọla to wa niileewe UNIOSUN, niluu Oṣogbo, atawọn araalu lanfaani lati beere ibeere lọwọ wọn, ti awọn oludije yii si sọ erongba wọn ati idi ti wọn fi ro pe o yẹ ki awọn araalu dibo fun awọn.

Lẹyin eto naa, Ọlọfinṣawo ni inu oun dun fun aṣeyọri ti ileeṣẹ BBC Yoruba ni lori eto to jẹ akọkọ iru ẹ nipinlẹ Ọṣun ọhun. O ni erongba ileeṣẹ naa ni lati ṣagbekalẹ anfaani ijọba to ni ipa fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.

O ni eto naa fun awọn oludibo lanfaani lati ba awọn oludije fun ipo gomina sọrọ lede abinibi, ti awọn oludije kọọkan si sọ oniruuru eto ti wọn ni nipamọ, eleyii ti awọn eeyan yoo fi maa pe wọn nija ti wọn ba de ori aleefa.

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.