Iṣẹ gidi wa lọwọ Bọla Tinubu

Spread the love

Bi aye ba n yẹ ni, afi ka maa ṣọ iwa hu, owe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni. Awọn ọrọ kan n jade lẹnu baba naa lasiko yii to jẹ afi ko fọgbọn ṣe e o, bi bẹẹ kọ, awọn eeyan yoo fi i wọlẹ, bi wọn ba si fi i wọlẹ, yoo ṣoro fun awọn ololufẹ rẹ lati tẹle e ni gbangba. Nnkan n lọ laarin ilu lasiko yii ti ko dara. Aṣiwaju Tinubu ko si le sọ pe oun ko mọ pe ara n ni mẹkunnu ati awọn eeyan ilu, ko le sọ pe oun ko mọ pe inu ọpọ awọn eeyan – yatọ si awọn ti wọn ba n ri kinni kan jẹ ninu ijọba yii – ko dun si bi nnkan ṣe n lọ. Awọn ti wọn n jẹun daadaa nile wọn tẹlẹ ko le jẹun gidi mọ, iṣoro si wa fun awọn ti wọn ni ọmọ nileewe lati sanwo, nitori bẹẹ ni ọpọ ọmọleewe ko si le lọ mọ nigba ti awọn obi wọn ko ri owo san. Ọpọ awọn oniṣowo ni ileeṣẹ wọn dẹnukọlẹ, ti ẹni to ti ni ri si di alaini laye ijọba yii naa ni. Ka sọ tootọ, ko si idẹrun fun ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lati igba ti ijọba yii ti de. Loootọ wọn ni ka ṣe suuru, ṣugbọn ọjọ wo ni suuru naa yoo da, ọjọ wo ni irin-ajo naa yoo bẹrẹ, nitori nigba ti a ba mọ ibi ti a n lọ, ti a si mọ igba ti irin-ajo sibẹ yoo bẹrẹ ni ọkan ẹni to n balẹ, ti a oo si ni ireti pe abọ irin-ajo naa yoo dara. Ṣugbọn irin-ajo naa ko ti i bẹrẹ lati ọdun kẹta ti APC ti de, ko si apẹrẹ idagbasoke kan, a ko si mọ ọjọ ti nnkan yoo yipada si daadaa fun wa. Iru awọn ọrọ ti yoo tu wa ninu, tabi ọrọ ti yoo ṣalaye ohun to n lọ ati ohun ti yoo ṣẹlẹ ni daadaa fun wa lawọn mẹkunnu ilẹ yii n reti lẹnu awọn eeyan bii Bọla Tinubu ti i ṣe ọkan ninu awọn aṣaaju wọn. Ṣugbọn Tinubu ko jọ pe o wo apa ibẹ yẹn, ko si jọ pe o mọ pe kinni kan n ṣẹlẹ si awọn eeyan oun yii, ni gbogbo igba ti oun yoo ba sọrọ, ko si ọrọ meji ti yoo sọ ju ọrọ oṣelu lọ. Ninu ko sọ pe Buhari nikan lo daa ju, ninu ko sọ pe loju ala oun, Buhari loun yoo dibo fun, tabi ko ni Buhari fẹẹ tun ohun ti awọn PDP ti fi ọdun mẹrindinlogun bajẹ ṣe. Gbogbo tirẹ ṣaa, ọrọ oṣelu ati ti Buhari ni. Oun ni yoo ri awọn ti wọn kuro ninu APC nitori pe ole ni wọn, oun ni yoo ri awọn ti wọn kuro ninu APC nitori wọn fẹẹ gbajọba lọwọ Buhari, oun yii kan naa ni yoo si lọọ pade awọn PDP to ba fẹẹ wọ inu APC ti yoo ni eeyan gidi ni wọn n ṣe. Gbogbo awọn nnkan yii ni ko ba aṣaaju ti Yoruba fẹ mu. Ipo ti Yoruba to Aṣiwaju Tinubu si, ipo akọni ẹda kan ni, wọn si ti ro pe bi ọrọ ba ti ri ni yoo wi, ko ni i tan wọn tabi ko fi ọrọ si abẹ ahọn sọ nibikibi. Ṣugbọn wọn ti n ri i bayii pe Tinubu n tan awọn ni, ati pe ko le sọrọ sọọọkan ọna, ko le ba Buhari sọ ododo ọrọ, kaka ko si sọ ododo ọrọ fawọn ti wọn n ṣejọba yii, araalu lo n dojukọ, to tubọ n tan wọn, wọn ti fẹẹ maa ri i bii ẹni ti ko nifẹẹ awọn tabi ti ko ṣetan lati dari awọn sibi to dara. Iyẹn ni iṣẹ ṣe wa lọwọ ọkunrin Jagaban yii, ko tete rin pada sẹyin diẹ, ko mọ pe ẹtẹ awo ni ẹtẹ ọgbẹri, ati pe bi eeyan ba ti tẹ ju nile, yoo ṣoro ko too le niyi nita. Ki Tinubu tete yaa tun ọmọluabi rẹ ṣe. Awọn mẹkunnu ilu ni ko duro ti o, bi Buhari ati awọn eeyan rẹ ba n ṣe ohun ti ko dara, ko tete jade yaa sọ fun wọn. Bi ko ba ṣe bẹẹ, awọn to ti fẹran rẹ yoo maa pada diẹdiẹ, igbẹyin iru nnkan bẹẹ ko si le dara fun oloṣelu kankan.

 

(56)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.