Haba, Bọọda Siaka, ẹ ṣe daju to bayii!

Spread the love

Ijọba Gomina Isiaka Ajimọbi pada wo ile Akọrin Yinka Ayefẹlẹ lọsẹ to kọja yii. Wọn wo ile naa, wọn si ba nnkan olowo iyebiye jẹ. Kinni naa ko lorukọ meji, iwa ika ni. Awọn ti ọrọ naa ko ba ye yoo sọ pe ki lo de ti a n sọ bẹẹ, wọn yoo ni onisọkusọ lawa naa tabi pe a tete n dajọ owu, ṣe a ko mọ pe ibi ti Ayefẹlẹ kọ ile rẹ si ko dara ni. Bẹẹ ni, o ṣee ṣe ko jẹ ibi ti Ayefẹlẹ kọ ile rẹ si yii, o ṣee ṣe ki ofin ijọba sọ pe wọn ko gbọdọ kọ ile rẹ sibẹ. Ṣugbọn iwe ikọle ati ifọwọsi ti wọn n pe ni “Approval” lati ọdọ ijọba ipinlẹ Ọyọ wa lọwọ Ayefẹlẹ. Ijọba kan lo fun un nilẹ, ijọba kan lo si fọwọ si i ko kọ ile sibẹ lẹyin to ti san owo to yẹ ko san. Nigba ti Ajimọbi paapaa de ori oye ni 2011, wọn ko ti i kọ ile naa yanju, wọn wa lẹnu rẹ ni. Bo ba jẹ ilẹ ti wọn kọ ile si ko dara, igba ti Ajimọbi de ni yoo ti sọ bẹẹ, ti yoo si ṣofin pe wọn ko gbọdọ kọle sibẹ. Bo ba ti kilọ bẹẹ to si ṣe ofin, ẹtọ ijọba ni lati mu iru ẹni to fọwọ siwee pe ki wọn kọle sibẹ, ki wọn si ri i pe wọn gba gbogbo owo ti ẹni to n kọle sibẹ ti naa pada fun un, nitori ijọba fọwọ si i. Ki ijọba too fọwọ si iwe bẹẹ, wọn gbọdọ lọ si ile naa, ki wọn ri ile naa, ki wọn si kọwe le e lori, iwe ti wọn ba kọ le e lori ni gomina yoo lo lati fi ọwọ si i. Bi ijọba kan ba ti de to ri gbogbo iwe yii, ko ni i deede lọọ wo ile yii, yoo kọkọ ba awọn eeyan rẹ to gbewee le wọn lọwọ ṣẹjọ, yoo si ri i pe wọn sanwo pada fonile. Bi wọn ti n ṣe ni orilẹ-ede awọn ọlaju, nibi ti ọrọ oṣelu ati ijọra-ẹni-loju, emi-ni-mo-jaja-depo-yii ko ba ti ba aye awọn to n ṣejọba jẹ. Awọn ara Ọyọ ko sọrọ Isiaka Ajimọbi daadaa, ko si yaayan lẹnu pe ọpọlọpọ eeyan lo n ṣepe fun un. Awọn iwa ika to kun ọwọ ijọba rẹ lo fa a, ati iwa ti ọkunrin naa n hu bii ẹni pe ibi to wa yẹn ni yoo ju si, ko ni i fi ipo gomina silẹ laelae, ko ni i rin kiri Ibadan mọ, yoo ko lọ siluu ẹyin odi. Awọn oponu ati onijẹkujẹ ti wọn n tẹle baba yii yoo maa tan an pe ko sewu, bẹẹ ewu wa fun un o, o wa lori ọmọ rẹ ati awọn idile rẹ lẹyin to ba kuro nijọba. Orukọ rẹ yoo bajẹ kọja atunṣe, iyanu ni yoo si jẹ nigba to ba fi ipo silẹ ti awọn eeyan ba n sọko fun oun tabi iyawo rẹ ni gbangba, tabi ti ẹnikan ba ni oun ọmọ Ajimọbi ti wọn ba pariwo ole le e. Eleyii ti ọkunrin yii ṣe yii ko lorukọ meji, ika ni, ọrọ oṣelu si lo fa a, yoo si pada waa ko ẹsan rẹ lọjọ kan. Ko le bọ ninu ẹ, yoo gbẹsan ẹ dandan!

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.