Ibo 2019: Wahala ti ba awọn gomina ilẹ Yoruba o

Spread the love

Ni ọdun mẹrin sẹyin, ko sẹni to le sọ pe ohun to ṣẹlẹ si Gomina Raufu Aregbẹṣọla lọjọ Jimọ ọsẹ to kọja yoo ṣẹlẹ si i nibikibi ni ipinlẹ Ọṣun. Ki i ṣe eni, ki i ṣe ana, ni ọkunrin naa ti n lọọ kirun ni gbogbo ọjọ Ẹti, Furaidee yii, bo ba si ti kirun rẹ tan bẹẹ ni yoo maa wa mọto lọ laarin ilu, tawọn eeyan yoo si maa sare tẹle mọto rẹ lẹyin, ti wọn yoo maa jo, ti wọn yoo maa yọ ki i. Ṣugbọn ti ọsẹ to kọja yii ko ri bẹẹ rara. Loootọ awọn eeyan naa sare tẹle mọto rẹ bo ti n jade ni mọṣalaaṣi, ṣugbọn ariwo buruku ni wọn n pa le e lori, “Arẹgbẹṣọla oole! Arẹgbẹṣọla oole!” ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ariwo ti wọn n pa, ko si si ibi ti wọn wa mọto naa gba ti wọn ko ti pariwo le e lori. Ohun to fa gbogbo eleyii ko ju bi wọn ti ṣe ọrọ ibo APC to waye ni ipinlẹ naa lọ, nibi ti awọn araalu ti gba pe ẹgbẹ APC fi eru gba ibukun ni.

Gomina Arẹgbẹṣọla niyi daadaa tẹlẹ ni ipinlẹ Ọṣun, awọn eeyan si fẹran rẹ, ṣugbọn lẹnu ọjọ mẹta yii ni nnkan yi biri, wọn si koriira rẹ bii igbẹ ni. Iṣoro to wa bayii ni pe Arẹgbẹṣọla ni i lọkan tẹlẹ lati lọ si ile-igbimọ aṣofin, ko maa ba oṣelu rẹ lọ nibẹ, ko si maa gun oke, ṣugbọn oun naa ti ri i pe ki i ṣe ọdun yii, koda, ko le jẹ ọdun mẹrin si asiko yii ni yoo tun pada lati waa du ipo kankan ni ipinlẹ Ọṣun. Bo ba dan an wo, wọn yoo le e, ẹsẹ rẹ ko ni i balẹ, ko si jọ pe oun naa ṣetan lati duro paapaa mọ, o fẹẹ pada si Eko nibi to ti wa. Eko naa ki i ṣe ibi ti yoo ti ri ipo mu, nitori awọn ara Eko n sọ pe oju awọn ti la, Arẹgbẹṣọla ki i ṣe ọmọ Alimọṣọ tabi ọmọ Agege, Ijẹṣa ni, bi yoo ba si dupo yoowu bayii, wọn ni Ileṣa ni yoo ti lọọ du u, ki i ṣe ko jokoo si Eko ko tun maa paṣẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ nibẹ.

Eyi to n ṣẹlẹ si Gomina Akinwunmi Ambọde bayii le, nitori bo oun ati awọn olori ẹgbẹ wọn l’Ekoo ti kọju ija si ara wọn. Ija naa le debii pe ko si ọna ti yoo gba bayii ti yoo ṣe gomina ipinlẹ naa lẹẹkeji, nitori bo ba gbe ẹsẹ kan, ibi ti awọn ọta rẹ yoo gba yọ si i ko ni i dara rara. Ti Gomina Ibikunle Amosun naa ko fi bẹẹ yatọ, nitori oun ati awọn aṣaaju ẹgbẹ tirẹ naa ni ipinlẹ yii ko fi bẹẹ gba ti ara wọn, bo si tilẹ jẹ pe wọn ti dibo to jẹ ẹni ti oun fẹ lo wọle sibẹ, awọn aṣaaju ẹgbẹ yii ti ko fẹ ẹni to fa kalẹ ti yari mọ ọn lọwọ, wọn ko si ṣetan lati ba a ṣe. Erongba toun naa ni lati lọ si ile-igbimọ aṣofin agba, ko si di sẹnetọ lẹẹkan si i, o ti gba fọọmu, o si ti sanwo, ṣugbọn ko jọ pe ọna kankan wa to fi le koju awọn araalu pe ki wọn dibo foun, bẹẹ lawọn aṣaaju APC ibẹ ko si ṣetan lati fa a kalẹ.

