Idaamu Ibikunle Amosun Wọn gba akoso ẹgbẹ lọwọ rẹ nipnlẹ Ogun Lo ba n sare kiri

Spread the love

Ki i ṣe asọdun, ki i si i ṣe ohun tuntun mọ, pe ajọṣepọ to dan mọran lo wa laarin Aarẹ Mohammadu Buhari ati gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun.

Ki Buhari too di aarẹ rara ni ajọṣepọ ti wa laarin wọn, inu ẹgbẹ oṣelu kan naa ni wọn ṣi jọ wa, iyẹn ANPP, ko too di pe awọn mejeeji darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC to pada gbe Buhari wọle.

Koda, lọdun 2011 ti Buhari ṣi wa ninu ẹgbẹ oṣelu CPC to fẹẹ dije du ipo aarẹ, ile Amosun ni ọkunrin naa ti gba awọn oniroyin lalejo, ibẹ ni ero si n wọ lọọ ba a ati ẹni to fẹẹ fi ṣe igbakeji rẹ lasiko ọhun, Pasitọ Tunde Bakare.

Idi niyi ti ko ṣe jọ awọn eeyan loju nigba ti okun ọrẹ wọn tun yi dain-dain si i nigba ti Buhari di aarẹ Naijiria, ti Amosun naa si di gomina ipinlẹ Ogun lẹẹkeji.

Ọpọ eeyan lo mọ pe ko si ohun ti Amosun gba to gba ti lọwọ Buhari, bi ẹnikan ba si fẹ ojuure Aarẹ ọhun nilẹ Yoruba yii ati lawọn ibomi-in, bo ba ti sọ fun Amosun, eyi to ku kere, nitori ọkunrin naa mọ bi yoo ṣe gbe ọrọ naa de eti Aarẹ ti yoo si gba ohun to ba fẹ kuro nibẹ. Ko sibi ti Aarẹ n lọ ti o maa n ṣẹyin Amosun, ko si ohun ti ọkunrin naa si n ṣe ti ko ni i pe e sibẹ.

Gbogbo ohun ti awọn eeyan ri niyi ti ọpọ fi n sọ pe ko si iṣoro ti o le koju gomina yii nipinlẹ to ti n ṣejọba nitori ko si ohun to fẹ ti ko ni i to o lọwọ, bi iṣoro ba si fẹẹ wa paapaa, bo ba ti pe Aarẹ lọwọ kan, ohun gbogbo yoo yanju.

O jọ pe eyi ni gomina to maa n de fila onilegogoro yii gbọkan le to fi kọyin si ọpọ awọn aṣaaju ẹgbẹ rẹ nilẹ Yoruba ti ajọṣe ti wa laarin wọn tẹlẹ. Aarin oun ati gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, ko fi bẹẹ danmọran, Ọṣọba paapaa ti binu fi ẹgbẹ oṣelu ti wọn jọ wa silẹ ko too pada laipẹ yii lẹyin ọpọlopọ arọwa lati ọdọ ọkan ninu awọn aṣiwaju wọn, Oloye Bọla Tinubu.

Nitori awọn alagbara ti Amosun n ba ṣe ati nitori pe gẹgẹ bii gomina, oun ni apaṣẹ, oun si ni aṣaaju ẹgbẹ oṣelu rẹ nipinlẹ rẹ ni wọn ko fi lero pe o le ni iṣoro kankan lasiko eto idibo ọdun 2019. Wọn gbagbọ pe ẹnikẹni ti gomina yii ba fa kalẹ ni yoo wọle si irufẹ ipo to ba fẹ ko wọle si. Eyi naa lo si fa a ti ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ fi n rọ lọ sọdọ rẹ lojoojumọ, nitori onikaluku naa lo n fẹ ẹni ti yoo tẹle ti erongba rẹ nidii oṣelu yoo fi di mimuṣẹ.

Bi eto idibo abẹle lati yan ẹni ti yoo dipo gomina mu lọdun to n bọ ṣe n sun mọle ni Amosun ti fi n da awọn eeyan loju pe oun mọ ẹni ti yoo di ipo naa mu, agbegbe Yewa ti wọn si ti n pariwo pe awọn fẹ ki ọmọ awọn naa ṣe gomina ni oun yoo ti mu oludije yii.

