Ibo gomina Oyo yoo gbona yato, laarin Makinde ati Penkelemeesi ni o

Spread the love

Ibi ti ọgọọrọ eeyan foju si lori ọrọ idibo gomina ipinlẹ Ọyọ ti yoo waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, o ṣeeṣe ki ọna ma gbabẹ lọ rara.

Ṣaaju asiko yii, ariwo ti gbogbo ẹgbẹ oṣelu yooku n pa ni pe ijọba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) to wa lori aleefa bayii ko daa to, o n ni araalu lara, dandan si ni ki awọn le wọn kuro lori apere. Gbolohun ti gbogbo wọn fi n polongo idibo naa ree. Ireti ọpọ eeyan si ni pe nigba ti yoo ba fi di asiko idibo, awọn ẹgbẹ wọnyi yoo ti parapọ ṣe ara wọn lọkan, ki wọn le ri ibo to pọ daadaa ju ti ẹgbẹ to wa lori aleefa lọ, ki wọn si ṣe bẹẹ gbakoso ijọba ipinlẹ naa mọ wọn lọwọ. Ṣugbọn kaka bẹẹ, inu ẹgbẹ APC gan-an lawọn ẹgbẹ oṣelu gbogbo tun n rọ lọ, ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako si n fojoojumọ aye tako ara wọn.

Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Ọtunba Adebayọ Alao-Akala, ti bẹrẹ igbesẹ ajumọṣe laarin awọn ẹgbẹ oṣelu yooku. Idibo gomina ku ọssẹ meji lo ti ba Sẹnetọ Rashidi Ladọja ti oun naa ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ naa ṣepade lori igbesẹ yii. Bẹẹ lo ti pe awọn to n dupo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu nla gbogbo bii PDP, ZLP ati ADC sipade alagbara kan nile ẹ ni Bodija, n’Ibadan, pe ki awọn jọ wa ọna lati fa ẹni kan kalẹ ninu awọn, ki awọn le bori ẹgbẹ APC lasiko idibo. Gbogbo wọn ni wọn si peju pesẹ sipade ọhun, yatọ si oludije lorukọ ẹgbẹ PDP, Ṣeyi Makinde ti ko wa, ti ko si ranṣẹ.

Ko ya ni lẹnu pe Akala lo ṣaaju ogun awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati ṣẹgun ẹgbẹ to wa nijọba lọjọ idibo. Ṣe ẹgbẹ Onigbaalẹ loun paapaa fẹẹ fi dupo gomina tẹlẹ. Nigba to mọ pe Oloye Adebayọ Adelabu loludije ti wọn ti pinnu lati fa kalẹ, lo binu kuro ninu ẹgbẹ ọhun to fi lọọ dupo naa lorukọ ẹgbẹ Action Democratic Party (ADP). Iyẹn ni pe nitori Adelabu lagba oṣelu ọmọ Ogbomọṣọ naa fi kuro ninu APC. Lọna keji, ẹgbẹ yii ti gbero lati kọyin Akala ati ọmọ ẹ, Ọlamijuwọnlọ Akala, sira wọn. Ọmọ ẹ dibo wọle sipo alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ogbomọṣọ lorukọ APC, wọn si ti yọ ọ kuro nipo naa nigba to kede pe ẹgbẹ ADP to fa baba oun kalẹ fun ipo gomina loun n ba lọ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti gbẹ koto silẹ fun APC ti gbogbo wọn ri gẹgẹ bii ọta wọn, o ku ẹni ti wọn maa yan lati jẹ aṣaaju wọn, ki wọn le ribi ti ẹgbẹ ti wọn n ba ṣọta naa sinu koto nla. Ṣugbọn aifagba-fẹnikan ko jaye o gun. Nibi ti wọn ti n jija agba mọra wọn lọwọ lẹgbẹ APC ti ba ọna ẹyin yọ si wọn, to si taari gbogbo wọn sinu ọgbun ainisalẹ ti wọn fi ọwọ ara wọn gbẹ.

Olori ogun alatako, iyẹn Akala, ẹni ti ẹnikan ko ro pe o le sun ko ṣeeṣi lalaa pe oun yoo ṣatilẹyin fun oludije gomina ẹgbẹ APC lati wọle idibo to n bọ yii, lawọn ẹgbẹ Onigbaalẹ kọkọ doju kọ.

ALAROYE gbọ pe baaluu lawọn apapọ ẹgbẹ APC gbe ranṣẹ s’Ibadan lati waa gbe Akala, o di bàgẹ̀ nile Aṣiwaju Bọla Tinubu ti i ṣe adari Onigbaalẹ l’Ekoo. Nigba ti Ọmọ Iya Alaro pada s’Ibadan lẹyin ipade to ṣe pẹlu Tinubu lohun ilu to ti n lu tẹlẹ yipada, ti ọgagun ẹgbẹ awọn alatako si bẹrẹ si kọrin mi-in jade lẹnu, pe bo ba ku irawọ kan ṣoṣo loju sanmọ, tẹgbẹ APC loun yoo ṣe.