Awọn araalu ni ko fẹran Isiaka Abiọla Ajimọbi ti i ṣe gomina Ọyọ ni tirẹ, bo ba jẹ ti ẹgbẹ oṣelu rẹ ni, apa rẹ ti ka ẹgbẹ naa bayii. Ẹni kan ṣoṣo to n ba a ta kangbọn ninu ẹgbẹ yii, to si ti ko pupọ ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ naa si ọdọ ara tirẹ ni Minisita Adebayọ Shittu to wa ni Abuja, ṣugbọn ọrọ mi-in ti ba ẹyin yọ fun minisita naa, nitori wọn ni ko ni iwe ẹri agunbanirọ, ọkunrin naa si ti gbe jẹẹ, nitori ko si ohun to le ṣe. Ẹni to fẹẹ du ipo gomina ipinlẹ naa paapaa,  Adebayọ Adelabu, eeyan ti Ajimọbi ni. Ṣugbọn Ajimọbi ni oun fẹẹ lọ si ile-igbimọ aṣofin, o fẹẹ lọọ ṣe sẹnetọ, ọpọlọpọ ọmọ Ibadan, paapaa ni agbegbe to ti wa yii ni wọn ti taku pe kaka ki Ajimọbi ri ibo nibẹ, awọn yoo dibo naa fun ẹgbẹ oṣelu mi-in ni. Awọn iwa ti ọkunrin yii hu si ọpọlọpọ ọmọ Ibadan lasiko to n ṣejọba lo fa wahala tirẹ yii o.

Ohun to n ṣẹlẹ ni Ondo yii ko ti i ye awọn eeyan, wọn ṣa kan ri i pe ọpọlọpọ awọn aṣaaju ati ọmọ ẹgbẹ APC to gbe gomina ibẹ, Ọgbẹni Rotimi Akeredolu, ko fẹ tirẹ mọ ni, wọn si fẹẹ ti i jade ninu ẹgbẹ yii, tabi ki wọn fọ ẹgbẹ naa mọ ọn lori. Ohun ti awọn yii n ṣe ni pe bi wọn ba ti le ja ẹgbẹ gba lọwọ rẹ, ko si bi yoo ti ṣe le wọle gomina lẹẹkeji, bẹẹ loun ti n pariwo pe saa meji ti gbogbo eeyan n lo loun naa yoo lo, ko si iṣẹ ti oun fẹẹ ṣe laarin ọdun mẹrin pere, afi ki toun naa pe ọdun mẹjọ. Awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin Tinubu nibẹ, iyẹn awọn ti wọn ba Akeredolu du kinni naa nibẹrẹ ti ri agbara gba pada, wọn si n lo agbara naa lati daamu gomina yii, nitori wọn ni oun ko mọ ọgbọn oṣelu rara, ko si mọ bi nnkan ti ṣe n lọ ni ipinlẹ naa ko too di pe o de. Boun yoo ṣe ri saa keji lo ni wahala rẹ, ti wọn o si ni i gba APC lọwọ rẹ ko too digba naa.

