Ibo abele APC ko ti i lojo nipinle Ogun

Spread the love

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin lori ibo pamari yii, ẹgbẹ APC ipinlẹ Ogun ko ti i le sọ pato ọjọ ti ibo ọhun yoo waye.

Loooto ni wọn pepade kan si gbọngan Mitros, n’Ibara, laaarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ana yii, ti gbogbo ẹgbẹ peju, ti Gomina Ibikunle Amosun paapaa si sare wa lati papa iṣere M.KO Abiọla to ti lọọ sọrọ lori ayẹyẹ ọdun ominira Naijiria, ṣibẹ, wọn ko le sọ ọjọ gan-an ti ibo naa yoo waye.

Gomina ko duro pẹ, bo ti sọrọ lowelowe pe awọn to fẹẹ ṣeto ọhun, atawọn ondije to ku lẹru n ba lo ti tun pada si papa iṣere to ti wa.

Ṣugbọn ko too lọ lọjọ naa, Amosun sọrọ lori awọn ondije dupo gomina lẹgbẹ APC ti wọn ni awọn alagbara fẹẹ pa awọn, tabi ji awọn gbe. O ni ko ṣeni to fẹẹ pa wọn, awọn ni wọn fẹẹ para wọn nitori ohun ti ko sọnu ti wọn n wa kiri.

Amosun sọ pe labẹ bo ti wu ko ri, Adekunle Akinlade ni gomina lọdun to n bọ, bo wu awọn to fẹẹ waa ṣeto ọhun ki wọn ma mu deeti kia, bo si wu awọn ondije dupo yooku ki wọn takiti, ẹni ti Ọlọrun fẹ ni Ọlọrun yan ni.

Abuja la gbọ pe awọn ti wọn yoo kede ọjọ idibo naa yoo ti wa, aago mẹjọ aarọ ni wọn pe ipade ọhun, ṣugbọn wọn ko bẹrẹ titi di aago mọkanla aabọ.

Titi ti a si fi pari iroyin yii, awọn ikọ ti yoo dari ibo naa ko ti i de s’Abẹokuta.

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.