Ibo Ọsun: Ifẹ awọn eeyan lo wa simuṣẹ—Fayẹmi Buhari ati APC ti fọ dẹmokiresi patapata—Fayoṣe

Spread the love

Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), ati People’s Democratic Party (PDP), nipinlẹ Ekiti ti sọrọ lori eto idibo to waye

lọsẹ to kọja nipinlẹ Ọṣun, nibi ti Gboyega Oyetọla ti APC ti jawe olubori.

Ninu atẹjade kan ti Yinka Oyebọde to jẹ olori eto iroyin fun Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, fi sita lo ti ni ibo naa fi ifẹ tawọn eeyan ni si APC han.

Fayẹmi ki Oyetọla ku oriire, o ni ọgbọn oṣelu tawọn eeyan Ọsun ni lo jẹ ki wọn dibo yan an, o si fi han pe o dangajia ju awọn oludije to ku lọ.

Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan l’Ekiti naa ni asiko lati ni idagbasoke agbegbe ti to bayii fun awọn ipinlẹ mẹfẹefa ilẹ Yoruba, nitori wọn ti bọ sọwọ APC.

O waa juwe Oyetọla bii alakooso to dangajia, o loun gbagbọ pe yoo mu aṣeyọri alailẹgbẹ ba ipinlẹ Ọsun laipẹ.

Ṣugbọn Gomina Ayọdele Fayoṣe nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Idowu Adelusi, ti ṣapejuwe eto idibo naa bii ojulowo jibiti ti APC ati Aarẹ Muhammadu Buhari ṣagbatẹru rẹ.

O ni itiju nla ni eto naa jẹ fun iṣejọba dẹmokiresi, Naijiria yoo si tipasẹ rẹ di oniyẹyẹ laarin awọn orilẹ-ede agbaye.

‘’Pẹlu eto ainitiju to waye nipinlẹ Ọṣun, o ti daju pe ijọba awa-ara-wa ti doku nilẹ yii. Iru madaru ti wọn ṣe l’Ekiti loṣu keje naa ni wọn tun lọọ ṣe l’Ọṣun, o si ba ni ninu jẹ pe ifẹ awọn eeyan ko ṣẹ.

‘’Aanu Ọlọrun ati ojurere ile-ẹjọ nikan ni Naijiria nilo bayii. Mo gboriyin fun Sẹnetọ Nurudeen Ademọla nitori o ja ija rere; ko fidi-rẹmi, wọn ji ẹtọ rẹ ni. O daju pe iranlọwọ n bọ laipẹ.’’

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.