Bi ẹ ba fiye si i, ki i ṣe gbogbo igba ni Ayọdele Fayoṣe n da sọrọ oṣelu mọ, koda, o ti sinmi nipa rẹ to ọjọ meloo kan. Lati igba ti wọn ti gba ipinlẹ naa lọwọ rẹ, iyẹn nigba ti wọn ko jẹ ki ẹni to fa kalẹ wọle gẹgẹ bii gomina ni ọkunrin naa ti gbe jẹẹ, eyi to si n ba a lẹru ju bayii ko ju ti okun ti awọn EFCC dẹ silẹ fun un lọ. Oriṣiiriṣii awọn eeyan to mọ pe wọn le ṣe ọna oun ni rere lo ti ba sọrọ, ẹni kan to si ni agbojule ju ninu rẹ naa ni Musiliu Ọbanikoro, ẹni ti awọn EFCC jọ fi ẹsun ole kan, to si ti ṣetimọle tirẹ, to ti tun da owo diẹ pada fun ijọba. Alaroye gbọ pe Ọbanikoro lo n ba Aṣiwaju Bọla Tinubu sọrọ lori ọna ti wọn yoo fi gba yọ Fayoṣe kuro lọwọ awọn EFCC, bẹẹ ni Fayoṣe funra rẹ naa si n ba awọn agba lọọya kan sọrọ pe ki wọn ma jẹ ki EFCC yii yẹyẹ oun. Eyi ni wahala tirẹ, bo ba si bọ lọwọ EFCC, yoo sinmi fungba diẹ naa ni.

Ko si ohun ti iba fa wahala kankan fun Abdlufattah Ahmed ni Kwara, ṣugbọn iṣoro to ni ni ọrọ ti Saraki ati awọn ti wọn n ba a ja yii. Ibi to wu oun naa lati lọ ni ile-igbimọ aṣofin agba, ṣe ibi ti gbogbo awọn gomina naa n lọ niyẹn. Ṣugbọn wahala to ti ba ẹgbẹ APC ti gbogbo wọn fi rọ lọ si inu PDP, ati bi wọn yoo ṣe le fa oun naa kalẹ ninu ẹgbẹ yii, ti awọn eeyan yoo si tun dibo fun wọn. Yatọ si eyi, oriṣiiriṣii ẹjọ lawọn EFCC ti to kalẹ foun naa, wọn loun lo n fẹyin pọn Saraki ti wọn ko fi rowo to ji ko nile ijọba gba pada lọwọ ẹ, bi awọn ba si mu un, yoo ṣalaye awọn owo yii fawọn ki awọn too fi i silẹ. Ohun to daju ni pe bi Saraki ba le bọ ninu iṣoro rẹ, to de ipo to n wa, Abdulfattah naa ko ni i niṣoro kan, yoo maa gbadun ni. Ṣugbọn wahala Saraki ni wahala tiẹ naa: bi Saraki ba jin si koto, oun ati Ahmed ni.

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahya Bello, mọ pe ko sohun to gbe oun wọle bi ko jẹ iku to pa Abubakar Audu tawọn eeyan dibo fun ni 2015, o si mọ pe agbara APC igba naa loun lo. Ṣugbọn awọn ti wọn ṣe APC nigba naa ti rọ wọ inu PDP, agaga ọkan ninu awọn aṣaaju wọn, Dino Melaye. Dino ati gomina yii ti dọta, eyi si ni Dino ṣe kuro ni APC. Ẹru n ba Bello bayii pe njẹ yoo ṣee ṣe foun lati bori lasiko to ku oun nikan yii, bawo loun yoo ṣe ṣe e ti oun yoo fi tun di gomina. Ohun to jẹ ko maa sare tẹle Buhari ree, to si n fi owo ipinlẹ naa ra fọọmu, o n ṣe awọn nnkan mi-in ki Buhari le ri i, bo tilẹ jẹ pe ko ri owo-oṣu awọn eeyan ipinlẹ rẹ san. Sibẹ naa, awọn alatako rẹ ko duro o, wọn ti ni ko si ibi ti yoo gbe e gba ti yoo fi tun ṣe gomina ipinlẹ Kogi, oun ko si fẹẹ fi ipo naa silẹ, wahala rẹ gan-an niyẹn.

Ohun ti eleyii mu dani fun gbogbo ilẹ Yoruba bayii ni pe awọn gomina wọnyi ko raaye ṣe ijọba ipinlẹ wọn mọ, ko si eto idagbasoke kan to si n lọ nibi kan, afi oṣelu nikan ti wọn n ṣe. Adura ti awọn araalu n gba bayii ni ki ọrọ oṣelu naa tete kọja lọ jare, ki awọn gomina yii le raaye gbaju mọ iṣẹ ilọsiwaju ilu to yẹ ki wọn ṣe gan-an.

 

 

(75)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.