Bẹẹ naa lo sọko ọrọ si awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn kan nigba naa pe oun ni olori ati aṣaaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun, ẹnikan ko le wa lati ibi kan ko waa gbe ẹni ti awọn ko fẹ tabi ti ki i ṣe oloṣelu ipinlẹ naa le awọn lori. O fi da gbogbo eeyan loju pe oun loun yoo yan ẹni ti yoo ṣe gomina.

Koda, nibi ti ọrọ yii da a loju de, ni asiko ọdun Ileya tawọn Musulumi ṣe kọja, ọkunrin yii ṣeleri pe lọdun to n bọ, oun ati ẹni ti oun fọwọ si ti yoo di ipo gomina ipinlẹ Ogun mu ti oun ba kuro nibẹ lawọn yoo jọ wa si yidi ọhun.

Gbogbo aṣamọ yii si dopin ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, nigba ti gomina naa kede pe Adekunle Akinlade ni oun yoo ṣe atilẹyin fun lati du ipo gomina ipinlẹ Ogun gẹgẹ bii ileri oun pe ọmọ bibi adugbo Yewa loun yoo gbe ijọba fun.

Kia lo si kede pe awọn ko ni i lo eto idibo mi-in to ju pipanupọ lati fa ọmọ ẹgbẹ kalẹ lati dupo kọọkan lai ṣeto idibo abẹle kankan lọ. Bẹẹ ni oun atawọn ọmọ ẹgbẹ APC kan si kora wọn jọ lọjọ kẹwaa, oṣu to kọja, o si kede awọn ti wọn ti mu lati ṣoju agbegbe kọọkan. Akinlade ni yoo ṣe gomina, ọkan ninu awon komiṣanna rẹ, Adepeju Adebajo ni yoo si jẹ igbakeji rẹ.

Ọkunrin yii ko fakoko ṣofo to fi fi orukọ naa ranṣẹ siluu Abuja, lai tiẹ fi ti Igbakeji Aarẹ orileede yii toun naa jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, ṣe. Nibi ti iṣoro rẹ ti bẹrẹ niyẹn.

Ṣe bi wọn ba to o bo ṣe yẹ, nitori ipo ti ọkunrin naa di mu, oun lo yẹ ko jẹ olori ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun, ko si yẹ ko si ohun ti wọn n ṣe tabi to n lọ ninu ẹgbẹ naa to maa ṣẹyin rẹ, ṣugbọn Amosun ko fi ti ọkunrin naa ṣe.

Diẹ ninu ohun to n fa wahala laarin wọn ni pe ko fi bẹẹ si ajọṣepọ to dan mọran laarin gomina ọhun ati aṣiwaju ẹgbẹ wọn, Oloye Bọla Tinubu. Tinubu yii si lo fa Oṣibajo kalẹ, ajọṣepọ ti ko lẹgbẹ lo si wa laarin wọn. Bẹẹ ni awọn kan ti n sọ tipẹ pe Amosun wa ninu awọn to yẹju Tinubu lọdọ Aarẹ, awọn ni wọn n ṣebajẹ ọkunrin yii, wọn fẹẹ gba ipo aṣaaju mọ ọn lọwọ, wọn ko si fẹ ko maa paṣẹ fun awọn mọ.

Gbogbo bi oun ṣe n ko orukọ jọ yii, to si yan awọn alatilẹyin rẹ nikan si awọn ipo naa, Oṣibajo ko wi nnkan kan, ile ni apoti i jokoo de idi lo fi ọrọ ọhun ṣe.

Afigba ti Amosun gbe orukọ awọn to yan sipo de Abuja ti awọn oloye ẹgbẹ yọ ṣọọki lẹsẹ rẹ, wọn da a si firii, wọn fagile orukọ to gbe wa, wọn ko gba a wọle, wọn ni idibo abẹle ni ki wọn lọọ ṣe.

