Idaamu Dino Melaye Ọmọlẹyin Saraki to ha sọwọ aye

Spread the love

Bi ẹnikan ba woṣẹ fun ọkan ninu awọn aṣofin agba lati ipinlẹ Kogi pe ni asiko ta a wa yii, ija nla yoo bẹ silẹ laarin oun ati awọn aṣaaju ẹgbẹ APC to gbe e wọle, to fi mọ ijọba apapọ, niṣe leeyan yoo sọ pe ẹni to n difa naa ko da a re rara. Idi ni pe laaarin ọdun 2014 titi di asiko ti ẹgbẹ APC fi gbajọba lọdun 2016, ọrẹ to wa laarin Dino Melaye ati ẹgbẹ APC pẹlu ijọba to wa lode too fowo wọ. Eeyan daadaa ni Dino loju wọn, a-too-fiṣẹ-ogun ran si ni pẹlu. Ọkunrin naa wa lara awọn to koju ijọba Goodluck Jonathan lọdun 2014 titi di 2015 tijọba PDP kogba sile, o ni afi dandan ki Jonathan lọ.
Oriṣiirṣii ẹsun lo ka si ijọba naa lẹsẹ, o ni ijọba onijibiti, akowojẹ, ti ko laaanu araalu ni. Iyẹn ijọba Jonathan. Ko sai mẹnuba ọrọ Boko Haram to ni apa ijọba naa ko ka, bẹẹ lo ni ko bikita fun awọn akẹkọọ ileewe Chibok ti awọn Boko Haram waa ji ko lọ.
Ojumọ kan, ipolongo kan ni, ojoojumọ lo si n dana wahala l’Abuja nigba naa, ti yoo ko awọn ọdọ ilu jọ, awọn iyalọja ko gbẹyin, ariwo to si n pa ni pe afi ki Jonathan lọ. Ni gbogbo asiko naa, ọrẹ oun atawọn aṣaaju wọn ninu ẹgbẹ APC ṣee fowo wo, nitori niṣe ni wọn n kan saara si i pe ọkunrin to gboya to si to gbangba-a-sun-lọyẹ ni pẹlu bo ṣe n koju Jonathan ati ijọba rẹ. Bẹẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Dino tẹlẹ, o si ti figba kan ṣoju awọn eeyan rẹ nile-igbimọ aṣoju-ṣofin ni Abuja kan naa lọdun 2007 si 2011.
Eyi ni wọn ṣe titi ti asiko ibo fi de, ti ẹgbẹ rẹ tuntun, APC, si wọle. Ọpọ awọn aṣofin, titi to fi mọ awọn gomina ti wọn jade lati dupo ninu ẹgbẹ oṣelu yii ni wọn wọle ibo nigba naa, ọrọ ko si yọ Dino Melaye silẹ, oun naa wọle lati ṣoju awọn eeyan rẹ lati agbegbe Kogi West ni ipinlẹ Kogi, nile igbimọ aṣofin agba.
Ṣugbọn ko pẹ ti wọn wọle ibo ti iṣejọba bẹrẹ ti wahala fi bẹ laarin aṣofin yii atawọn aṣaaju ẹgbẹ APC, to fi mọ aarẹ paapaa. Asiko ti wọn fẹẹ yan olori ile igbimọ aṣofin ni wahala naa ti kọkọ yọju. Dokita Bukọla Saraki nifẹẹ si ipo naa, ṣugbọn awọn aṣaaju ẹgbẹ naa ni ẹlomi-in lọkan ti wọn fẹẹ fakalẹ, eyi si dija nla laarin wọn. N lo ba di pe onikaluku bẹrẹ si i ba awọn aṣofin sọrọ ni kọrọ, wọn n ko ọmọ ẹyin jọ lati ri i pe awọn lawọn bori.

 

 

