Ibi ti ọrọ adajọ agba yii n lọ ko maa daa o

Spread the love

Kinni kan ba ijọba yii jẹ, iyẹn naa ni irọ pipa, abi bawo lawọn eeyan yoo ṣe jokoo maa parọ oriṣiiriṣii bayii. Ni ọsẹ to kọja lọhun-un ni ariwo bẹrẹ lori olori awọn adajọ pata, iyẹn adajọ agba ilẹ wa, Adajọ Walter Onnoghen, ti wọn ni ijọba ni awọn n gbe e lọ si CCT, nibi ti awọn yoo ti ba a ṣẹjọ pe ko sọ awọn ohun-ini rẹ to ni fun ijọba nigba to gba iṣẹ yii. Ọrọ naa di ariwo, nijọba ba jade, koda, Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, lo jade to sọ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yẹn, Buhari ko mọ si i rara, ko mọ pe wọn n ba adajọ agba naa ṣe ẹjọ, awọn si ti yanju ọrọ naa, ko sẹni to fẹẹ ba olori adajọ naa ṣe ẹjọ kankan, ko maa ṣe iṣẹ rẹ lọ lalaafia ni. Ko ju ọjọ keji to sọ eyi lọ ti wọn fi ni ijọba apapọ ti gbẹsẹ le gbogbo akaunti ti adajọ agba yii ni ni banki, iyẹn ni  gbogbo ibi to lowo si, ko le gba owo kankan jade nibẹ, nitori ijọba ti fi ofin de awọn owo naa mọ banki, wọn si ti sọ olori adajọ yii si kolombo. Iyẹn n lọ lọwọ ko ti i tan ni wọn tun ni ijọba fẹẹ wadii adajọ agba yii naa wo, ijọba apapọ yii kan naa ti Ọṣinbajo n ba ṣiṣẹ ni o. Eyi to wa nita bayii ni pe ijọba apapọ naa ti tun lọ si ile-ẹjọ, wọn ni ki ile-ẹjọ ba awọn yọ Onnoghen kuro ni ipo adajọ to wa, ati ipo olori igbimọ awọn adajọ. Ohun ti awọn ọlọgbọn n beere ni pe ki lo n kan ijọba yii loju, ki lo n kan wọn loju gan-an? Kin ni awọn naa ni lẹru to n ba wọn lẹru, kin ni wọn di mẹru ti wọn ko fẹ ki aye ri? Bo ba jẹ ti adajọ agba yii ni, eeyan a maa le ekute ile ẹni ko fi apa rọ bi? Bo ba jẹ ọkunrin naa ṣe ohun kan ti ko dara, ẹgbẹrun saamu waa le sa mọ Ọlọrun lọwọ, ṣebi ibi iṣẹ yii naa lo wa, ọjọ meloo lo ku ti yoo fi ṣe iṣẹ rẹ, ti yoo si di araalu lasan lai ni i ni agbara kankan. Ki lo de ti ijọba yii, abi ka sọ pe awọn ọmọ Buhari fẹẹ ba eto idajọ jẹ, ti wọn yoo sọ kinni naa di yẹpẹrẹ nitori ẹni kan ṣoṣo. Ki lo de to jẹ lasiko ti ibo ku si dẹdẹ ni wọn ranti pe ọkunrin naa ṣẹ wọn lẹṣẹ kan. Awọn ibeere ti awọn eeyan n beere ree, ibeere to si n ba ni lẹru ni. Ohun to jẹ ki ẹru maa ba awọn eeyan ni pe o fihan pe ijọba yii ni nnkan aburu kan ti wọn fẹẹ ṣe lori ọrọ ọkunrin adajọ yii. Bi ẹ ba ti ri awọn ọmọ Buhari ti wọn n tako ẹnikan bayii, ti wọn si mura kankan lati ba tirẹ jẹ, nnkan kan wa nidii ẹ ni, bi wọn ko si ba ẹni naa kanlẹ, wọn ko ni i jawọ. Amọ eyi ko dara, ko ni i tun eto oṣelu Naijiria ṣe, bẹẹ ni ko ni i mu idagbasoke kan ba wa. Ẹ jawọ ninu iru awọn iwa bayii nitori Ọlọrun.

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.