Ibi ti Sẹmiu ti n ba ọmọ ọga ẹ lo pọ niyẹn ka wọn mọ n’Ibadan, o ti dero kootu

Spread the love

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn agba bọ, wọn ni iyan ogun ọdun a maa jo ni lọwọ. Bẹẹ lọrọ ri pẹlu ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun (21) kan, Sẹmiu Ọladimeji, ẹni to ba ọmọ ọga ẹ laṣepọ lọdun 2017, ṣugbọn to jẹ lẹyin ọdun meji, iyẹn lọdun 2019 yii, ni wọn ṣẹṣẹ gbe e lọ sile-ẹjọ.

Sẹmiu, to jẹ ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ lo ti sọ ọmọ ọga ẹ to n jẹ Anikẹ, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri di iyawo, to n ba a sun bo ṣe fẹ.

 Ọdọ Baba Anikẹ ni Sẹmiu n gbe ni Opopona Laniyan, laduugbo Idi-Iṣin, nitosi Jericho, n’Ibadan. Oun lo si maa n mu ọmọbinrin ti ko ju ọmọọdun mẹsan-an yii lọ sileewe laraarọ. Ṣugbọn nnkan ti awọn ọga ẹ ko mọ ni pe jagunlabi ti n ṣaáyan ọmọ wọn, afi lọjọ kan ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2017, ti ọga Sẹmiu to n jẹ Adewale ka a mọ ori ọmọ ẹ to n gbo o nigbokugbo.

Wọn ti kọkọ ṣe ọrọ naa ni òkú òru lati igba naa, paapaa nigba to jẹ pe ọmọ ni Sẹmiu naa jẹ si idile Adewale. Wọn ko si gbero lati fiya kankan jẹ ẹ, afigba to sọ iwa aitọ naa di aṣa, to fẹẹ jẹ pe gbogbo ibi kọlọfin to ba ti kù ú ku ọmọ ọga ẹ to jẹ bii aburo si i, lo n ki ọmọọlọmọ mọlẹ, to n gbọn ọn lara nù.

Gẹgẹ bii iwadii akọroyin wa, ounjẹ agba ti Anikẹ paapaa n jẹ nigba gbogbo ti la a loju ni àlàsódì, ọrọ kan ko ti i loju lati sọ mọ. Eyi lo jẹ ki awọn obi ẹ woye pe bi awọn ko ba tete wa nnkan ṣe lori ọrọ yii, Sẹmiu yoo fi kinni ẹ ba aye ọmọ jẹ fun awọn patapata.

Lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii (31-05-2019), ni iya Anikẹ gbera, o di ọfiisi awọn ẹṣọ alaabo ilu ti wọn n pe ni Sifu Difẹnsi n’Ibadan. O ni latigba ti Sẹmiu ti ba ọmọ oun laṣepọ lọmọ naa ti ya aṣa, to di pe ko huwa ọmọluabi mọ, ti ko si mọ ọrọ kan ni eeyan ki i sọ jade lẹnu.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Anikẹ sọ pe tipa-tikuuku lọmọọṣẹ baba oun fi ba oun laṣepọ lọjọ to kọkọ ṣe kinni naa foun. O ni niṣe lo fi okùn so oun lẹnu pa ti oun ko si lanfaani lati pariwo sita.

Bi ọrọ ko ba tilẹ ri bẹẹ nipa okun ti Anikẹ sọ pe Sẹmiu fi so oun lẹnu pa nitori ti ẹnu ko da bii igi ta a le ri di lokun, ohun to daju ni pe ọpọ igba ni iwa aitọ yii ti ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji pẹlu bi ọmọdebinrin naa ṣe sọ pe ẹẹmẹrin ọtọọtọ lọkunrin naa ti ba oun laṣepọ ko too di pe aṣiri tu.

Ọmọbinrin yii fidi ẹ mulẹ siwaju pe aburo oun ọkunrin kan naa ti ka awọn mọ idi ere egele yii lọjọ kan ri, ṣugbọn ko tu aṣiri iṣẹlẹ ọhun fẹnikẹni.

Lẹyin imọran lati ọdọ Ọgbẹni Adeọla Badru ti i ṣe ọga agba wẹ́fíà, iyẹn ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n ri si igbaye-gbadun araalu, awọn Sifu Difẹnsi ti gbe Sẹmiu lọ sile-ẹjọ.

Gẹgẹ bi ẹsun ti Ọgbẹni Afẹ Oluranti to ṣoju ọga agba ajọ yii ni kọọtu ka si olujẹjọ naa lẹsẹ niwaju adajọ, “Sẹmiu Ọladimeji 21 nigba kan ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2017, ni plot 6/7, Ọlaniyan Cresent, fipa ba Anikẹ to jẹ ọmọọdun mọkanla laṣepọ. Eyi lodi si abala ọtalelọọọdunrun-o-din-meji (358) iwe ofin ipinlẹ Ọyọ ọdun 2000, eyi to ṣe iwa ọdaran leewọ, to si ṣagbekalẹ ijiya fun ẹni yoowu to ba rufin naa.

Sẹmiu jẹwọ pe loootọ loun huwa ibajẹ naa. O ni oun loun maa n mu ọmọ yii lọ sileewe laraaarọ. Lọjọ ti ẹmi eṣu ọhun kọkọ gbe oun wọ, niṣe loun kọkọ gbe Anikẹ sori itan oun. Lẹyin naa loun tọwọ bọ ọ loju ara ni igba bii mẹrin ki oun too kuku ki kinni oun bọ ọ nigba to ka oun lara tan.

O fidi ẹ mulẹ pe lọjọ ti aṣiri oun yoo tu, baba ọmọ yii funra ẹ lo ka oun mọ ibi ti oun ti n ba a ṣere egele.

Igbẹjọ naa ṣi n tẹsiwaju ninu waju Onidaajọ Taiwo Ọladiran ti ile-ejọ Majisireeti to wa ni, Iwo Road, n’Ibadan.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.