Haa, baba yii ti tun k’atọsi o

Spread the love

Ti mo ba sọ kinni kan fun yin, njẹ ko ni i ya yin lẹnu, njẹ ẹ maa gba mi gbọ, ara Iya Tọmiwa ti n ya o. Ọrẹ mi, iyaale Sẹki, ara ẹ ti n ya sẹẹ. Ohun ti mo ri ya mi lẹnu, bi Ọlọrun ṣe n ṣe iṣẹ ẹ si tun waa jẹ pabambari loju mi. Ṣe ẹ ri i, Ọlọrun wa to wa loke yii, ọba iyanu ni o. Ara ọrẹ mi ti n ya, awọn oogun ti awọn baba yẹn n lo fun un n ṣiṣẹ gidi ju bi emi naa ti ro lọ. Ko si ẹbọ, ko si etutu o, agbo ni, agbo ati agunmu tabi ẹtu, ki wọn ni ko maa fi mu ẹkọ gbigbona, ko ju bẹẹ lọ. Wọn tun fi oori ṣe ipara kan fun un, wọn ni ko maa fi wọ gbogbo ibi ti ko ṣiṣẹ lara ẹ.

Mo pada lọ si ile awọn Sẹki ni, ṣe ẹ mọ pe bi mo ṣe kuro nile laaarọ ọjọ naa ko daa, nigba ti mo si ti ba Sẹki sọrọ tan, mo tun pada lọ, nitori mi o sọ ootọ ọrọ to wa nibẹ fun un nigba ti a fi n lọ, mo kan sọ pe Sẹki fẹẹ ba mi de ibi kan ni. Mo ni lati pada lọ ki n lọọ salaye fun un. N ko sọ ootọ bẹẹ naa fun un o, awọn ọrọ kan wa ti eeyan ki i sọ fọrẹẹ ẹ, paapaa to ba jẹ eyi to le da ile wọn ru, tabi to le mu un ko tun maa ronu ni iru aaye to wa yẹn. Nnkan ti mo sọ fun un ni pe mo lọọ fi ilẹ kan ti mo ṣẹṣẹ ra nitosi wa nibẹ han Sẹki ni. Lo ba n rẹrin-in, o ni emi ati ọmọ mi yii ṣaa.

Ṣugbọn ẹrin temi ko lọ rẹpẹtẹ, afi bii ẹni pe o ti to ọsẹ meji ti mo ti ri i gbẹyin ni, bẹẹ mo ṣi ri i ni ọsẹ to lọ, bii ọjọ mẹfa sẹyin. Ohun ti mo kọkọ ri ni pe o ti dide, o jokoo sori bẹẹdi tepọn o kan fi ọwọ di  mantiraasi bẹẹdi naa mu ni. Aṣe oun naa n ṣọ mi, niṣe ni mo ri i to gbe ọwọ ẹ soke, afi gbaa lo fi gba mi lẹyin, ni mo ba fo dide, mo pariwo: “Iya Tọmiwa!” Lo ba ni oun fẹ ki emi mọ pe ọwọ oun kan ti n ṣiṣẹ ni. Lemi naa ba sun mọ ọn, ni mo fa ọwọ naa wo, o ti n ṣiṣẹ loootọ, ọwọ kan to ku naa ti n naro bọ nita, bẹẹ ni eegun ẹyin yẹn ti dide naro.

Bo ṣe n lọ yẹn, obinrin yẹn maa dide rin. Mo kan n ṣe haa, haa, haa ni. Nibi ti mo ti n ṣe haa yẹn lo ti di mi lọwọ mu, lo ba bẹrẹ si i sunkun. Ẹkun ayọ ni, ki i ṣe ẹkun ibanujẹ, ninu ẹkun nibẹ lo  dẹ ti sọ fun mi pe “Iya Biọla, sista mi, ọrẹ mi, ẹgbọn mi, iwọ ni angẹli ti Ọlọrun ran si mi, mi o ni i da ẹ laelae.” Lo ba tun bu sigbe. Ni mo ba jokoo pada, mo wọ ori ẹ mọra, ni mo ba yọ ankaṣiifu mi, ni mo fi n nu un loju. Nigba naa lo sinmi diẹ, ṣugbọn ko yee leri ẹkun bo ti gbori si mi laya naa, mi o si mọ bemi naa ṣe ṣe e, ni mo ba n jami loju.

Emi o mọ pe iṣẹ kuku ti lọ bẹẹ, awọn baba yẹn ko wa si ọdọ temi mọ, mo ṣẹṣẹ gbọ lẹnu Iya Tọmiwa naa ni o, pe oun ati ọkọ oun ti gba pe bi wọn ba fẹẹ ṣe agbo naa nile awọn, tabi ti wọn ba ni nnkan ti wọn fẹẹ ṣe, ki wọn duro wọn ki wọn ṣe e, nigba ti awọn ti ri i pe iyanu ni iṣẹ ti awọn baba naa n ṣe, ti wọn o si rubọ tabi ta ẹjẹ eeyan silẹ, tabi ta ẹjẹ ohunkohun silẹ, pe iyẹn ni ko jẹ ki n ri wọn lọdọ mi mọ. Mo tẹ ọwọ mi mejeeji si oke-ọrun, mo ni, “Ọlọrun, to o ba ma le ṣe oore yii jalẹ fun mi, mo maa fi nnkan nla dupẹ lọwọ ẹ ni o!”

