Haa, Buhari ma fẹẹ ju Ọbasanjọ sẹwọn loootọ

Spread the love

Kinni kan wa ninu eto oṣelu ati ijọba ṣiṣe, paapaa ni Naijiria, iyẹn naa ni pe bi ẹnikan ba fi ṣe olori ijọba, fun ọpọlọpọ ọdun ni yoo ṣi maa mọ ohun to ba n lọ nile ijọba ati ni ọfiisi olori ijọba bẹẹ, nitori awọn ọmọ tirẹ naa ko ni i jẹ ki eti rẹ di si ọrọ gbogbo to ba n lọ. Agaga fun iru Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ẹni to ti ṣe aarẹ Naijiria laye ologun ati laye oloṣelu, koda, bi abẹrẹ lasan ba bọ silẹ nile ijọba, awọn ti wọn yoo sọ fun un yoo pe e sọ fun un, ọpọlọpọ aṣiri ijọba lawọn eeyan bẹẹ maa n mọ, o kan jẹ ki i ṣe gbogbo ẹ naa ni wọn n sọ sita ni. Ohun to jẹ ko ya gbogbo aye lẹnu ree nigba ti Ọgagun agba naa pariwo sita si gbogbo aye leti pe Ọga ologun toun naa ti di oloṣelu to n ṣejọba Naijiria bayii, Aarẹ Muhammadu Buhari, n wa ọna lati mu oun, ki i ṣe pe o fẹẹ mu oun lasan kọ o, o fẹẹ ju oun sẹwọn ni.

Bo ba jẹ oniroyin kan lo sọ iru rẹ jade, wọn yoo maa pariwo le e lori pe irọ lo n pa ni. Ṣugbọn Ọbasanjọ funra rẹ lo jade to sọ bẹẹ, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ta a wa yii lo jade to ni ki gbogbo aye gba oun. Ọrọ to mu baale to fi sa wọnu igbẹ, ki gbogbo awọn ara abule bẹẹ ma ṣafara ni. Ohun to le mu ki odidi aarẹ ilu sọ bayii, ẹni to ni awọn ọpọlọpọ ṣọja to n ṣọ ọ, ọrọ naa ko yatọ si ti agbalagba to n sare ninu ẹkan, bi nnkan ko ba le e, aa jẹ pe o n le nnkan ni. Eleyii ko si tilẹ ni bakan meji ninu, nnkan n le Baba Ọbasanjọ, Buhari lo n le e. Ṣugbọn nitori pe oun Ọbasanjọ funra rẹ n le nnkan ni Buhari ṣe n le e o, Ọbasanjọ fẹ ki ijọba Naijiria bọ lọwọ Buhari, o ti kọwe, o si ti ko ẹgbẹ jọ, o ni Buhari ko daa, lilọ ni yoo lọ, eyi to ṣe ninu ijọba Naijiria ti to gẹẹ. Bi Ọbasanjọ ba fẹ ki wọn le ijọba kan lọ, bi i ti i kọwe naa lo kọ ọ yii, iru ijọba bẹẹ yoo si lọ.

Ṣugbọn o jọ pe ti asiko yii yatọ, o jọ pe eera Ọbasanjọ ti gbe ohun to ju u lọ, Buhari ko ba a mu ọrọ naa ni kekere, ija ologun lo fẹẹ ba a ja, bi awọn ṣọja ti n ba ara wọn ja loju ogun. Nitori pe Ọbasanjọ naa si jẹ ṣọja, o mọ pe ija naa ko ni i jẹ kekere, idi eyi lo ṣe tete pariwo sita. Awọn Buhari ti n dẹ okun silẹ fun un ni, awọn okun ti wọn si dẹ silẹ yii, bo ba fi le ko si ọkan ninu rẹ loootọ, ibi ti baba naa yoo ba ara rẹ, ko ni i dara. Bi awọn ṣọja ba n jagun, ọkan ninu awọn ọgbọn ijagun wọn ni wọn lo fun Ọbasanjọ laipẹ yii. Ohun ti wọn n pe ni Siratẹji (Strategy), ete buruku, ni wọn lo fun un. Bi awọn ṣọja ba n jagun, wọn a maa fẹẹ ya awọn ọta wọn kuro lara awọn ibi ti wọn ba ti ni atilẹyin, wọn yoo sọ ọta naa sihooho ti ko ni i si ẹni ti yoo le gbeja rẹ, ko too waa di pe wọn rọọṣi ẹ, ti wọn yoo si da seria ti wọn ba fẹ fun un.

