Ibo ijọba ibilẹ yoo waye loṣu kejila l’Ekiti

Spread the love

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ti nnkan ko ba yipada, oṣu kejila, ọdun yii, nibo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Ekiti yoo waye.

Eyi jẹyọ ninu ọrọ Onidaajọ Jide Aladejana to jẹ alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti (EKSIEC) lopin ọsẹ to kọja lasiko ipade toun atawọn adari ajọ naa ṣe pẹlu ajọ eleto idibo gbogbogboo (INEC) niluu Ado-Ekiti.

Aladejana ni EKSIEC ti ṣetan lati ṣeto idibo ti ko ni magomago ninu, awọn si nilo iranlọwọ INEC. O ni gbogbo ẹgbẹ oṣelu to ba kunju oṣuwọn lo lẹtọọ lati kopa, odiwọn kan naa lo si wa fun gbogbo wọn.

Nigba to n fesi, Ọmọwe Mulim Ọmọlẹkẹ to jẹ akọwe eto INEC sọ pe gbogbo iranlọwọ lawọn yoo pese fun EKSIEC nilana eto to wa laarin ajọ mejeeji nitori ibo ijọba ibilẹ jẹ ajọ naa logun.

Tẹ o ba gbagbe, Gomina Kayọde Fayẹmi ko ṣeto ibo ijọba ibilẹ ni saa rẹ akọkọ (2010-2014) latari bi ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) ṣe gba ile-ẹjọ lọ. Ẹjọ ti wọn pe ni pe Abilekọ Cecilia Adelusi to jẹ alaga EKSIEC jẹ ọmọ ẹgbẹ Action Congress of Nigeria (ACN) igba naa.

Oṣu kejila, ọdun 2017, lawọn alaga ti Ayọdele Fayoṣe to jẹ gomina ana ṣeto ibo wọn wọle, opin ọdun yii ni saa wọn yoo si pari.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.