Ibo abẹle APC l’Ekoo Ambọde, Sanwoolu ati Amzat yoo koju ara wọn lọsẹ yii

Spread the love

Pẹlu bi nnkan ṣe ri lagbo oṣelu lọwọlọwọ nipinlẹ Eko, o ti han gbangba pe Gomina Akinwumi Ambọde, Ọgbẹni Jide Sanwoolu ati Dokita Jide Hamzat ni yoo jọ koju ara wọn lasiko ibo abẹle ẹgbẹ naa ti yoo waye lopin ọsẹ yii. Eyi ko ṣẹyin bi awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ṣe fi dandan le e pe awọn ko le yan Ambọde nikan lati dije, afi ki oun atawọn ẹgbẹ rẹ yooku jọ dibo abẹle, ẹni to ba si wọle naa ni awọn faramọ.

Gbogbo awọn tọrọ kan ni wọn ti n sare kiri lati ri i pe awọn rọwọ mu ninu ibo abẹle ọhun. Bẹẹ ni iṣẹ ti n lọ labẹlẹ laarin awọn eeyan yii lati ri i pe wọn wa ojuure awọn oludibo lati le ri ibo wọn.

Ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn alaga ijọba ibilẹ mẹtadinlọgọta to wa niluu Eko fi ọkan ọkan ninu awọn oludije sipo gomina nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwoolu, balẹ, ti wọn si ni gbagbaagba lawọn wa lẹyin rẹ lati ri i pe o yege ninu eto idibo abẹle ti yoo waye nipinlẹ Eko lopin ọsẹ yii.

Ileri yii waye lẹyin ipade ti oludije naa ṣe pẹlu awọn eeyan naa ni ileetura Water Creset, to wa niluu Ikẹja, leyii ti igbakeji alaga ijọba idagbasoke Ikosi-Isheri to jẹ alaga awọn ẹgbẹ yii, Arabinrin Bọlanle Bada, ti sọrọ lorukọ wọn. Awọn ẹgbẹ naa ṣeleri lati ṣatilẹyin fun Sanwoolu, ki wọn si dibo fun un pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ yooku lati ri i pe oun lo jawe olubori nibi eto idibo abẹle lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu eto idibo gomina ti yoo waye lọdun to n bọ.

Wọn sọ pe awọn yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ atawọn oloye ẹgbẹ yooku lati ri i pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ.

Bakan naa ni ọkan ninu awọn agbaagba ẹgbẹ ọhun to wa nibi ipade yii, Cardinal James Ọdunbaku, sọ pe ọkan oun balẹ pe Sanwoolu yoo rọwọ mu nibi eto idibo abẹle naa, oun ni yoo si bori lati ṣoju ipinlẹ Eko lorukọ ẹgbẹ APC.

Lara awọn to tun wa nibi ipade naa ni Alaaji Kaoli Olusanya ati Alaaji Ganiyu Badmus.

Pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, Babajide Sanwoolu ati Gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Akinwumi Ambọde ati Dokita Jide Hamzat ni wọn yoo jọọ dije nibi ibo abẹle naa.

Eyi waye pẹlu bi gbogbo ẹbẹ ti Gomina Akinwumi Ambọde bẹ awọn agbaagba ẹgbẹ yii ati Aṣiwaju Tinubu lati fa a kalẹ gẹgẹ bii oludije ti ko ni alatako ṣe forisanpọn. Ṣe lati bii ọsẹ diẹ sẹyin ni awuyewuye ti n waye lori boya wọn yoo fa ọkunrin naa kalẹ lati dije tabi bẹẹ kọ, iyẹn nigba ti awọn meji mi-in lọọ gba fọọmu lati tun dupo yii kan naa, leyii ti ki i fi bẹẹ waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC, paapaa nigba ti gomina naa ṣi ni anfaani lati tun lọ lẹẹkeji.

Bo tilẹ jẹ pe Ambọde ja fitafita lati ri i pe eleyii ṣee ṣe pẹlu bo ṣe yan awọn ẹlẹbẹ loriṣiiriṣii si Tinubu, bẹẹ ni Aarẹ Buhari pẹlu alaga ẹgbẹ wọn, Adams Osihomhole, pẹlu awọn gomina paapaa da sọrọ ọhun, ṣugbọn to jẹ pe ibi pẹlẹbẹ ni ọrọ naa fi n lelẹ.

