Ibọn ti Niyi fi n ṣiṣẹ ọdẹ loun atọrẹ ẹ fi lọ jale n’Ibadan.

Spread the love

Awọn ọrẹ meji kan, Adewale Adegoke ati Adigun Niyi ti wọn sọ ole jija diṣẹ ti dero ahamọ awọn ọlọpaa bayii. Owo ati foonu ni wọn fipa gba lọwọ awọn eeyan pẹlu ibọn.
Ni nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to lọ lọhun-un ni Adegoke Adewale ati Adigun Niyi lọọ ka awọn olugbe adugbo Abaniṣe, lagbegbe Mọniya, n’Ibadan, mọle pẹlu ibọn, ti wọn si fipa ja wọn lole owo ati ẹrọ ibanisọrọ wọn.
Ọwọ́ kì í pẹ́ nisa àkeekèé ni wọn fi ọrọ ṣe pẹlu bo ṣe jẹ pe ni kete ti wọn pari iṣẹ buruku naa tan ni wọn ti pin gbogbo nnkan ti wọn ri ji mọwọ láàjìn alẹ naa
Eyi to kan Adewale ninu awọn ẹru naa lo n ko lọ sile to fi ko sọwọ awọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ fun aabo ilu, paapaa lagbegbe Mọniya, n’Ibadan, loru ọjọ naa. Ẹrọ ibanisọrọ marun-un ọtọọtọ ti wọn ba lọwọ afurasi ole ẹni ọdun mẹtalelogun (23), naa lo tu u laṣiiri.
Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Abiọdun Odude, ẹni to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan sọ pe ki ilẹ ọjọ naa too mọ lawọn agbofinro ti wa Niyi kan, ti wọn fi sọ awọn mejeeji satimọle.
Gẹgẹ bi iwadii ṣe fi ye ni, ileeṣẹ nla kan ti wọn ti n ṣe ọsin adiẹ ati ẹlẹdẹ labule kan ti wọn n pe ni Olórìṣàoko, nitosi Ibadan, ni Niyi ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọdẹ. Ibọn ibilẹ to si n lo fun iṣẹ ọhun ni wọn mu lọ sibi idigunjale naa.
Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ ẹ fakọroyin wa, Adewale sọ pe ainiṣẹlọwọ mọ lo sun oun dedii ole jija ati pe Niyi lo gba oun nimọran lati lọọ ṣịṣẹ ibi naa.
Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun naa ṣalaye pe, “Mọniya (n’Ibadan), lemi ati Niyi ti pade. Ibi iṣẹ birikila ta a jọ n ṣe tẹlẹ la ti mọra ka too pada pade ni Mọniya. O sọ fun mi pe inu ọgba ti wọn ti n sin awọn nnkan ọsin loun ti n ṣiṣẹ. Oun lo fun mi lounjẹ titi ti ilẹ ọjọ yẹn fi ṣu.
“Nigba ti ilẹ ti ṣu patapata, a lọ si adugbo sọọmeeli (Saw Mill), lọọ jale. Ile mẹta la fọ́ lalẹ ọjọ yẹn. Awọn ile ti wọn fi igi ṣe ilẹkun wọn nikan la ja lole nitori awọn ilẹkun onigi ko ṣoro o já.
“Ẹgbẹrun meje ati aadọjọ Naira (N7,150), ni gbogbo owo ta a ri ji. A si ri foonu meje gba. Ṣugbọn nibi ti mo ti n ko owo atawọn foonu to kan mi ninu ẹru ta a pin lọ lawọn ọlọpaa ti da mi duro, ti wọn mu mi.
Niyi Adigun fidi ọrọ ọrẹ ẹ mulẹ, o ni oun loun mu Adewale lọ soko ole pẹlu ibọn ti oun fi n ṣiṣẹ ọdẹ, ṣugbọn o ya oun lẹnu pe Adewale lo tun pada mu awọn ọlọpaa waa ka oun mọle.
Gbogbo ẹrọ ibanisọrọ ti awọn afurasi adigunjale yii fipa gba lọwọ awọn ẹni ẹlẹni pẹlu ibọn ti wọn fi ṣiṣẹ ibi naa lawọn ọlọpaa ti gba pada lọwọ wọn.
Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii lawọn mejeeji ṣi wa lahaamọ awọn agbofinro. Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti n ṣakitiyan lati gbe wọn sile-ẹjọ.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.