Ere lo sa pada sile, lo ba tun sọ pe eto idibo gbangba-laṣa-a-ta lawọn yoo ṣe, nibi ti eto idibo yoo ti waye kaakiri awọn ijọba ibilẹ. Bayii ni wọn ṣeto idibo naa lọsẹ to lọ lọhun-un, ni wọn ba tun ni Akinlade yii kan naa lo wọle.

Nibi yii ni baba kukuru to ti n wo Amosun lati ọjọ yii ti fi han an pe ọga loun jẹ si i nidii oṣelu.

Nigba ti awọn igbimọ ti yoo mojuto eto idibo de, ọdọ awọn igun ti Igbakeji Aarẹ fara mọ ni wọn lọ, wọn ṣeto idibo, wọn si kede esi idibo ọhun pe Dapọ Abiọdun lo wọle. Niwọn igba to si ti wa ninu alakalẹ ẹgbẹ pe ibo ti awọn ti wọn ba ran wa lati ilu Abuja ba kopa ninu rẹ ni ojulowo, ibo ti igun Oṣibajo ni wọn gba wọle, ẹni ti oun naa si nifẹẹ si lati dupo gomina lo wọle, bo tilẹ jẹ pe Rẹmọ loun ti wa, ki i ṣe Yewa ti awọn eeyan ti n pariwo pe awọn ni ipo naa kan bayii.

Nibẹ lo si ti han si i pe baba kukuru Rẹmọ ti ko sọrọ lati ọjọ yii lo wa nidii ọrọ oun. Ọkunrin naa jẹwọ fun un pe ariwo kọ ni gbogbo nnkan, ati pe ọga loun jẹ si i, ko si le maa gbe nnkan gba ẹyin oun nidii oṣelu ipinlẹ Ogun.Loooto ni alaga ẹgbẹ wọn nipinlẹ Ogun, Oloye Derin Adebiyi, kede awọn eeyan ti Amosun, ṣugbọn ti Oṣibajo ni wọn forukọ rẹ silẹ gẹgẹ bii ẹni ti ẹgbẹ mu.

Eyi lo fa wahala nla fun Amosun, bo tilẹ jẹ pe o n fọkan awọn alatilẹyin rẹ balẹ pe ko ni i si iṣoro, ọkan rẹ ko balẹ rara, bẹẹ ni inu rẹ ko dun, nitori bi Igbakeji Aarẹ ati awọn to ka si ọta rẹ nidii oṣelu ṣe fẹẹ yi i lagbo da sina. Ṣe ni gbogbo igba to fi n yan awọn orukọ to n yan ọhun ni wọn n sọ pe ko fi ti awọn igun Oluṣẹgun Ọṣọba ṣe.

Bayii ni Amosun sare lọ sọdọ Buhari l’Abuja lọsẹ to kọja. Oun atawọn gomina mẹjọ mi-in tawọn naa ni iṣoro kan tabi omi-in ni wọn jọ lọ. Wọn ṣepade loootọ, ṣugbọn o jọ pe ẹkọ ko ṣoju mimu nibi ipade ọhun. Awọn oloye ẹgbẹ naa ni Buhari pada taari wọn si. Bẹẹ lo si ni ki Oṣinbajo ati gomina yii jọ ṣepade papọ. Loootọ ni ipade ọhun waye, ṣugbọn ko yi ohun to ti wa nilẹ pada. Eyi si jẹ ibanujẹ ọkan fun ọpọlọpọ wọn, nitori wọn ti ni i lọkan pe pẹlu bi awọn ṣe sun mọ Buhari, paapaa julọ Amosun, ko si ohun ti awọn ko le gba lọwọ rẹ.

Beeyan ba si ri gomina yii lasiko to n ya fọto pẹlu Aarẹ Buhari, tọhun yoo ti mọ pe ina oṣelu n jo o labẹ aṣọ. Ẹrin iyangi lo rin ninu fọto naa, niṣe ni oju rẹ si le koko.