Laarin ọsẹ kan pere, ijọba Buhari ti wa ọna lati ya Ọbasanjọ kuro lara awọn eeyan rẹ, nitori wọn ṣe ohun ti awọn Yoruba beere titi pe ko ṣe ti ko ṣe, iyẹn naa ni ọrọ MKO Abiọla ti wọn fi oye da lọla. Lati igba ti eleyii ti ṣẹlẹ ni ọpọlọpọ ọmọ Yoruba ti koriira Ọbasanjọ si i, awọn ti wọn si ti koriira Buhari tẹlẹ ninu awọn Yoruba ti pada sẹyin, wọn ni eeyan daadaa ni. Ohun ti eyi tumọ si ni pe bi ohun kan ba ṣe Ọbasanjọ lasiko ti a wa yii, iba diẹ awọn ọmọ Yoruba ni wọn yoo kaaanu rẹ, pupọ ninu wọn yoo maa sọ pe Ọlọrun lo mu un ni. Alaroye gbọ pe ọrọ yii fa ibẹru pupọ si ọkan baba yii, nitori oun naa mọ pe bii igba ti awọn Buhari ti kọyin ọpọlọpọ eeyan soun ni. Awọn Buhari ko ti i duro, bi wọn ti ṣe bẹẹ ni wọn ti ba ọna mi-in yọ, wọn fẹẹ fabuku ti yoo le ju kan Ọbasanjọ, ọna ti wọn si le gba mu un gan-an niyẹn.

Awọn oku mẹta kan ti wọn ti ku laye igba ti Ọbasanjọ fi n ṣejọba ni awọn eeyan naa ni awọn yoo hu jade, wọn ni awọn fẹẹ mọ ohun to pa wọn gan-an, ati idi ti ẹjọ wọn ko fi ti i yanju lati ọjọ yii wa. Awọn oku mẹtẹẹta yii ni ti Oloye Bọla Ige ti wọn pa ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun 2001, Harry Marshall ti wọn pa ni ọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun 2003, ati A K Dikibo ti wọn pa ni ọjọ keje, oṣu keji, ọdun 2004. Awọn mẹtẹẹta yii, agbọ-sọgba-nu ni iku wọn jẹ, nibi ti ọrọ si ti le ni pe ko si eyi to ku ninu wọn ti wọn ko darukọ Ọbasanjọ ati awọn eeyan rẹ si i, wọn ni wọn mọ bi wọn ti ṣe ku. Ati pe lẹyin ti awọn eeyan naa ku ti Ọbasanjọ si lo bii ọdun mẹrin ko too pada gbe ijọba silẹ, wọn ko ri awọn to pa wọn, wọn ko si ri ibi gidi kan fi ori ẹjọ naa ti si titi doni, iyẹn lawọn ọta Ọbasanjọ ṣe n pariwo nigba naa pe oun paapaa mọ si i.

Iku Bọla Ige ka gbogbo Yoruba lara, nitori pe ọna ti wọn gba pa a ko dara rara. Minisita ni, Ọbasanjọ gan-an lo si n ba ṣiṣẹ, ṣugbọn iroyin ti kan pe baba oloṣelu nla naa yoo fi ijọba Ọbasanjọ silẹ nitori awọn ohun to n ṣe ko tẹ ẹ lọrun, pe o n bọ wa lati tun ẹgbẹ oṣelu wọn, AD ati ANPP ṣe, ki awọn ẹgbẹ mejeeji le tun papọ, ki wọn si fa oun Bọla Ige kalẹ lati koju Ọbasanjọ lasiko idibo ọdun 2003. Awọn kan tilẹ sọ pe o ti lọọ sọ fun Ọbasanjọ pe oun ko ṣiṣẹ mọ, oun fẹẹ kọwe fi ipo silẹ, wọn ni iwe naa ni ko raaye kọ titi to fi ku. Wọle Ṣoyinka kọ ọrọ kobakungbe kan lẹyin iku baba oloṣelu naa, nigba ti awọn ijọba Ọbasanjọ bẹrẹ si i dana ayẹyẹ pe awọn sọ ọkan ninu awọn nu, itumọ oyinbo ti Ṣoyinka sọ nigba naa ni pe lẹyin ti wọn pa Bọla Ige tan ni wọn n dana ayẹyẹ, wọn waa n jo lori saare rẹ. Titi di akoko yii, wọn ko yanju ọrọ iku baba naa.

