Habeeb f’ada ge ori ọrẹ rẹ nitori ija to bẹ silẹ laarin wọn

Spread the love

Habeeb Aliyu, lo ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn bayii, lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o fi ada ge ori ọrẹ rẹ Umar, bọ silẹ lasiko ti ija bẹ silẹ laarin wọn.

Afurasi naa ni wọn lo pa Umar Ismail, to n gbe labule Sunbare, ni Banni, nipinlẹ Kwara, sinu igbo lasiko to n da maalu. Lẹyin to pa a tan lo ge ori rẹ lọ.

Iwe ti ileeṣẹ ọlọpaa fi wọ afurasi naa lọ si ile-ẹjọ majisreeti tiluu Ilọrin, fi han pe ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2018, ni Umar da ẹran lọ, ṣugbọn ko pada sile mọ.

Iwadii fihan pe ija kan bẹ silẹ laarin awọn mejeeji, ti Habeeb si gba ẹpọn Usman mu lasiko ti wọn n ja, ada si ni Habeeb fi ṣa oloogbe naa lọrun, to si ge e lori bọ silẹ ninu igbo naa. Nigba ti awọn obi Umar n wa a, Habeeb sọ fun wọn pe ki wọn ma da ara wọn laamu,  o ni ki wọn fọkan balẹ, o maa pada wale.

Lasiko iwadii ni wọn ba ogulutu Umar ninu igbo. Iṣẹlẹ naa ni wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ko too di pe wọn fi pampẹ ọba gbe Habeeb.

Habeeb lo mu awọn ọlọpaa lọ sibi ti wọn ti ri ori Umar, nibi to gbe e pamọ si. O jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Agbẹjọro fun ijọba, Ayẹni Gbenga, rọ ile-ẹjọ lati fi olujẹjọ naa pamọ sahaamọ, titi ti iwadii to n lọ yoo fi pari.

Adajọ Miriam Dasuki, paṣẹ ki wọn lọọ fi olujẹjọ naa sahaamọ ọgba-ẹwọn titi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.