Ibo odun 2019 R-APC, ADP, SDP atawon egbe oselu mi-in kowo bowe adehun

Spread the love

Bi gbogbo nnkan ba lo bo se ye, Monde, ojo Aje, ojo kesan-an, osu yii ni awon omo egbe oselu to din die ni ogoji ko ara won jo alti sepade, ki won soi towo bowe adehun ajosepo gbogbo egbe yii lasiko eto idibo to n bo. Igbese yii waye nitori ipinnu won lati le Aare Mohamaddu Buhari kuro lori ipo, ki won si fi okan ninu awon ti egbe yii ba fenuko le lori sori aleefa.

Bo tile je pe awon egbe oselu yii ninu eyi ta a ti ri egbe PDP,ADC,R-APC SDP atawon mi-in ti ni ajoso oro, ti won si ti gba pe awon yoo jo sise po ninu eto oselu odun to n bo, iwe adhun ti won yoo kowo bo, nibi ti won yoo ti jo salaye ohun ti eto naa ba duro ati bi yoo se see se lo n da won duro.

Monde ana ni won si ni ipade yoo waye lori eleyii. ALAROYE gbo pe ipade yii se pataki nitrori awon omo egbe ti won fee darapo yii ti kogbon, ohun ti won si n so ni pe ina esisi ko gbodo jo awon leemeji nitori opo won lo darapo mo egbe APC ki egbe yii too le rowo mu lasiko eto idibo to koja, sugbon won ni nigba ti Buhari gba ijoba, gbogbo awon tawon ba a sise ni ko naani mo, bee ni ko si siika adehun to se pelu awon, kaka bee awon ti ko tie nawo, ti won ko si nara, ti opolopo won ki i si i se oloselu lo je anfaani wahala ti awon se lasiko naa.

Eleyii ni awon eeyan naa n sa fun ti won fi so pe o digba tawon ba kowo bowe adehun ki awon too le se ohunkohun pwelu egbe tuntun tawon fee darapo mo yii.

Opolopo nnakn ni awon omo egbe to sese fee darapo mo yii n fe ni won ti kowe re, ti won si ti fi sowo si awon igbimo ti yoo ri si oro naa.

Gege bi ALAROYE se gbo, opo ninu awon eeyan naa ni won so pe ki awon too le darapo mo egbe yii, aridaju gbodo wa pe won maa fun awon ni ipo oselu ti awon ti wa tele, bee ni aown to n gbiyanju lati lo fun ipo tuntun kan tabi omi in so pe afi bi won ba setan lati fun awon ni tikeeti lati dije fun ipi yii ni awon yoo too le di omo egbe PDP patapata.

Lara awon nnakn ti ipade ohun yoo tun da le lori ni ona ti awon egbe oselu to fee darapo mo egbe PDP yii yoo gba lati polongo ibo fun eni ti won ba jo fa kale lati dupo aare loruko gbogbo won, paapaa julo laarin awon oludibo ti opolopo won ko kawe, to si da bii pe o le fee nira die.

Bakan naa ni egbe oselu PDP pe ipade kan siluu Abuja ni Monde, ose yii. Gege bi enikan to sofofo fun ALAROYE se so, o ni awon nnakn pataki pataki kan ni awon egbe naa fee fenuko le lori, ninu eyi ti eto idibo ti yoo waye nipinle Ekiti ati Osun lodun yii.Bakan naa ni oro awon omo egbe oselu APC to ti ya kuro nibe bayii ti won pe ni R-APC to fee darapo mo egbe yii.

Awon ti won n reti nibi ipade ohun ni alaga egbe naa, Uche Secondus, awon aare to ti koja ti won je omo egbe oselu yii, gbogbo awon to fee du ipo aare, awon gomina to wa nipo bayii atawon to ti koja, awon omo ile igbimo asofin atawon alenuloro gbogbo.

Bakan naa ni won yoo tun gbo abo iwadii igbimo ti won gbe kale, leyii ti gomina ipinle Cross River tele, Seneto Liyel Imoke je alaga. Igbimo yii ni won pase fun pe ko ba awon omo egbe oselu APC ti inu n bi, to fi mo awon aare ile yii tele soro lori bi won yoo se joo sise papo lati gba ijoba lowo Buhari.

Awon igbimo yii ti ri Aare Olusegun Obasanjo ati Aare Goodluck Jonathan, awon si ti jo soro po. Bi gbogbo nnakn ba si lo bi won se pinnu re, ti eto ti won to kale ko ye, lara awon eeyan nla ti won n reti pe yoo darapo o won ni awon gomina to wa lori aleefa bayii atawon to ti kuro. eyi ko yo olori ile igbimo asofin agba ati kekere, Bukola Saraki ati Yakubu Dogara sile. Bee ni gomina Kano tele, Rabiu Kwakawanso atawon eeyan nla nla mi in lagbo oselu.

Lose to koja ni awon omo egbe oselu APC kan ti alaga egbe CPC tele, Buba Galadimoa kede pe awon ti kuro ninu egbe naa, awon si ti da egbe mi in, R-APC sile, leyii tawon si ti setan lati gba ijoba lowo Aare Buhari.

Ohun ti won lo fa igbese ti won geb ohun ni bi won se ni aare ko mojuto eto aabo, bee ni ko si duro lori awon ileri to se lasiko idibo. Gbogbo eleyii atawon nnakn mi in ni won lo fa a tawon se fee fi egbe naa sile, ti aown yoo si darapo mo egbe oselu mi in.

Pelu igbese ti awon omo egbe APC to ya kuro gbe yii, Oludamoran fun egbe ohun lori oro ofin, Babatunde Ogala ti so pe awon yoo gbe awon eeyan naa lo sile ejo nitori iwa to lodi labe ofin ni won hu. Bee ni won ni awon eleto aabo yoo maa mu awon omo eekan egbe yii, pataki julo, Buba Gladima to pe ara re ni alaga egbe yii. Won ni igbese to gbe lodi labe ofin.

Sugbon se lo da bii pe ihale egbe APC yii ko tu irun kan lara Galadima to je alaga tuntun yii, ariwo to n pa ni pe awon ti ni omo ile igbimo asofin to to lati yo Buhari nipo tawon ba fee yo o.

Titi ti a fi pari akojopo iroyin yii, ko ti i si abajade lori ipade apapo ti won ni aown omo egbe yii fee se, nibi ti won ti fee fenuko lori bi won yoo se pin ipo ati eni to won yoo fa kale fun ipo aare atawon igbese pataki pataki mi in ti won fee gbe.

Bi gbogbo re ba se n lo, ALAROYE yoo maa fi to yin leti.

 

 

 

(73)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.