Bi iku Bọla Ige ti dun gbogbo Yoruba, bẹẹ naa ni iku Oloye Harry Marshall dun awọn ara South South, iyẹn gbogbo awọn ọmọ Ijọ pata ni Naija Delta. Oun ni olori oloṣelu wọn, ọmọ ẹgbẹ PDP ni, koda, oun ni igbakeji aarẹ ẹgbẹ naa ni adugbo naa, ko si meji Harry Marshall ninu PDP ko too di pe awọn Ọbasanjọ gbajọba. Oun lo fa Peter Odili kalẹ gẹgẹ bii gomina ni Rivers, ko si si ẹni to jẹ gomina lati Rivers titi de Cross Rivers, Akwa Ibom, Delta ati Edo ti wọn ko fi tirẹ ṣe. Ṣugbọn ko pẹ ti ija de laarin oun ati Ọbasanjọ, ati Odili ti i ṣe ọmọ Ọbasanjọ, lo ba taku pe awọn ko ni i duro ti Ọbasanjọ ko lọ ni saa keji, nitori ileri to ṣe fawọn kọ niyẹn. Ni ija ba de, nigba ti ija naa si le, Harry Marshall kuro ninu ẹgbẹ PDP, o ko awọn ero rẹpẹtẹ lọ sinu ẹgbẹ ANPP, oye ti wọn fi i jẹ ninu PDP naa ni wọn si fi i jẹ ni ANPP, oun ni igbakeji aarẹ.

Ọrọ naa waa n gbona lọwọ, asiko ti wọn si fẹẹ dibo ni ọdun 2003, ibo ku bii oṣu kan pere ni wọn pa ọkunrin naa si inu ile rẹ niluu Abuja, wọn ti kọkọ yin in lọrun ki wọn too ṣẹṣẹ waa fi ibọn fọ ọ lori. Nitori ija to wa laarin oun ati Ọbasanjọ pẹlu Odili, titi di asiko yii ni awọn ọmọ Delta n sọ pe oun lo pa aṣaaju awọn. Nigba ti ọrọ naa yoo si kuku fabuku kan Ọbasanjọ, ọdun 2003 ni wọn ti pa ọkunrin yii, titi di ọdun 2007 to si gbejọba silẹ, wọn ko ri ẹjọ naa fi ori rẹ ti sibi kan to tẹ araalu lọrun rara. Bi ọrọ tirẹ naa si ti ri ni ti Dikibo ri, bo tilẹ jẹ pe inu PDP loun naa wa, to si jẹ oloye nla ninu ẹgbẹ, oun ati Ọbasanjọ tun kọyin sira wọn, igbẹyin ẹ si ni iku fun un. Awọn ẹjọ yii ni awọn Buhari ni awọn fẹẹ gbe jade, wọn si ti bẹrẹ ariwo yii lati ọdun 2016, ṣugbọn asiko yii ni wọn fẹẹ mu ọrọ naa ṣe.

Ọga ọlọpaa pata, Ibrahim Idris, ti n sọ pe lasiko ti awọn wa yii lawọn yoo mọ ẹni to pa Bọla Ige ati awọn meji to ku yii gan-an, ọrọ naa si wuwo pupọ, nitori lẹsẹkẹsẹ lawọn kan ti n sọ pe Ọbasanjọ ni wọn n powe mọ yẹn o. Ohun ti awọn eeyan to mọdi ọrọ n beere larin ara wọn naa ni pe: Ṣe Buhari fẹẹ ju Ọbasanjọ sẹwọn loootọ ni? Awọn kan n pariwo pe ko to bẹẹ, awọn mi-in si n sọ pe oju awọn ni yoo ṣe. Bi yoo ti ri, ẹnikan ko ti i mọ, ṣugbọn kinni kan to han daadaa ni pe awọn Buhari ko ro daadaa si Ọbasanjọ o, nitori wọn ni Ọbasanjọ paapaa ko ro daadaa sawọn

(75)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.