Idaamu Yẹmi Ọṣinbajo

Spread the love

Wn lo ṣ’owo Naijiria bauau nigba ti Buhari ko si nile

Ọlọrun nikan lo mọ bi Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, yoo ṣe ṣe e ti yoo fi bọ lọwọ awọn alatako ti wọn n sọ pe dandan ni ki wọn yọ ọ nipo to wa yii, ati awọn ti wọn n sọ pe dandan ni ki wọn ba a ṣẹjọ. Awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin agba ti sọ pe pasitọ naa ni alaye rẹpẹtẹ lati ṣe fawọn ọmọ Naijiria lori ọrọ owo kan ti wọn ni wọn na ni inakuuna lasiko to n ṣe adele aarẹ Naijiria loṣu kẹfa, ọdun to kọja. Bawọn kan ti n sọ pe biliọnu mẹtalelọgbọn Naira (N33B), lowo naa, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe eyi to kan Ọṣinbajo ju ni biliọnu mẹfa o din diẹ (N5.8b), to jẹ oun funra rẹ lo ṣeto bi owo naa ti jade. Ju gbogbo rẹ lọ, ọpọ awọn eeyan ti dide bayii ninu awọn alatako, atawọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin paapaa, awọn ni bi Ọṣinbajo yoo ba ṣe bii pasitọ tootọ, ko fi ipo rẹ silẹ lo dara.

Ki lo de gan-an?

Ileeṣẹ kan wa ti wọn n pe ni NEMA, National Emergency Management Agency, ileeṣẹ naa lo maa n ri si ọrọ ijamba tabi ajalu to ba ṣẹlẹ nibikibi ni Naijiria. Bi ina rẹpẹtẹ ba jo odidi ilu kan, tabi awọn Boko Haram le awọn eeyan jade, abi ogun deede ja apa kan Naijiria, ileeṣẹ NEMA ni yoo sare lọ sibẹ, ti wọn yoo si ṣe itọju awọn ti ajalu naa ba ba. Nibi ti iṣẹ NEMA pọ si ju bayii ni agbegbe Ariwa Naijiria, iyẹn ilẹ Hausa, nibi tawọn Boko Haram, ti n yọ wọn lẹnu. Loootọ ileeṣẹ naa ni adari agba (Director General), Alaaji Mustapha Maihaja, to n ṣe kokaari gbogbo eto nibẹ, ṣugbọn Ọṣinbajo ni olori igbimọ apaṣẹ ileeṣẹ yii, kọbọ kan ko gbọdọ jade sita ti ko ba fọwọ si i, bẹẹ ni eto nla yoowu ti igbimọ naa ba fẹẹ ṣe, ti igbakeji aarẹ naa ko ba ti ni ki wọn ṣe e, wọn o gbọdọ dan an wo.

Ileeṣẹ NEMA yii lawọn owo nla nla waa sọnu nibẹ, n lawọn eeyan ṣe n pariwo Ọṣinbajo, wọn ni ko waa sọ bo ṣe jẹ, nigba to jẹ oun lolori wọn. Ẹni kan ninu awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti wọn n ri si ọrọ ileeṣẹ NEMA lo sọ fawọn ẹlẹgbẹ rẹ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji, ọdun yii, pe ọrọ awọn NEMA yii ko ma ye oun mọ, owo nla nla ma n sọnu nibẹ, n ni gbogbo ile-igbimọ ba kuku ni ki wọn lọọ wadii ohun to n ṣẹlẹ wo ki awọn gbọ, ki awọn le mọ ohun ti awọn yoo ṣe bo ba jẹ loootọ. Ohun to hu ariwo yii jade ni pe ijọba orilẹ-ede Ṣaina (China) fi ẹgbẹrun lọna mejilelọgọjọ o le diẹ (162, 696), apo irẹsi ta awọn ti Boko Haram ti sọ di alarinkiri ni agbegbe Borno lọrẹ, ileeṣẹ NEMA si gba irẹsi yii, wọn ko gbe e de ọdọ awọn ti ọrọ kan, wọn pin in mọ ara wọn lọwọ ni, ko de ọdọ awọn tawọn Ṣaina fun rara.

