Iba pọnju-pọntọ kan wa lọdọ EFCC, awọn oloṣelu lo n mu

Spread the love

Iba buruku ni iba naa, akọ iba ni. Bo ba ti mu wọn, bẹẹ loju wọn yoo pọn kankan, bẹẹ ni itọ wọn naa yoo pọn buruku, iyẹn ni wọn ṣe n pe e ni iba pọnju-pọntọ. O da bii pe yara kan wa lọdọ awọn EFCC to n wadii awọn ti wọn ba kowo-jẹ to jẹ ibẹ ni akọ-iba yii wa, awọn oloṣelu nikan ni kinni naa si da mọ, nitori bi wọn ba ti debẹ lo n mu wọn. Ṣaṣa ni oloṣelu Naijiria to wọ ọdọ awọn EFCC ti iba naa ko ni i mu, nitori bi yoo ba fi to ọjọ kan si meji ti wọn debẹ, awọn dokita wọn yoo ti bẹrẹ si i sọrọ, awọn lọọya awọn oloṣelu yii yoo ti bẹrẹ si i pariwo, wọn yoo ni ara onibaara awọn ko ya, aisan kan ti wa lara ẹ tipẹ, aisan naa le jẹ ẹdọ rẹ tabi ko jẹ ẹ nifun to ba ti pẹ ju ni itimọle EFCC, abalọ ababọ si ni ki awọn EFCC tete fi i silẹ kia ko le lọọ tọju ara rẹ. Irọ gbuu! Ọrọ buruku lẹnu awọn ole! Ike Ekweremadu ni igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin agba, ọsẹ to kọja lawọn EFCC bo o mọle, wọn gbe e janto, wọn ni ko waa ṣalaye awọn owo kan to ko jẹ, ati awọn ile nla nla kan to ni ti ko ṣalaye funjọba pe oun ni iru ile bẹẹ nigba ti wọn n beere ohun to ni lọwọ rẹ. Bi wọn ṣe gbe e ti wọn bẹrẹ si i bi i leere ọrọ, bẹẹ ni wọn ni ẹjẹ rẹ ru, iba pọnju-pọntọ yii mu un, awọn dokita to n tọju rẹ tẹlẹ, ati awọn lọọya, ati awọn oloṣelu ẹgbẹ rẹ si n pariwo pe ki EFCC ma jẹ ki Ekweremadu ku sawọn lọdọ o, ki wọn yaa fi i silẹ kia. Ki lo de to jẹ eeyan ki i gbọ aiyaara awọn oloṣelu Naijiria, afi igba ti EFCC ba mu wọn. Ki lo de ti ara awọn eeyan yii kọ itimọle bayii na! Bẹẹ awọn ree, wọn ko le ṣe ki wọn ma jale. Ẹni ti ko ni oogun arindọ ki i jẹ aayan, tawọn oloṣelu Naija kọ. Wọn yoo jale, wọn yoo ko owo jẹ, wọn ko si ni i fẹẹ sun itimọle. Iru awọn eeyan wo ree na. Ọlọrun yoo ma gba wa lọwọ wọn o. Ekweremadu, jẹ ki ara rẹ tete ya o, owo to sọnu lawọn EFCC n beere, ṣalaye ibi ti owo wa ati bi ọrọ awọn ile ti jẹ ki o si maa lọ lalaafia ara. Ṣugbọn bi o ko ba ṣalaye, awa paapaa fọwọ si i ki iba naa maa le si i lọdọ awọn EFCC nibẹ. Ko ju bẹẹ lọ ojare.

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.