Iṣẹ nla ni Ọọni ati Alaafin gbọdọ ṣe lori iṣọkan gbogbo ọmọ Yoruba- Deji

Spread the love

Deji tilu Akurẹ, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi, ti rọ Ọọni Ileefẹ ati Alaafin Ọyọ, lati gbe igbesẹ lori bi imọ gbogbo awọn Yoruba yoo ṣe ṣọkan.

Ọba Aladetoyinbo sọrọ yii niluu Akurẹ, nibi ayẹyẹ ẹlẹekarun-un ẹgbẹ Idagbasoke ọmọ Oodua (OPU), eyi ti Aarẹ Ọnakakanfo ilẹYoruba, Ọtunba Gani Adams, sagbekalẹ rẹ.

Awọn ọba mejeeji yii lo juwe bii opomulero fun iran Yoruba nile ati loko, o ni ta a ba fẹ ki irẹpọ pada si aarin awọn ọmọ Yoruba, wọn gbọdọ gba a gẹgẹ bii ojuṣe lati ri i daju pe iṣọkan wa laarin awọn ọba alaye ni gbogbo ilẹ kaarọ-o-o-jiire.

Ọtunba Gani Adams ni tirẹ sọ pe idi ti oun fi da ẹgbẹ naa silẹ lọdun 2011 ni lati ko gbogbo awọn ọmọ Yoruba lorileede yii ati oke-okun pọ ni iṣọkan.

Ilu Eko lo sọ pe awọn ti bẹrẹ ayẹyẹ ọhun lọdun 2015, 2016 lọpọn sun kan Ileefẹ, nipinlẹ Ọṣun, Ọyọ lo gba alejo wọn ni 2017, nigba ti wọn ṣe ti 2018 l’Abẹokuta, ko too di pe wọn pinnu ati gbe tọdun ta a wa yii wa si Akurẹ, nipinlẹ Ondo.

Lori iṣọkan ilẹ Yoruba, Gani Adams ni ibaṣepọ to daa lo wa laarin oun ati awọn ọba alaye mejeeji.

O ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ṣagbekalẹ aadọrin awọn ọmọ Yoruba ti wọn jẹ ọlọpọlọ pipe lati maa gba Aarẹ Ọnakakanfo nimọran lori bi iran Yoruba yoo ṣe wa niṣọkan lai fi ti ẹya tabi oṣelu ṣe. di kikọ lawọn ileewe wọn.

Lara awọn ọba alaye to pesẹ sibi eto naa ni Deji Akurẹ, Ọba Aladetoyinbo, Zaki Arigidi, Ọba Yisa Ọlanipẹkun, Akapinsa ti Ipinsa, Ọba Ọmọniyi Olufunmilayọ atawọn eeyan pataki mi-in.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.