Bawo leeyan yoo ṣe ṣe bẹẹ, nigba to jẹ awọn ipinlẹ mẹfa ti Boko Haram ti n yọ wọn lẹnu ju ni wọn ni ki wọn ko irẹsi naa fun, awọn ipinlẹ naa si ni Borno, Yobe, Adamawa, Gombe, Bauchi ati Taraba. Iyẹn ni wọn ṣe pe olori ileeṣẹ NEMA, Maihaja, pe ko waa ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ. Oun lo sọ pe awọn ko tete ko irẹsi naa kuro ni ibudokọ oju omi ni, bo si tilẹ jẹ pe apapọ iye owo irẹsi naa jẹ irinwo miliọnu Naira (N400m), sibẹ, owo ti awọn na gẹgẹ bii owo itọju-ẹru naa nibudokọ to de si, ẹgbẹrin miliọnu owo Naira ni (N800m), ko si si ohun to fa gbese bẹẹ ju pe awọn ko tete ko o kuro ni ibudokọ to de si lọ. Loootọ si ni, nitori lati inu oṣu kẹfa, ọdun 2017, ni irẹsi naa ti de si ibudokọ oju omi, wọn ko si ko o kuro nibẹ titi di bii oṣu kẹfa, ọdun yii, nigba ti wọn si ko o kuro nibẹ ni ẹni kan ko mọ bo ṣe wọlẹ.

Yatọ si eleyii o, ọpọlọpọ awọn owo nla nla mi-in bẹẹ lo n wọlẹ si ileeṣẹ NEMA yii, to jẹ bo ba ti balẹ bẹẹ, ko sẹni ti yoo mọ bi owo naa ti ṣe poora. Owo kan wa ti wọn ni ki NEMA pin fawọn ipinlẹ ti omiyale ati iji-lile yọ lẹnu, ọgọrun-un miliọnu fun ipinlẹ kan, tipatipa lawọn mi-in fi ri idaji owo naa gba, bẹẹ ipinlẹ mẹrindinlogun ni gbogbo wọn. Awọn yii ni Eko, Edo, Kwara, Ọyọ, Ebonyi, Niger, Ekiti, Kebbi, Akwa-Ibom, Plateau, Sokoto, Bayelsa, Enugu, Ondo, Abia ati Abuja. Bo tilẹ jẹ pe lati inu oṣu kẹfa, ọdun 2017, lowo naa ti wa lọwọ NEMA, awọn ipinlẹ mi-in ko ri idaji owo naa gba titi di oṣu kẹta ọdun yii, awọn ọga NEMA n fi owo naa pawo, wọn si ji eyi to ku ko sapo ara wọn ni. Bẹẹ lawọn owo mi-in tun sọnu bẹẹ, apapọ rẹ si ni biliọnu mẹtalelọgbọn (N33B), ti wọn sọ.

Gbogbo eleyii to n ṣẹlẹ yii, labẹ ofin, ko gbọdọ ṣe ẹyin Ọṣinbajo, nigba to jẹ oun ni olori igbimọ apaṣẹ fun ileeṣẹ yii, to si jẹ kọbọ kan ko gbọdọ jade lai jẹ pe o fọwọ si i, bẹẹ lo si gbọdọ mọ ohun ti wọn fẹẹ fi owo naa ṣe, ati bi wọn ṣe na an lẹyin ti wọn gba a tan. Ohun ti wọn fi n pariwo ọkunrin naa niyẹn. Ṣugbọn ọkan wa to kan an gbọngbọn, iyẹn si le diẹ. Ninu oṣu kẹfa, ọdun to lọ (2017), yii naa ni. NEMA ni wọn tun ni o fẹẹ nawo kan ni pajawiri, owo naa si jẹ biliọnu mẹfa o din diẹ (N5.865b), ko si si Buhari nile, Ọṣinbajo lo wa nipo aarẹ. N ni wọn ba kọwe lati ọfiisi rẹ, iwe naa si jẹ aṣẹ ti Adele-Aarẹ naa fọwọ si funra rẹ fun Kẹmi Adeọṣun to jẹ minisita eto inawo nigba naa, niyẹn naa ba paṣẹ ranṣẹ si Central Bank pe ki wọn gbe owo naa jade kia. Owo yii lo di idaamu Ọṣinbajo.

