Ibo abele to gbe mi wole yii lo daa ju ninu itan ijoba awa-ara-wa ni Naijiria__Atiku

Spread the love

Alaaji Atiku Abubakar ti won sese dibo yan ninu egbe oselu PDP lati dije dupo aare lodun to n bo ti so pe latari bi egbe oselu APC se ja awon araalu kule, ti won ko si seto ijoba to daa, leyii to mu ki won ba oro aje wa je, o ni gbogbo araalu lo n pongbe fun ipadabo egbe oselu PDP nile Naijiria, nidii eyi, awon ko ni i ja won kule.

O soro yii niluu Portharcourt lasiko to n ka iwe pe oun gba lati soju egbe PDP lasiko ibo ti yoo waye lodun to n bo ohun.

Atiku sapejuwe eto idibo to waye ohun gege bii eyi to daa ju latigba ta a ti bere eto ijoba awa-ara-wa tuntun ta a wa yii. O ni eto naa lo bo se ye, ko si ojoro tabi awuruju kanakn ninu. O ni ki i se pe ki egbe awon kan ri, ki won si toka awon isoro ro n koju Naijiria nikan, awon gbodo setan lati wa ojuutu si isoro yii, ki opin si de ba a.

O ni gbogbo omo Naijiria lo n pongbe fun ipadabo egbe oselu PDP bayii nitori pe won ti to egbe oselu APC wo, won si ti mo iyato laarin mejeeji bayii. Okunrin naa salaye pe laye isejoba PDP, awon eeyan mo pe idagbasoke wa, isokan wa, igbe aye irorun si wa fawon araalu yato si bi nnkan se ri bayii. O ni anfaani nla lawon ni bayii lati da egbe oselu PDP pada sori aleefa.

Bakan naa lo dupe lowo awon ti won joo dupo naa fun emi isokan ti won ni, ti won mu isokan egbe ni pataki ju ife okan enikookan lo.

Bakan naa lo ni oun ni iriri to to fun ipo naa pelu bi oun ti se figba kan je igbakeji aare orileede yii. Bee lo fi kun un pe bi Olorun ba se e ti egbe awon ba dori ipo, awon ko ni i je ki ipo naa ko si awon lori, awon setan lati sise takuntakun ki ayipada rere le de ba araalu.

O dupe lowo Oloye Olusegun Obasanjo to yana an lati se igbakeji re nigba ti won jo sejoba. O ni bi ki i baa se pe Obasanjo fun oun ni anfaani naa, oun ko ba ma ti ni anfaani lati dupo tabi wole gege bii oludije lonii.

Agbegbe wo ni igbakeji aare yoo ti wa

Bo tile je pe ajo eleto idibo fi aaye sile fun awon omo egbe naa lati mu igbakeji won wa lasiko ti won ba yan an, ti won ko si fi gbedeke le e bii ti ipo aare, ko ti i seni to mo eni ti yoo se igbakeji fun Atiku bayii, nitori okunrin naa ko ti i kede re.

Bi awon kan se n so pe ile Yorba ni yoo ti mu igbakeji ni awon kan n so pe ile Ibo ni igbakeji re yoo ti wa nitori o jo pe ibo awon ara agbegbe naa lo gbe e wole.

Gbogbo aown omo egbe ni won ti n sare kiri bayii ti onikaluku si n lo gbogbo agbara re lati ri i pe ipo igbakeji naa bo si agbegbe awon, yato si ile Hausa ti ko ni anfaani lati tun fa igbakeji kale nitori pe ibe ni Atiku ti yoo dupo aare ti wa.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.