Hammed ṣẹṣẹ tẹwọn de, lo ba tun lọọ ji ogogoro

Spread the love

*Adajọ ti ni ko pada sibi to ti n bọ

Florence Babaṣọla

Ọrọ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogbọn kan, Hammed, ti wọn mu fun ẹsun ole jija niluu Ileefẹ laipẹ yii ko yatọ si afiṣe rara, nitori ko ti i ju ọjọ meloo kan to tẹwọn de to tun lọọ fọ sọọbu oniṣọọbu, ogogoro lo si pọ ju ninu awọn nnkan to ji.

Ṣe ni Onidaajọ Ọlatunji diju wọn ẹwọn ọdun marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara fun oun ati ekeji rẹ, Oluwaṣeyi Emmanuel, toun jẹ ẹni ọgbọn ọdun, ko si faaye faini kankan silẹ fun wọn rara.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ ti wọn fi kan awọn olujẹjọ mejeeji ni: igbimọ-pọ huwa buburu, ole jija, ile fifọ ati wiwọle onile lọna aitọ, awọn mejeeji si sọ pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun naa.

Ọlawale Oduṣina to jẹ agbefọba lori ẹsun ti wọn fi kan Hammed ati Emmanuel ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje, ọdun yii, ni wọn huwa naa lagbegbe Odo-Ọgbẹ, niluu Ileefẹ.

Oduṣina ṣalaye pe wọn tun wọ sọọbu Ọgbẹni Afọlabi Jamiu to wa lagbegbe Onireke, niluu Ileefẹ, ni nnkan bii aago meji oru ọjọ naa, ti wọn si ji ẹrọ amohun-bu-gbamu (sound amplifier) nibẹ.

Lara awọn nnkan ti wọn ni awọn olujẹjọ ji lọna mejeeji ni ẹrọ amunaduro (stabilizer), igo waini Baron kan, ọti Black Bullet mẹrin, igo Agbara Hot Frunks marun-un ati Regal Dry Gin marun-un.

Bakan naa ni wọn tun ji paaki ọti maltina mẹta ati igo ọti Captain Jack, apapọ owo gbogbo nnkan tawọn olujẹjọ ji gẹgẹ bi Oduṣina ṣe wi jẹ ẹgbẹrun lọna mejilelọgbọn Naira (#32,000).

O ni iwa ti wọn hu ọhun lodi si abala okoodinnirinwo o din mẹta (383) ati irinwo o din mẹwaa (390) ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo, bẹẹ lo si nijiya labẹ abala irinwo o le mejila (412) ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin ofin kan naa.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Ọlatunji sọ pe pẹlu gbogbo ẹri to wa niwaju oun, kedere lo han pe awọn olujẹjọ jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, nitori naa, ki wọn lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fun ọdun marun-un gbako.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.