ALAROYE yọ ọ gbọ pe awọn kan ni ki ọkunrin naa lọọ bẹ Igbakeji Aarẹ, ko si lọọ bẹ alaga ẹgbẹ wọn, Adams Oshiomhole, ati Aṣiwaju Bọla Tinubu, nitori ogun afọwọ-sowo-pọ awọn eeyan naa lo n ja a, ṣugbọn ọkunrin naa ko le lọ sọdọ awọn eeyan naa. Awọn kan ni iwa igberaga to ti hu si wọn ti ko si fi tiwọn ṣe ninu ẹgbẹ lo pada waa jiya rẹ yii. Wọn ni o wa ninu awọn ti ko fẹ ki Osihomhole di alaga ẹgbẹ APC, bẹẹ ni ko tẹriba fun Tinubu mọ, gbogbo ọna lo n wa lati ri i pe ọkunrin naa ki i ṣe alaṣẹ lori oun mọ, bẹẹ ọsan ati oru ni oun ati Igbakeji Aarẹ.

Bayii ni Amosun pada sile lọwọ ofo lati ilu Abuja nitori gbogbo awọn to ri, gbogbo awọn to bẹ, gbogbo awọn to ro pe wọn le ba a da si ọrọ naa ni wọn ko ri i yanju, ko si le pada si ọdọ awọn ti agbara yii wa lọwọ wọn.

Koda, ọkan ninu awọn ọmọ bibi Yewa to tun ti figba kan jẹ minista fun eto ẹkọ, Iyabọ Aniṣulowo, bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa. O ni Igbakeji Aarẹ lo n da ẹgbẹ APC ru nipinlẹ Ogun. O ni bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni, Eko lo ti n ṣe oṣelu rẹ, nitori idi eyi, ko yẹ ko waa maa da sọrọ oṣelu tawọn ti n ṣe tipẹ nipinlẹ Ogun. Ṣugbọn gbogbo ariwo yii paapaa ko mu nnkan kan jade.

Awọn agbaagba ẹgbẹ, to fi mọ awọn kan lati Yewa naa tun fi aidunnu wọn han si igbesẹ yii, wọn ni igbesẹ yii le ṣakoba fun ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun nitori ẹni ti awọn ko fẹ ni wọn gbe le awọn lori.

Yẹyẹ la gbọ pe awọn eeyan naa atawọn ọmọ ẹgbẹ APC kan nipinlẹ Ogun ti ko faramọ bo ṣe n ṣe ijọba n fi i ṣe, wọn ni ọrọ rẹ ko yatọ si ti alaṣeju to kidi bọ omi gbigbona.

Nibi ti nnkan si de duro bayii, ko ti i sẹni to mọ ohun ti yoo tidi wahala naa yọ fun oludije ti wọn fa kalẹ yii, nitori Amosun ti ni oun ko ni i ṣiṣẹ fun un, loju oun si kọ ni Dapọ Abiọdun yoo fi di gomina Ogun. Bi eleyii ba si fi waye, afaimọ ko ma jẹ ẹgbẹ oṣelu mi-in ni yoo wọle nipinlẹ Ogun.

Ni bayii, Dapọ Abiọdun to wa lati Rẹmọ ni ẹgbẹ oṣelu APC fọwọ si, Adebutu to wa lati Ijẹbu ni ẹgbẹ oṣelu PDP fa kalẹ, nigba ti ẹgbẹ oṣelu tuntun ti wọn gba pe Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, n ṣatilẹyin fun, Gboyega Isiaka wa lati Yewa. Ṣe bi ẹẹkẹ ẹranko ko ba bajẹ, ẹẹkẹ ọmọ eeyan ko ni i dun. Njẹ o ṣee ṣe ko jẹ pe Gboyega Isiaka toun naa wa lati Yewa ni yoo kofa wahala yii, abi awọn Amosun yoo pada ṣatilẹyin fun Dapọ Abiọdun lati dupo, ko si di gomina ipinlẹ Ogun lọdun to n bọ? Akerengbe awọn oloṣelu yii ni yoo juwe ibi ti wọn yoo fokun bọ. Esi idibo gomina ọdun to n bọ nipinlẹ Ogun ni yoo fi eyi han.

 

(66)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.