Iṣoro gidi ni fun Jagaban

Spread the love

Yoo ṣoro gidi fun un, ati ni tootọ, iṣoro gidi ni fun Jagaban lati so pe Abubakar Atiku ki i ṣeeyan daadaa, tabi pe ko yẹ lẹni ti ki wọn dibo fun ni Naijiria. Iṣoro gidi ni fun Jagaban lati sọrọ pe Buhari daa ju Atiku yii lọ, nitori ni ọdun 2007, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lo n ru Atiku kaakiri ilẹ Yoruba, bẹẹ lo si tẹle e de ilẹ Hausa, o tẹle e de ilẹ Ibo, ko sibi ti ko ba a de, to n sọ pe ko sẹni ti yoo se ijọba Naijiria daadaa ju Abubakar Atiku lọ. Iṣoro gidi ni fun Jagaban lati sọ pe Buhari daa ju Atiku lọ, nitori ni 2007, Buhari jade ibo, Tinubu si sọ pe bi Naijiria ba fẹẹ ri ifasẹyin nikan ni wọn le dibo wọn fun Buhari, ẹni kan ṣoṣo ti yoo mu ilọsiwaju ba wọn ni Atiku. Iṣoro ni fun Jagaban lati sọ pe oun ko mọ Atiku mọ nitori nigba naa, ohun to n sọ fun gbogbo eeyan ni pe oun mọ Atiku deledele, oun si mọ pe ẹni kan ṣoṣo ti ko fẹran ẹlẹyamẹya ni, oun mọ pe ninu gbogbo aṣaaju Naijiria to ti jẹ, ti Atiku ni yoo jẹ ara ọtọ, nitori yoo lo gbogbo ọgbọn okoowo to ti ni lati fi gbe Naijiria yii ga ni. Iṣoro ni fun Jagaban lati sọ pe ki i ṣe pe oun fẹẹ ṣi ọmọ Naijiria lọna bayii ni bo ba n sọrọ siwaju, to n sọ sẹyin. Iṣoro ni fun Jagaban to ba sọ pe ade gun ri, to tun waa jade to n fi ẹnu rẹ kan naa sọ pe ade ko gun mọ. Iṣoro ni fun Jagaban lati maa ba orukọ ara rẹ jẹ nitori ọrọ Buhari ati Atiku yii o. Iṣoro ni fun Jagaban lati ma di oloṣelu yẹpẹrẹ nilẹ Yoruba nigba tawọn eeyan ba bẹrẹ si i sọ pe opurọ ni, tabi pe ki i sọrọ ka ba a bẹẹ, alasọkojẹ ọkunrin kan ni. Iṣoro gidi ni fun Jagaban lati ṣalaye ẹni ti Yoruba yoo dibo fun lasiko yii o. Iṣoro ni fun Jagaban ki ọrọ Atiku ati Buhari yii ma too ta epo si aṣọ ala to n wọ kiri lati ọjọ yii wa. Iṣoro ni o, iṣoro ni; iṣoro ni fun Jagaban!

Ninu oṣelu APC, olowo lalagbara
Beeyan ba lowo gidi lọwọ, to si wa ninu ẹgbẹ APC, yoo lagbara gidi. Bo ba si ti waa lagbara yii tan o, ko si ara ti ko le da, ko si ohun ti ko le ṣe, aṣegbe si ni pẹlu. O kan jẹ pe ninu ẹgbẹ naa, agbara ju agbara lọ. Oshiomhole, alaga ẹgbẹ naa n kuru, o n ga, o n fo soke bii ẹni ti wọn rọ ina si lara, nitori ohun to sọ pe Gomina Ibikunle Amosun ṣe. O ni ki i ṣe ibo ti awọn eeyan oun jẹrii si ni Amosun gbe jade, ohun to si fa wahala niyẹn. Ṣugbọn ọkunrin yii mọ pe ko si oṣiṣẹ tabi ọmọ igbimọ awọn kan to jẹrii si ibo ti wọn di l’Ekoo, ati pe olu ileeṣẹ ẹgbẹ wọn naa ti jade to sọ pe awọn ko ti i dibo l’Ekoo, bi awọn ba dibo, gbogbo aye yoo mọ. Ṣugbọn lẹyin ọjọ keji, kia ni wọn ko ọrọ naa jẹ, wọn ni awọn ti ṣeto ibo, ibo ti wọn si mu wa lati Eko lo dara julọ. O ṣee ṣe ki ibo ti wọn di ni Eko daa loootọ, ṣugbọn kọkọrọ kan to ba eyin aja jẹ nibẹ ni pe ko si awọn oṣiṣẹ olu ileeṣẹ ẹgbẹ APC, tabi igbimọ ti wọn yan lati ṣeto idibo naa nibẹ, kinni naa ko ṣoju wọn. Gẹgẹ bi ofin ẹgbẹ wọn si ti sọ, bi ibo kan ko ba ti ṣoju wọn, wọn ko ni i gba ibo naa wọle. Iyẹn ni wọn o ṣe gba ibo yii wọle lakọọkọ, ko too di pe wọn tun sare yipada nigba ti agbara ju agbara lọ, ti wọn si n sọ pe ibo Eko daa, awọn si ti gba a wọle. Nitori pe wọn gba a wọle yii ni awọn gomina to ku ṣe bẹrẹ wahala, ti wọn si n sọ pe ofin ti Oshiomhole lo fun Tinubu l’Ekoo, ko waa lo iru rẹ naa lọdọ tawọn. Ṣugbọn Oshiomhole kọ, o ni oun ko le ṣe ohun ti wọn ni ki oun ṣe. Ninu ẹgbẹ ti wọn ba ti n lo ofin meji, ti wọn n lo ọkan fun awọn olowo, ti wọn n lo ọkan fun awọn mẹkunnu tabi awọn ti ko lowo, iru ẹgbẹ bẹẹ ki i toro, koda ko jẹ orilẹ-ede, wahala ti yoo maa ṣẹlẹ nibẹ niyi. Ohun to n ba wọn ja ninu APC ree, iyẹn naa lo si n ba wa ja ni Naijiria, ki Oluwa gbe wa bori awọn ẹlẹnu-meji bii ọbẹ ni.

(63)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.