Idi ni pe Ọṣinbajo ko laṣẹ lati gbe iru owo bẹẹ jade bi ko ba jẹ pe awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti fọwọ si i fun un. Lọna keji, ibi to sọ pe ki wọn ti mu owo yii jade wa ki i ṣe owo ti wọn gbọdọ fi ọwọ kan rara, nitori ile-igbimọ aṣofin ti fọwọ si owo naa fun nnkan mi-in ti ko ba ileeṣẹ NEMA lọ. Lọna kẹta, nigba to jẹ Ọṣinbajo ni olori pata fun awọn NEMA yii, to si jẹ oun naa lo tun fẹẹ fọwọ si iwe owo ti wọn fẹẹ na yii, ẹtọ ni fun un lati jẹ ki ẹni-kẹta tabi ileeṣẹ ijọba kẹta da si i, ko ma jẹ oun lo fẹẹ nawo, oun naa lo tun fọwọ si i funra rẹ. Wọn ti beere lọwọ Ọṣinbajo pe ki lo de to ṣe bẹẹ, oun ni nitori pe ọda ounjẹ ati owo da awọn eeyan naa loun ṣe ṣe bẹẹ, ti oun si ni ki wọn fun wọn lowo ati ounjẹ lai fi akoko ṣofo rara. Ṣugbọn awọn eeyan ni ki lo de ti wọn ko ṣe bẹẹ nigba ti Buhari wa nile, ati pe ki lo de ti ko gbe ọrọ naa dewaju awọn aṣofin koda, ki Buhari ma si nile.

Ibinu tun wa ninu bi wọn ṣe pin owo naa, nitori lati Central Bank ni wọn ti pin owo naa fawọn ileeṣẹ marun-un kan, eleyii ti ko ba ofin mu rara, nitori Central Bank ki i sanwo fun araata, banki ijọba apapọ ni, afi owo laarin ijọba kan sijọba kan, tabi si ileeṣẹ ijọba mi-in. Ṣugbọn Ọṣinbajo faṣẹ si i ki banki pin owo naa fun ileeṣẹ Dangote Rice, Golden Agric Input, BUA Rice Ltd.,WACOT Limited, ẹẹmeji si ni ileeṣẹ WACOT yii gbowo. Ileeṣẹ NEMA to jẹ ti awọn Ọṣinbajo naa tun gba ninu owo yii o, awọn na an radarada, bii owo pakejin (Packaging), owo irin-ajo, owo akiiṣeemọ (contigencies) ni wọn fi ẹgbẹrin miliọnu owo Naira (N800m), ti wọn gba ninu owo naa ṣe.

Eyi lawọn aṣofin ṣe taku pe ọmọwe ni Ọṣinbajo, o si mọ nipa ofin daadaa, ko le sọ pe oun ko mọ nipa ofin to de owo nina, bẹẹ ni ko le pe oun ko mọ bowo ṣe n sọnu nileeṣẹ NEMA, awọn kan si n sọ pe ajọṣe buruku kan wa laarin oun ati ọga agba NEMA yii, bẹẹ ni oun ati Kemi Adeọṣun ni kinni kan ti wọn jọ ṣe papọ ni ti owo ti wọn gbe jade lojiji nigba ti Buhari ko si nile yii. Ile-igbimọ aṣofin agba ti ni awọn yoo da si ọrọ yii, awọn ajijagbara si ti n gbara jọ. Ẹgbẹ PDP ni ki Oṣinbajo lọ si ṣọọṣi ko tọrọ idariji pe oun ko owo jẹ, ko si ko owo naa kalẹ kia. Ọrọ naa tobi diẹ fun APC, wọn o ti i le fesi, ohun to fẹẹ ṣẹlẹ gan-an ko si ti i ye ẹni kan. Idaamu ni kinni naa fun Ọṣinbajo, bi yoo ti yọ ninu rẹ lẹni kan ko ti i le sọ.

 

 

 

 

 

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.