Ibo ku si dẹdẹ: AWỌN ỌMỌ BUHARI KỌLU OLORI ADAJỌ *Atiku ni nitori wọn fẹẹ ṣojooro ni o

Spread the love

Ọrọ naa ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, o pẹ diẹ ti kinni ọhun ti n bọ wa. Ija laarin Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ ati ẹni to jẹ olori awọn adajọ pata lasiko yii, Adajọ Walter Onnoghen. Ni ọdun 2007, nigba ti Muhammadu Buhari du ipo aarẹ ti ko wọle, o gba ile-ẹjọ to ga julọ nilẹ wa (Supreme Court) lọ, o ni ki awọn adajọ ibẹ ba oun gba kinni naa lọwọ Umar Yaradua to wọle lorukọ  ẹgbẹ PDP, ki wọn gbe kinni naa foun ti oun jẹ ọmọ ẹgbẹ ANPP. Nigba ti wọn dajọ naa, awọn adajọ giga yii kọ, wọn ni Buhari ko wọle ibo, o kan n fi atamọ mọ atamọ lasan ni. Iyẹn lọ bẹẹ. Nigba to tun di ọdun 2011, wọn tun dibo, Buhari si du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ rẹ tuntun to da silẹ, iyẹn CPC. O tun ja kulẹ ninu ibo naa, o si tun gba ile-ẹjọ lọ pe ki wọn ba oun gba ipo aarẹ lọwọ Goodluck Jonathan to wọle, ki wọn gbe e foun. Awọn adajọ yii tun kọ.

Ninu ẹjọ mejeeji ti Buhari pe yii, ti 2007 ati 2011, adajọ kan wa nibẹ to wa ninu awọn to gbegidina fun Buhari, Adajọ Waltrer Onnoghen ni. Ọkan ninu awọn adajọ ile-ẹjọ to ga julọ naa ni, gbogbo wọn ni wọn si jọ fẹnuko pe loootọ loootọ, Buhari ko wọle, ibo to ni ko to nnkan to le gbe e wọle. Ọpọlọpọ awọn adajọ to ku ti wọn jọ dajọ naa ni wọn ti fẹyinti, Onnoghen lo gbẹyin ninu wọn, iyẹn naa ni ipo olori ile-ẹjọ to ga julọ nilẹ wa si ṣe tọ si i lọdun 2016. Ṣugbọn Buhari ko fẹẹ gbe e sipo naa, nitori ijọba ti de ọwọ tirẹ, ko si fẹ ko jẹ iru ẹni bẹẹ ti oun ti mọ tẹlẹ, to wa ninu awọn adajọ to da oun lẹbi, ni yoo tun waa di olori awọn adajọ lasiko ti oun n ṣejọba. Asiko to yẹ ki wọn ti darukọ ọkunrin naa ti kọja, ṣugbọn Buhari ko darukọ ẹ, ko si forukọ rẹ ranṣẹ sawọn aṣofin, o n wa ọna lati fi orukọ mi-in rọpo ẹ.

Nigba naa ni Ọlọrun gbe iṣe rẹ de. Ara Buhari ko ya ni o, aiya ara naa si pọ gan-an debii pe ilu oyinbo ni wọn gbe e lọ. Nigba ti yoo fi gbadun ti yoo fi pada wale, Yẹmi Ọṣinbajo to n ṣe adele aarẹ nigba naa ti fi orukọ Onnoghen yii ranṣẹ, wọn si ti sọ ọ di olori awọn adajọ pata nilẹ wa. Nigba ti Buhari de to mọ, ko si ohun to le ṣe mọ, o gba kamu, ọkunrin adajọ naa si n ba iṣẹ rẹ lọ. Amọ bi asiko ibo yii ti n sun mọle, bẹẹ ni ijaya de ba Buhari atawọn ọmọ ẹ, nitori lẹyin ti wọn wo iwaju ti wọn wo ẹyin, ti wọn ri i pe gbogbo eto lawọn ti ṣe, wọn mọ pe ibi kan ṣoṣo ti ọrọ ku si ni ọdọ olori awọn adajo yii. Awọn ọlọpaa ti wa labẹ wọn, nitori ẹni to jẹ ọga fawọn, ọmọ wọn ni; awọn ṣọja ti wa labẹ wọn, nitori awọn naa ni wọn fi Buratai sibẹ, tiwọn naa lo si n ṣe. Awọn ni wọn ni awọn DSS naa, wọn si ti ri i pe awọn eeyan awọn ni awọn fi sidii eto idibo yii, awọn aṣoju wọn pe ni INEC debii pe ohun ti wọn ba fẹ ni wọn yoo ṣe, koda bi ẹgbẹ PDP wọle, wọn le yi esi ibo naa pada ti kinni kan ko ni i ṣe.