Eyi to han si gbogbo eeyan, to si ṣee foju ri ninu awọn adehun to wa laarin Akala ati ẹgbẹ APC ni pe, wọn ni lati da ọmọ ẹ ti wọn ti yọ nipo alaga kansu Ariwa Ogbomọsọ pada sipo naa. Lọgan ni wọn si ti da a pada sọfiisi loootọ. Ahesọ ti ẹnikẹni ko si le fidi ẹ mulẹ ni pe wọn fun Ọmọ Iya Alaro ni biliọnu Naira diẹ kan. Ṣugbọn ọkunrin naa ti sọ fun wọn, o si sọ ọ loju gbogbo aye pe oun ko darapọ mọ ẹgbẹ APC, Adelabu ti wọn fa kalẹ fun ipo gomina nikan loun yoo ṣiṣẹ fun, ati pe ẹgbẹ oun, ADP ni ki awọn ololufẹ oun dibo aṣofin fun ninu idibo to n bọ yii.

Ko na awọn adari ẹgbẹ Onigbaalẹ ni wahala rara lati pe awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to ti binu lọ pada saarin wọn. Lojiji niroyin ọhun kan jade kulẹ, pe gbogbo awọn ti wọn n pera wọn ni igun Unity Forum ninu APC yii ti pada sinu ẹgbẹ wọn atijọ; awọn bii Sẹnetọ Monsura Sumọnu, Ọnarebu Adedapọ Lam-Adeṣina, awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin atawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) tẹlẹ. Nnkan ti Ọlọrun si fi ba ẹgbẹ APC ṣe e ni pe bo tilẹ jẹ pe gbogbo awọn abẹnugan Unity Forum lo dupo sẹnetọ, ati aṣoju-ṣofin, ko si ọkankan to wọle ibo ninu wọn, oju gbogbo wọn ti walẹ wayi, pe ẹgbẹ tuntun naa ko lẹnu nibẹ, ko si le gbe awọn debi rere kan ninu oṣelu asiko yii.

Bi oju ọjọ ṣe ri lẹyin idibo aarẹ ati idibo sileegbimọ aṣofin agba mejeeji to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun 2019 yii, lo ṣeru ba ẹgbẹ APC. Ṣe ẹgbẹ People’s Democratic Party lo ni ibo to pọ ju ninu idibo aarẹ ni ipinlẹ Ọyọ. Wọn si mọ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, o ṣee ṣe ki PDP gba ipinlẹ naa mọ awọn lọwọ bi awọn ko ba tete wa nnkan ṣe ṣaaju asiko idibo gomina to n bọ yii . Iyẹn ni wọn ṣe tete wa wọrọkọ fi ṣada nigba ti wọn gbọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu yooku tun ti n mura lati parapọ koju awọn ninu idibo naa.

Iroyin ajumọṣe to wa laarin Akala ati ẹgbẹ APC ko jinnijinni ba awọn ẹgbẹ yooku, n ni PDP, ADC, Social Democratic Party (SDP), ZLP ati Alliance for Democracy, AD ba tun sare pera wọn jọ lọjọ Jimọ to kọja. Ṣeyi Makinde (PDP) to ti takete si wọn tẹlẹ paapaa ko gbẹyin ninu ipade ọhun lọtẹ yii. Ṣugbọn asasi awọn APC ko jẹ ki imọ wọn tun ṣọkan, ọpọ ninu awọn to kopa nibi ipade ọhun to waye nile Ladọja ni Bodija, n’Ibadan, faramọ Makinde, oun funra ẹ naa sọ pe oun kaju ẹ lati ṣe e, ṣugbọn Lanlẹhin yari, o loun ko gba, n ni kaluku ba ṣe tiẹ lọtọọtọ.

Ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn tun ṣepade lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ṣugbọn ibi pẹlẹbẹ lọbẹ fi lelẹ. Amọ ṣaa, SDP, AD ati apa kan ẹgbẹ ZLP ti gba lati ba Makinde ṣe. Ori ipade ojoojumọ ọhun ni wọn ṣi wa titi dirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ta a pari akojọ iroyin yii.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade alẹ ọjọ naa, oludije fun ipo gomina lorukọ ẹgbẹ SDP, Oloye Bọlaji Ayọrinde, sọ pe “a n tẹsiwaju ninu ifikunlukun wa. Ninu ẹgbẹ tiwa (SDP), ba a ṣe wa naa la wa, ṣugbọn a ti pinnu lati ṣatilẹyin fun PDP ninu idibo gomina to n bọ.