Ni gbogbo asiko yii, ẹyin Bukọla Saraki ni Dino wa, oun lo si n polongo fun lati di olori ile igbimọ aṣofin agba. Bẹẹ naa lọrọ si ri nigba ti awọn ọmọlẹyin Bukọla pẹlu atilẹyin awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to wa nile naa yi ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Bọla Hammed Tinubu, lagbo da sina. Wọn dibo naa lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ yooku lọ sibi ipade kan ti awọn aṣaaju ẹgbẹ APC n ba Aarẹ Buhari ṣe, ki wọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti dibo nile igbimọ, Bukọla Saraki si di olori ile igbimọ aṣofin. Bẹẹ lo ṣi wa titi di ba a ṣe n sọ yii.
Latigba naa lo jọ pe idaamu Melaye ti bẹrẹ pẹlu ijọba atawọn aṣaaju ẹgbẹ APC, nitori ọkunrin ara Kogi naa ko fi bo pe ẹyin olori aṣofin naa loun wa. Ni gbogbo asiko ti idaamu si ba Saraki, ti wọn fi ẹsun ikowojẹ kan an, ti wọn ni ko ṣe akọsilẹ gbogbo dukia to ni fun igbimọ to n gba akọsilẹ dukia tawọn oloṣelu ba ni ki wọn too dipo ti wọn wa mu, ẹyin rẹ ni Dino wa gbagbaagba.
Ṣe ọgbọn oṣelu naa ni gbogbo ẹ, nigba ti wọn wa gbogbo ọna lati yọ Saraki nipo olori ile naa ti wọn ko ri ni wọn lọọ hu ẹsun yii jade, bẹẹ ni wọn sọ pe o ṣe owo ijọba ipinlẹ Kwara baṣubaṣu lasiko to wa ni ipo gomina. Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn ẹsun yii ni Bukọla jẹbi rẹ, bo ba ṣe pe ko ni wahala tabi ija kankan pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn ni, ko sẹni ti yoo ranti eleyii mọ.
Ni gbogbo asiko naa, digbi ni Dino wa lẹyin olori wọn. Iku nikan ni i gbaṣọ lara ewurẹ lo fọrọ naa ṣe, nitori gbogbo asiko ti Saraki ba n lọ si kootu ni Dina n tẹle e. Bẹẹ lo n fi gbogbo igba sọ pe wọn kan n gbogun ti aṣaaju awọn naa ni, irọ ni gbogbo ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ, awọn kan lo wa nidii gbogbo idaamu ọga awọn aṣofin.
Melaye ko duro lori eleyii, nigba ti gbogbo nnkan bẹrẹ si i fọjupọ ninu ijọba Buhari, ti eku ko ke bii eku mọ, ti ẹyẹ naa ko si ke bii ẹyẹ, ọkunrin yii ki i fi ọrọ sabẹ ahọn sọ, gbogbo igba lo si maa n dide sọrọ nibi ijokoo wọn nile igbimọ lati sọ awọn ohun ti ijọba yii n ṣe ti ko daa.
Ọrọ yii ko dun mọ ọpọ awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu. Wọn ni bawo ni Dino to jẹ ọmọ ẹgbẹ ṣe le maa dide ni gbangba, ti yoo si maa tabuku ẹgbẹ to gbe e wọle, ẹgbẹ to pe e pe ko waa jẹun, nitori ounjẹ jijẹ ni ọpọ awọn oloṣelu yii ri wiwa nipo wọn lati ṣoju awọn eeyan wọn si. Igbagbọ wọn ni pe bo ba tiẹ ri ohunkohun, niṣe lo yẹ ko pe awọn aṣaaju ẹgbẹ si kọrọ ko sọ fun wọn, wọn ni iwa idojuti ni bi Dino ṣe maa n tabuku iṣejọba Aarẹ Buhari ati oriṣiiriṣii ohun aburu to n lọ niluu ti ijọba naa ko ya si wọn.
Nibi yii ni Dino ti bẹrẹ si i ni ọpọlọpọ ọta, ti awọn tọrọ kan naa si n wa gbogbo ọgbọn lati yẹgi lẹyin ọkunrin ara Kogi yii. Ọtọ ni wọn sọ pe ko jade Yunifasiti Ahmadu Bello ni Zaria to sọ pe oun lọ, wọn ni ayederu iwe ẹri lo n gbe kiri. Nigba to bọ ninu eleyii ni wọn tun fẹsun kan an pe o fun awọn adajọ ni abẹtẹlẹ lati yi esi idibo pada. Ariwo eyi ko ti i tan nilẹ ti wọn fi tun sọ pe o lo awọn tọọgi lati pa awọn kan, pe oun lo ko ibọn fun wọn, eyi lawọn ọlọpaa si fi n wa a kiri.
Ohun to tun mu ọrọ naa buru ni ija buruku to wa laarin Dino ati gomina ipinlẹ rẹ, Yahyah Bello. Bii ata ati oju ni ọrọ awọn mejeeji, wọn o ki i ri ara wọn soju. Gbogbo ohun to ba jẹ mọ ti ijọba Buhari ni Bello maa n kan saara si ni tirẹ, ibaa dara, ibaa ma dara. Ọrọ ko si le ṣe ko ma ri bẹẹ nitori ijọba Buhari lo gbe e wọle gẹgẹ bii gomina. Bi ko ba si atilẹyin Aarẹ, ọkunrin naa ko le gburoo ipo naa laelae. Idi ni pe niṣe ni wọn fi ọgbọn alumọkọrọyi gbe e wọle pẹlu atilẹyin ofin ti ajọ eleto idibo tumọ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo gbagbọ pe igbakeji oludije fun ipo gomina nipinlẹ Kogi, James Abiọdun Faleke, lo yẹ ko di ipo naa mu.
Ojoojumọ lawọn mejeeji maa n dọdẹ ara wọn, gbogbo ibi ti anfaani rẹ ba si ti yọ ni wọn ti maa n sọko ọrọ sira wọn. Ọrọ naa le debii pe awọn kan ninu awọn eeyan agbegbe Kogi West ti wọn fibo gbe Dino Melaye wọ ile igbimọ aṣofin ni awọn ko fẹ ẹ ni ipo naa. Wọn ni ko ṣe iṣẹ idagbasoke kankan si adugbo to n ṣoju, bẹẹ lo maa n fabuku kan awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu to gbe e wọle, ọrọ ṣakaṣaka to si maa n sọ ko dun mọ awọn ninu, nidii eyi, awọn fẹ ko maa pada bọ nile, ki awọn si yan ẹlomi-in ti yoo ṣoju awọn bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Awọn to mọ bọrọ oṣelu ṣe n lọ sọ pe gbogbo ariwo yii ko sẹyin gomina ipinlẹ naa, nitori gbogbo ọna lo n wa lati yẹgi nidii aṣofin ipinlẹ rẹ yii. Igbagbọ wọn ni pe nitori pe o wa nile igbimọ aṣofin agba lo fi n pariwo, to si n sọrọ ijọba Buhari lai daa, ti ko ba si nibẹ mọ, ko sẹni to maa gbohun rẹ.
Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii ni wọn bẹrẹ eto idibo lati yọ Dino nile igbimọ. Ṣugbọn itiju nla lo bọ si fun Gomina Bello ati ijọba apapọ to n ti i lẹyin, nitori o han pe irọ ni wọn n pa lati ilẹ wa. Awọn eeyan agbegbe naa ko jade, wọn ko si ri ida mẹwaa ibo to yẹ ki wọn ri to le fi gbe Dino pada wale. Bẹẹ ko si Dino nile o, osibitu loo wa, iyẹn gan-an labuku nla to kan Bello ni Kogi.
Ọrọ ọtẹ yii naa lo sọ ọ di ero ọsibitu. Ọsẹ to kọja yii ni awọn ẹṣọ alaabo papakọ-ofurufu lọọ rẹbuu ẹ nigba to n ba iṣẹ awọn aṣofin lọ si orilẹ-ede Morocco. Wọn da a duro ni, wọn ni ko yẹ lati rin irin-ajo naa, nitori awọn ọlọpaa ti n wa a tipẹ. Ọlọrun nikan lo ṣa mọ bi wọn ṣe ṣe e, Dino tun yọ mọ wọn lọwọ.