Lọsẹ to kọja ni opin de ba gbogbo awuyewuye yii, iyẹn nigba ti awọn aṣaaju ẹgbẹ to maa n ri si iru ọrọ to ba jẹ mọ bayii pade nipinlẹ Eko ni Satide, ọsẹ to kọja lori ọrọ Ambọde, ti wọn si fẹnuko pe ki kaluku lọọ dan agbara rẹ wo ninu ibo abẹle ni, ẹni to ba si wọle ni wọn yoo fun lanfaani lati ṣoju ẹgbẹ nibi ibo to n bọ naa.

Loootọ ni awọn eeyan naa sọ bayii, ṣugbọn gbogbo eeyan lo mọ pe yoo le diẹ fun Gomina Ambọde lati tun gba ipo yii pada nitori igbagbọ wa pe Ọgbẹni Sanwoolu ni Tinubu atawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ to da silẹ ti wọn n pe ni ‘Mandate Group’ n ṣatilẹyin fun, ko si si ani ani kan nibẹ, ibi ti wọn ba lọ lawọn ọmọ ẹgbẹ yooku naa yoo lọ.

Latibẹrẹ wahala ọhun ni awọn ọmọ ẹgbẹ ‘Mandate Group’ yii si ti n tẹle Sanwoolu kaakiri, ti wọn ti n sọ pe oun ni yoo di gomina Eko lọdun to n bọ.

Bo tilẹ jẹ pe Aṣiwaju ẹgbẹ naa, Oloye Bọla Tinubu, sọ jade ninu fidio kan to gba ori ẹrọ ayelujara kan pe ẹnikẹni to ba ni oun n ṣe atilẹyin fun oun n tan ara rẹ jẹ ni, o ni oun ko si lẹyin ẹnikẹni, ki gbogbo wọn lọọ dibo, awọn ọmọ ẹgbẹ ni yoo si fi ibo wọn sọrọ si ibi ti wọn ba fẹ. O ni niwọn igba to jẹ pe nigba toun naa fẹẹ dupo sẹnetọ ati gomina, ibo ni wọn fi yan oun, awọn ọmọ ẹgbẹ naa lo dibo, igbesẹ yii kan naa lawọn pẹlu yoo tẹle.

Ṣugbọn ọpọ eeyan ni ko gba ọrọ yii gbọ, wọn ni baba naa ni iromi to wa labẹ omi to n lulu fun Sanwoolu, wọn ni ti ko ba si atilẹyin Tinubu nibẹ, wọn ko bi ọkunrin naa daa ko ni oun fẹẹ dupo gomina.

O jọ pe awọn alatilẹyin Gomina Ambọde toun naa ti mura lati dupo gomina ti ri i pe idasi Ọlọrun nikan lo ku ti ọkunrin naa fi tun le pada sile ijọba lo fi di afadurajagun, to si n gbadura lojoojumọ, bẹẹ ni awọn eeyan ilu Ẹpẹ paapaa ti wọle adura fun un bayii, wọn n gbadura kikankikan pe ki iyanu ṣẹlẹ si ọkunrin yii.

Bakan naa ni olori ileegbimọ aṣofin Eko tẹlẹ, Ọgbẹni Adeyẹmi Ikuforiji, rọ gbogbo awọn ọmọ ilu Ẹpẹ ati awọn alatilẹyin gomina yii lati wọle adura, ki wọn si maa gba a kikankikan fun Ambọde, nitori adura lọrọ rẹ gba bayii lati pada sile ijọba. Bẹẹ lo ni ki wọn ma sọ ireti nu, nitori ko si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe.

Satide ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, ni ibo abẹle naa yoo waye, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ yoo ti yan ẹni ti wọn ba fẹ ko ṣoju wọn lati dupo gomina lọdun to n bọ. Bi ọrọ naa yoo ṣe lọ lawọn eeyan n reti bayii.

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.