Ibajẹ lẹ n ṣe nibẹ yẹn o.

Spread the love

Ni bayii, orukọ ileeṣẹ CCB ti gbajumọ daadaa, iyẹn ileeṣẹ ti wọn n pe ni Code of Conduct Bureau. Ileeṣẹ naa lo maa n ṣe akọsilẹ ohun-ini awọn oṣiṣẹ ijọba ki wọn too gba iṣẹ ijọba, ti wọn yoo si tun ṣe akọsilẹ ohun to ba sọ pe oun ni nigba to ba fi iṣẹ naa silẹ, ọdun mẹrin-mẹrin leeyan yoo maa lọ sibẹ ti yoo si maa sọ ohun to ni. Ileeṣẹ yii ni wọn fi tu aṣiri Bukọla Saraki si eti aye, nitori awọn ohun to ni oun ni ko too di gomina Kwara, nigba ti yoo fi jade, eyi to ni ti pọ ju bẹẹ lọ. Tiẹ tilẹ buru nitori nigba ti wọn yẹ ẹ wo daadaa, wọn ri i pe bi owo ti n jade lapo ijọba Kwara, bẹẹ ni ohun-ini Saraki n pọ si i ni tirẹ, ko si si tabi-ṣugbọn kan nibẹpe ogbologboo ole loun nile ijọba. Bo ba jẹ nibi ti eto oṣelu ati ijọba ti dara ni, Saraki ko ni i si laarin ilu, ẹwọn ni yoo wa ti yoo ti maa ṣaye. Ṣugbọn Saraki lu kinni naa pa, gẹgẹ bi Aṣiwaju Bọla Ahmed ti lu ẹjọ tirẹ naa pa nigba ti awọn Jonathan n halẹ mọ ọn. Ibẹ naa ni wọn ti ṣe ti adajọ agba wa tẹlẹ, Adajọ Walter Onnoghen, pa lọsẹ to sẹṣẹ kọja yii, ti wọn ni ohun-ini rẹ bayii yatọ si eyi to kọ silẹ tẹlẹ, ti wọn lo ti dọgbọn si i ni. Ileeṣẹ yii, ileeṣẹ ijọba ni, ofin si sọ pe ko gbọdọ si aṣiri kan nibẹ, gbogbo ohun ti wọn ba ni, bi araalu ba fẹẹ mọ ọn, bi awọn oniroyin ba ti le kọwe fun un, wọn gbọdọ gbe e sita ni. Ohun to mu ki awọn oniroyin Punch kọwe si ileeṣẹ naa lọsẹ to lọ lọhun-un niyẹn, nigba to ti jẹ aye aṣiri titu la wa, to jẹ gbogbo ẹni to ba ṣebajẹ, to ni ohun-ini ti ko yẹ ko ni nijọba n ba ja, ileeṣẹ Punch naa kọwe fun akọsilẹ ohun-ini awọn oloṣelu kan lọwọ CCB. Wọn ni ki wọn fun wọn ni akọsilẹ ohun-ini Aba Kyari to n ba Buhari ṣiṣẹ, ti Babatunde Faṣọla, Adebayọ Shittu, Lai Muhammed, Rotimi Amaechi, atawọn mi-in ti wọn wa nijọba Buhari. Ṣugbọn titi di bi a ti n wi yii, ileeṣẹ CCB ko da Punch lohun, wọn lawọn ko le fi aṣiri naa han wọn, bẹẹ eleyii ko ba ofin mu. Ohun ti ofin Naijiria wi kọ niyẹn rara, ofin Naijiria sọ ni pe ti awọn eeyan ba ti fẹ akọsilẹ ohun-ini awọn oṣiṣẹ ijọba tabi tawọn oloṣelu ti wọn n ṣejọba, ki CCB gbe e jade lẹsẹkẹsẹ ni. Ṣugbọn CCB ko le gbe e jade, nitori ninu gbogbo awọn ti wọn darukọ yii, ko si ẹni ti wọn yoo gbe akọsilẹ ohun-ini rẹ jade ti ko ni i ṣẹwọn, tirẹ yoo si buru ju ti adajọ agba ti wọn ki mọlẹ yii lọ. Ohun ti awọn eeyan ṣe n pe ileeṣẹ CCB yii ati ijọba Buhari ni aṣebajẹ niyẹn, nitori bo ba jẹ ti awọn ọmọ PDP tabi awọn alatako mi-in ni Punch beere, loju ẹsẹ ni ileeṣẹ yii yoo gbe e jade, ṣugbọn nitori pe ti awọn ọmọ APC ni bayii, ileeṣẹ naa dakẹ minimini. Igba wo waa l’Ọlọrun ko ni i mu gbogbo aṣebajẹ, ẹ mura si i daadaa!

 

 

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.