Eyi lo jẹ ki awọn ọlọpaa lọọ gbe e nile rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti wọn si gbe e sinu motọ, wọn ni ipinlẹ Kogi ni yoo ti jẹjọ ẹsun pe oun ni baba isalẹ awọn apaniyan ti wọn fi kan an. Ọrọ yii lo fa wahala laarin oun atawọn ọlọpaa, nigba ti aṣofin naa loun ko ni i tẹle wọn lọ si Kogi, nitori wọn n gbe oun lọ sibẹ lọọ pa ni.

Ariwo to gbalu lọjọ naa ni pe Dino fẹẹ sa jade ninu motọ ti wọn fi n gbe e lọ si Lokoja, lo ba ṣeṣe. Di ba a ṣe n wi yii, ọsibitu ijọba, niluu Abuja, ni Dino wa to ti n gba itọju. Awọn agbofinro ti ni bi ara rẹ ba ti balẹ ni yoo foju bale-ẹjọ lati jẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an. Koda, wọn de ṣẹkẹṣẹkẹ mọ ọn lọwọ nibẹ, niṣe ni wọn fi ankọọbu mu ọwọ ẹ mọ bẹẹdi, wọn ni ko ma baa sa lọ.

Ṣe ki i buru buru ko ma ku ẹni kan mọ ni, awọn aṣofin ẹgbẹ rẹ rọ lọ sibẹ lọsẹ to kọja lati lọọ ki i. Bẹẹ ni olori ile igbimọ aṣofin agba, Bukọla Saraki, funra ẹ lo ṣaaju wọn lọ o, o si sọ pe ara rẹ ti n balẹ daadaa.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ohun ti Dino Melaye jẹ lo yo o, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe tori pe ọkunrin naa ko dakẹ, to si n sọ gbogbo iwa ibajẹ to wa ninu ijọba APC to gbe e wọle ni gbogbo wahala wọnyi fi de ba a.

Awọn mi-in ni nitori Saraki ni wọn ṣe fẹẹ ṣe e leṣe. Wọn ni oun ni Saraki fi n diju lati sọ ọrọ odi si ijọba, ati pe ọrọ ti akuwarapa Dino ba sọ, ara ọrun Saraki lo sọ ọ. Saraki gan-an lo n ba ijọba Buhari ja, o kan n fi ọrọ si Dino lẹnu lasan ni.

Nibi ti nnkan de duro bayii, ko sẹni to ti i mọ boya Dino yoo bọ ninu awọn okun ẹjọ oriṣiiriṣii ti wọn dẹ silẹ fun un yii, nitori egbinrin ọtẹ lọrọ aṣofin naa bayii, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru jade. Oju wa ni yoo ṣe.

(75)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.