Habeeb fẹsun jibiti miliọnu mẹta aabọ Naira kan Issa

Spread the love

Afurasi kan, Mahmud Issa ti wọ gau bayii nitori bi oniṣowo ọkọ kan, Habeeb Onimago ṣe wọ ọ lọ sile-ẹjọ fẹsun jibiti miliọnu mẹta aabọ Naira.

Iwe tileeṣẹ ọlọpaa fi wọ ọkunrin naa lọ sile-ẹjọ fi han pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2018, ọkunrin kan waa ba Onimago nibi to n patẹ awọn ọkọ to n ta si lagbegbe Asa Dam, niluu Ilọrin. Onitọhun loun fẹẹ ra ọkọ ayọkẹlẹ  Lexus kan towo rẹ jẹ miliọnu mẹta aabọ Naira.

Nigba to maa di ọjọ keji, oṣu kẹsan an, ọdun 2018, ni ọkọ naa ṣadeede dawati nibi to gbe e si.

Lasiko iwadii awọn ọlọpaa, wọn ba ọkọ naa lọwọ Muhammed Sanni Ajia. Oun gan-an lo waa na ọkọ naa lọwọ Onimago.

Bakan naa ni wọn tun ba ayederu risiiti ti orukọ ‘AA Motors’, ti nọmba foonu  Mahmud Isaa wa lori rẹ pẹlu ọkunrin naa. Eyi fi han pe Isaa ti wọn ba nọmba rẹ lori risiiti naa lo ta a fun Ajia.

Ajia ti sa lọ ni tiẹ, ṣugbọn Issa foju bale-ẹjọ Magisreeti tilu Ilọrin. Ẹsun igbimọ-pọ lati huwa ọdaran ati ole ni wọn fi kan an.

Aṣoju ijọba nile-ẹjọ, Sgt. Innocent Ọnọọla, rọ adajọ lati gbe olujẹjọ naa sahaamọ.

O ni iwadii ṣi n lọ lati le ri Ajia to sa lọ mu, fun idi eyi, bi ile-ẹjọ ba gba oniduuro rẹ, o le ṣakoba fun iwadii ileeṣẹ ọlọpaa.

Agbẹjọro olujẹjọ, Samuel Umoh, ni ki ile-ẹjọ da ẹbẹ agbefọba naa nu. O ni onibaara oun ko ni i ṣi anfaani beeli naa lo.

Adajọ Hauwa Buhari gba beeli ọkunrin naa ni miliọnu meji Naira, pẹlu oniduuro meji, ọkan gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba to wa nipele kẹrinla.

 

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.