Haa, ki l’Ọbasanjọ kuku ṣe fun Oshiomhole to bẹẹ

Spread the love

Ọrọ oṣelu ti a ba n ṣe to ba ti la epe lọ, ti a n ṣepe buruku funra wa, iyẹn ti kuro lọrọ oṣelu, o ti di ija ajadiju, ija patapata-ka-ma-kira-mọ! Lọsẹ to kọja ni Adams Oshiomhole, olori ẹgbẹ APC fi epe banu. Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo fi kinni ọhun ranṣẹ si, o ni Ọbasanjọ yoo ri ibinu Ọlọrun. Ki lo le to bẹẹ! Oshiomhole ṣalaye pe Ọbasanjọ funra rẹ lo ti kọkọ sọrọ yii, to ni lọjọkọjọ ti oun ba tẹle Atiku, tabi ti oun ba gba a laaye lati ṣejọba orilẹ-ede Naijiria, oun n wa ibinu Ọlọrun ni. Iyẹn l’Oshiomhole ṣe waa sọ pe nigba ti Ọbasanjọ ko si rẹlomi-in tẹle bayii, to jẹ Atiku lo fẹ ko di aarẹ Naijiria, afaimọ ko ma ri ibinu Ọlọrun. Iwa agọ ati iwa oponu ni yoo mu ọmọde sọ iru ọrọ bẹẹ si agbalagba, oṣelu ti wọn n ṣe to pa laakaye wọn rẹ naa niyẹn. Nigba ti Oshiomhole ba duro sibi kan to n sọrọ si Ọbasanjọ pẹlu gbogbo iwa ibajẹ ti ariwo rẹ gba ilu kan pe oun naa hu lasiko to fi n ṣe gomina, ati nigba to di olori ẹgbẹ APC yii, ṣe ẹ ri i pe aye ọhun n dojuru lọ. Ṣugbọn bi eeyan yoo ba bu Oshiomhole, yoo bu u, yoo dakẹ naa ni, ohun ti baba funra wọn ṣe lo fa iru isọkusọ bayii si i. Agbalagba ki i ja ajatan, bẹẹ ni agbalagba ki i sọ asọtan ọrọ, nitori ọrọ ọjọ iwaju ni. Inu buruku ni agba n ni, agba ki i lọrọ buruku lẹnu. Idi ni pe inu ẹni ni iwa ti a ba fẹẹ hu yoo wa, bẹẹ ọrọ ti a ba ti sọ sita ti di ti gbogbo aye. Ọbasanjọ royin Atiku sinu iwe rẹ, o si sọ oriṣiiriṣii ti ko fi le mu ẹnikẹni ba ọkunrin naa ṣe. Loootọ ni Ọbasanjọ pe Atiku ni ole ati akowojẹ ninu iwe to kọ, gẹgẹ bi Ọbasanjọ si ti jẹ ẹni ti awọn eeyan pupọ nigbagbọ ninu rẹ, ole ni ọpọlọpọ wọn n pe Atiku, wọn ni ọga rẹ lo sọrọ, ko tun sẹni to mọ itan Atiku bii Ọbasanjọ. Igbakigba ti wọn ba si ti beere ọrọ Atiku lọwọ Ọbasanjọ, yoo ni oun ko le fori ji i, oun ko si le jẹ ko ṣejọba Naijiria, nitori ole ni. Iyẹn lawọn eeyan bii Oshiomhole ṣe n sọsọkusọ si i. Ṣugbọn ọrọ ti oun sọ yẹn ju ẹnu awọn baba rẹ lọ!

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.