Bi mo ṣe n sọ bẹẹ yẹn, ibi kan ni ọkan mi lọ,  awọn aafa wa ti wọn ni awọn ti ra ilẹ si ibi kan lọna Mowe, awọn fẹẹ kọ mọṣalaaṣi sibẹ, ibẹ lọkan mi lọ, mo si ti fi ọkan mi daniyan pe ti Ọlọrun ba le ṣe oore naa fun wa jalẹ bẹẹ, mo maa lọọ fun wọn lowo nla lati fi bẹrẹ mọṣalaaṣi naa ni. Mo fẹẹ fi dupẹ lọwọ Ọlọrun ni, ti mo ba si bẹrẹ ti ko ba ga mi lara ju, mo maa kọ ọ tan fun wọn ni. Oore Ọlọrun ni, ko si bi mo ṣe le ṣe e, mo gbọdọ dupẹ lọwọ ẹ ni. Ani nigba ti mo n lọ, Iya Tọmiwa sin mi jade, ko si jokoo lori ṣia ẹ, o fẹsẹ ara ẹ rin ni, bo tilẹ jẹ gategate bii ọmọde lo ṣe n rin.

Nnkan to tun jẹ ki n tun lọọ wo o ni bii ọjọ kẹrin niyẹn, nigba ti mo dẹ tun ri i, nnkan ti tun yatọ si ti tẹlẹ, ọkan mi waa balẹ wayi pe obinrin yii maa gbadun gidi. Mo waa fẹsẹ kan de ọdọ Sẹki pe ki n ki i, ki n dẹ mọ ibi to ba ọrọ oun ati ọkọ ẹ de. Ọkọ wọn naa kuku ti de, wọn lọdọ ẹ lo wa. Afi bi mo ṣe wọle ti mo ri ọmọ mi, ọtọ ni imura to mu. Sẹki wọ ṣokoto nika ni, ninu ile ẹ ni o, ni iyẹn gbe gbogbo itan ẹ jade. Ọlọrun lo mọ ibi to ti ri buresia to wọ, niṣe ni iyẹn ko gbogbo ọmu ẹ sita, koda, a fẹẹ le maa ri ori ọmu ẹ nita. Mi o mọgba ti mo ni Sẹki ki lo de.

Lo ba ni kin ni Iyaa mi, mo ni iru imura wo ree. Lo ba ni imura tawọn ọmọ aye n wọ ni, nigba to dẹ jẹ awọn ti wọn n ṣi ọmu silẹ lọkọ oun fẹran bayii, awọn ti wọn n gbe itan jade lo laiki, oun ti lọọ ka nika oriṣiiriṣii jọ, ati awọn aṣọ keekeekee, to maa ko ọmu oun jade, ki Akinfẹnwa le maa ri nnkan wo bo ba ṣe fẹ, oun dẹ ti gbe ara oun silẹ fun un, koda bo ba sọ pe o ti ya ni baluwẹ, oun maa tẹdii silẹ fun un nibẹ ni. Nigba to maa pari ọrọ e, o ni, “Iya mi, ko sọmọ kan to le gba ọkọ temi o, ẹ lọọ gba bẹẹ, wọn maa sa lọ gbẹyin ni!” Mo ni ṣe Akinfẹnwa dẹ fẹran eyi to o n ṣe yii.

Sẹki ni nigba ti oun ko wọ aṣọ naa jade, o ni ninu ile nikan ni, fun ọkọ oun nikan ni, oun ko jẹ wọ ọ bọ si gbagede debii pe iyaale oun paapaa yoo ri i tabi pe alejo kan yoo ri ara oun, ṣugbọn ninu ile oun, ninu yara oun yii, bo ba ku oun ati ọkọ oun, nnkan ti oun maa maa wọ fun un niyẹn. Ni mo ba ni too, ko sija nibẹ, bo ba ti jẹ ọkọ ẹ fẹran ẹ. O lo fẹran ẹ bajẹ, o ni ẹni to jẹ nigba ti oun gbe gbogbo ohun to ṣe e ko o niwaju, niṣe lo dọbalẹ foun, to ni iṣẹ eṣu ni, loun naa ba kunlẹ fun un, oun ni gbogbo ohun to ba fẹ pata loun maa ṣe fun un, ko ma tẹle awọn ọmọ keekeekee yẹn mọ o, ko ma jẹ ki wọn ba oun laye jẹ.

Sẹki ni nnkan ti oun ṣe yẹn ya ọkọ oun lẹnu to fi tun waa bi oun pe ṣe oun sọrọ naa fun iya oun ni, emi niyẹn o, o ni oun ni rara. O ni Akinfẹnwa sọ pe ọgbọn agba ṣe waa wa ninu oun bẹẹ yẹn, lo ba ṣeleri foun pe oun ko tun tẹle awọn ọmọ keekeekee kan mọ. Idunnu ni mo ba dele nijọ yẹn, afi bi baba yin dẹ ṣe tun gbe tiẹ ka mi laya. Bi mo ṣe n wọle bayii lo fo doke to n gbalẹkun, ni mo ba dẹ ṣi i fun un. “Ọkọ mi ki lo de!” Bi mo ṣe wi niyẹn, ọrọ Sẹki ni mo n ranti. Baba o raaye iyẹn, niṣe lo n gbọn, “Suwe, njẹ o ranti orukọ oogun to o ra fun mi lọjọ yẹn mọ?” Mo ni oogun wo tun niyẹn, o ni, “Oogun atọsi yẹn!” Mo lanu. “Ṣe ẹ ti tun katọsi ni?”

 

 

(93)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.