Ibi kan ṣoṣo ti iṣoro ku si naa ni ọdọ adajọ agba yii, nitori bi wọn ba yi esi idibo tabi ti wọn ba ṣe ojooro kan, ti wọn ba gbe e dewaju awọn adajọ yii, to ba jẹ adajọ agba naa lo wa nibẹ, o le ma ṣe ohun ti wọn fẹ ko ṣe fun wọn, paapaa julọ, nigba to jẹ Cross River lo ti wa, to si jẹ gomina to wa nibẹ bayii, ọmọ ẹgbẹ PDP ni. Eleyii ki i ṣe ohun ti awọn eeyan naa le dakẹ si rara, nibẹ ni wọn si ti gbimọ pọ lati yẹju olori awọn adajọ yii, wọn fẹẹ fẹyin rẹ balẹ kia. Awọn alagbara ti wọn wa ninu eto ipolongo ibo fun Buhari bii Aṣiwaju Bọla Tinubu, Nasir El-Rufai (Oun mọ adajọ yii daadaa tẹlẹ pe ki i ṣe eeyan awọn), Rotimi Amaechi ti wọn jọ wa lati adugbo kan naa atawọn olori awọn agbofinro ti wọn n ṣiṣẹ fun ijọba yii sare jokoo, wọn wo akoko ti ọkunrin yii yoo fẹyinti tabi ọna ti wọn le ba mu un, wọn ko ri kinni kan rara.

Awọn ole-ti-i-mọ-ẹsẹ-ole-i-tọ-lori-apata ti wọn wa laarin wọn ni wọn ni ko si ọna ti awọn le ba mu un ju ki awọn sọ pe ko ṣe akọsilẹ awọn ohun-ini rẹ gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba lasiko to fi n gba iṣẹ adajọ agba yii lọ. Gẹgẹ bi ofin ti wi, gbogbo awọn lọgaa lọgaa nidii iṣẹ ijọba yii ni wọn gbọdọ maa ṣe akọsilẹ awọn ohun-ini wọn lọdọọdun, ki ijọba le mọ ohun ti wọn ni. Amọ pupọ ninu awọn eeyan yii ni ki i ṣe e nitori bi wọn ba gbajọba loni-in, nigba ti yoo ba fi di ọdun to n bọ, ohun-ini wọn yoo ti wa ni ilọpo mẹta, wọn ko si ni i le ṣalaye gidi lori ọna ti wọn gba ri owo ti wọn fi ko awọn kinni naa jọ. Ohun tawọn ijọba Jonathan fi ba Tinubu ja nijọsi ree, ṣugbọn ti wọn ko ri ẹjọ naa yanju nitori igbimọ naa ni awọn ti wọn mu ẹjọ naa wa ko to o kalẹ bo ṣe yẹ ki wọn to o, wọn o da Tinubu lẹbi, wọn ko si da a lare, ẹjọ naa wa nibẹ sibẹ.