“Mi o le sọ fun yin bayii pe iye ẹgbẹ bayii lo ti pinnu lati ṣiṣẹ pọ pẹlu oludije PDP nitori ifikunlukun ṣi n tẹsiwaju. Ti mo ba sọ pe marun-un ni wa bayii, nigba ta a ba fi maa pari ọrọ ta a jọ n sọ lọwọ yii, o le ti di meje, nitori ẹgbẹ oṣelu pọ ni ipinlẹ Ọyọ. Ohun ti mo le sọ bayii ni pe ṣiṣi la ṣi ilẹkun ajumọṣe wa silẹ fun ẹnikẹni to ba ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu wa lati wọle nigbakuugba to ba fẹ.”

Ninu ọrọ tiẹ, Ẹnijia Makinde sọ pe “ṣiṣi nilẹkun wa wa, ẹnikẹni lo le wọle tọ wa wa. Awọn SDP ati AD ti ṣeleri pe awọn ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu wa. Nipa twọn ZLP ati ADC, wọn n ṣepade pẹlu awọn igbimọ adari ẹgbẹ wọn lọwọ. Wọn ṣi le darapọ mọ wa, boya lọla, tabi titi ọjọ idibo ku ọla.”

Ṣugbọn awọn adari apapọ ẹgbẹ APC ko mu ọrọ yii ni kekere rara ni tiwọn. Bi wọn ṣe n pe Akala atawọn ọmọ ẹgbẹ wọn to ti lọ pada naa ni wọn tun n dọgbọn ba awọn to n dupo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu nla nla yooku sọrọ labẹnu. Gbogbo awọn ti PDP gbọkan le wọnyi, bii Sẹnetọ Ladọja, Sẹnetọ Lanlẹhin ati Amofin Sharafadeen Alli to n dupo gomina lorukọ ẹgbẹ Zenith Labour Party (ZLP) ni wọn n bẹ lati ṣe tiwọn. Ko si ni i ya ni lẹnu ba a ba ri eyi to kẹru ẹ sọkọ to gba inu ẹgbẹ APC ninu wọn nigba ti yoo ba fi dọjọ idibo.

Makinde to n dije dupo gomina lorukọ ẹgbẹ PDP lawọn eeyan ti n fọkan si pe o ṣee ṣe ko wọle idibo ọhun tẹlẹ. Ariwo ẹ lo gba gbogbo ipinlẹ Ọyọ kan, to jẹ bẹ ẹ ba debi, Ṣeyi Makinde ni, bẹẹ dọhun-un, oun ni, orukọ ẹ ni wọn n da ninu mọto ati nibi gbogbo kaakiri. Awọn araalu fẹran ọkunrin naa nitori pe eyi kọ nigba akọkọ to maa dupo gomina ti ko wọle ṣugbọn ti ko sinmi owo nina lati maa ran awọn eeyan lọwọ.

Nigba ti nnkan yoo waa tubọ ṣẹnuure fun Makinde, awọn eeyan dibo daadaa fun ẹgbẹ alaburada lasiko idibo to kọja to bẹẹ to jẹ pe oludije ẹgbẹ oṣelu ẹ (PDP), Alhaji Atiku Abubakar lo ni ibo to pọ julọ ninu idibo naa ni ipinlẹ Ọyọ. Eyi lawọn eeyan ṣe n sọ pe bii igba teeyan ba n fẹran jẹkọ ni Makinde yoo wọle idibo gomina, paapaa nigba ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako kan tabi meji ba tun pinnu lati ṣatilẹyin fun un. Ṣe ohun ti gbogbo eeyan ti n sọ tẹlẹ naa ni pe yoo ṣoro ki ẹgbẹ oṣelu kan too le fi ẹyin APC balẹ ninu idibo, afi ki wọn parapọ lati koju awọn alagbara naa.
Ọpọ awọn oludibo ti wọn ti n pariwo Makinde ni inu wọn ko dun si ibi ti ayo oṣelu ti awọn oloṣelu ipinlẹ yii ta fori sọ yii, to fi jẹ pe dipo ki awọn ọmọ ẹgbẹ alatako parapọ tako APC, inu ẹgbẹ ọhun gan-an lawọn ẹgbẹ alatako nla nla tun sa lọ.

Nibi ti nnkan si de duro yii, idibo gomina ipinlẹ Ọyọ to maa waye lopin ọsẹ yii, aarin awọn agba oṣelu atawọn oludibo ti ki i ṣoloṣelu lo wa. Awọn oludibo si ree, wọn pọ ju awọn agba oṣelu lọ, ibo wọn si lo n gbe oloṣelu wọle. Ṣugbọn awọn agba oṣelu lo n tọka ibi ti ọpọ oludibo wọnyi maa dibo wọn si, awọn lapaṣẹ ibo, awọn ni wọn si mọ ayinnike rẹ. Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, o dọjọ idibo ka too mọ tẹni ti yoo ṣẹ ninu wọn.

(46)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.