Igbimọ yii kan naa lo fi Oloye Bukọla Saraki lakalaka nijọsi, ti wọn n fi ojoojumọ wọ ọ lọ sile-ẹjọ lati waa ṣalaye idi ti ko fi ṣe akọsilẹ awọn ohun-ini rẹ, ati bi awọn ohun-ini to ni lẹyin to ṣe gomina tan ṣe ju eyi to ni tẹlẹ lọ. Code of Conduct Bureau (CCB) ni wọn n pe igbimọ yii, awọn naa si ni ile-ẹjọ tiwọn, Code of Conduct Tribunal (CCT) lọtọ, nibi ti wọn ti le da oṣiṣẹ ijọba lẹbi, wọn si le sọ ọ sẹwọn. Nibi yii lawọn ọmọ Buhari sare gbe ọrọ gba. Kia ni wọn wa ọkunrin kan, Dennis Agbanya, wọn ni ko kọwe ọran sawọn CCB, ko sọ fun wọn pe o da oun loju pe Onnoghen, olori awọn adajọ pata, ko ṣe akọsilẹ awọn ohun-ini rẹ sinu iwe ijọba. Dennis, iyẹn ọkunrin to kọwe yii, ọmọọṣẹ Buhari ni tẹlẹ, o ti ba a ṣiṣẹ daadaa, oun ati awọn El-Rufai si jọ wa ninu ẹgbẹ CPC ni, koda oun ni akọwe ipolongo wọn, ki wọn too di APC.

Lati fi han pe ọrọ naa lọwọ aye ninu, bo ti kọwe rẹ si awọn igbimọ yii ni ọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, iyẹn Mọnde ọsẹ to kọja, ti iwe naa si de ọwọ wọn ni ọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu kin-in-ni, ọjọ keji, ni wọn ti pari iwadii wọn, ti wọn si pe Adajọ Agba naa lẹjọ lọjọ kọkanla oṣu, iyẹn ọjọ Jimọ, ti wọn ni ọjọ Mọnde ni igbẹjọ yoo bẹrẹ, iyẹn ni pe laarin ọjọ mẹrin ni wọn pari gbogbo eto naa pata. Ẹsun ti wọn fi kan olori awọn adajọ yii ni pe awọn ba miliọnu mẹta owo dọla ninu akaunti rẹ kan, wọn ni owo naa wa ni banki, ko si sọ fawọn bo ṣe jẹ. Adajọ awọn CCT to jẹ olori igbimọ yii, Daladi Umar, ni ẹjọ niwaju awọn EFCC, wọn loun naa gba awọn owo ẹyin kan, EFCC si ti tori rẹ gbe e lọ sile-ẹjọ lati bii ọdun meji sẹyin, ẹjọ naa ko ti i bẹrẹ titi di bi a ṣe n wi yii o. Ṣugbọn adajọ naa lo ni ki Adajọ Agba pata fun gbogbo Naijiria waa foju kan oun nile-ẹjọ tirẹ, ko si waa sọ ohun to mọ nipa owo to ko pamọ.

Ọrọ naa ti da wahala silẹ, nitori gbogbo awọn to wa nidii ọrọ yii, atawọn ti wọn fẹẹ ṣe ẹjọ naa paapaa, awọn eeyan Buhari ni.  Iyẹn lo bi awọn ẹgbẹ oṣelu alatako gbogbo ninu. Abubakar Atiku to n dije lorukọ awọn PDP sọ pe ko ṣẹṣẹ digba teeyan ba lọ si ile babalawo ko too mọ pe awọn Buhari fẹẹ fi ẹjọ awuruju yii yọ Adajọ Agba yii kuro nipo rẹ ni, ki wọn le gbe eeyan tiwọn si i, ọna lati ṣe ojooro lasiko ibo to n bọ, to jẹ ti wọn ba ṣe ojooro ati eru buruku lasiko ibo naa tan, ko sẹni ti yoo le da wọn lẹbi nile-ẹjọ kankan ni. Ẹgbẹ awọn oloṣelu to ku ti ni awọn yoo jade lẹgbẹrun-ẹgbẹrun, awọn yoo si le ni miliọnu kan ti awọn yoo fẹsẹ rin lọ si Aso Rock, ki wọn le mọ pe ohun ti Buhari ati awọn eeyan rẹ n ṣe ko dara.

Awọn lọọya n binu, awọn adajọ gbogbo naa si faraya. Wọn ni Buhari n fawọn ṣe yẹyẹ ni, o fẹẹ sọ eto idajọ di gbẹwu-dani, ko ki olori awọn adajọ gbogbo sabẹ rẹ. Ṣugbọn wọn lawọn o ni i gba, wọn ni omi ija toun atawọn ọmọlẹyin rẹ gbe kana yii, bo ba ho tan, apa wọn ko ni i ka a.

 

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.