Gomina to jale yii nkọ o

Spread the love

Lori fidio la ti kọkọ ri i, ṣugbọn ohun tawọn eeyan n ro ni pe aye ti daye kọmputa, ko si ayederu ohun ti wọn ko le ṣe. Ọrọ gomina ipinlẹ Kano la n sọ o, Gomina Abdullahi Umar Ganduje. Wọn ti n sọ ọ tipẹ, nitori wọn ni nigbakigba to ba ti gbe iṣẹ fun awọn agbaṣeṣe, yoo gba ida mẹẹẹdọgbọn ninu owo iṣẹ to ba gbe fun wọn. Wọn ni ko si kọntirakitọ ti ki i ṣe bẹẹ fun. Bo ba gbe iṣẹ ọgọrun-un (N100), Naira fawọn eeyan, yoo gba ida mẹẹẹdọgbọn (N25), ninu owo iṣẹ naa, yoo sọ pe dọla ni ki wọn fi waa san an foun, yoo si ni wọn yoo san owo naa foun ki wọn too bẹrẹ iṣẹ, tabi ko jẹ owo akọkọ tijọba ba san fun wọn ni wọn yoo ti kọkọ yọ toun foun. Bẹẹ lo jẹ pe ko si agbaṣẹṣe kan to ṣiṣẹ ni Kano ti gomina Ganduje ki i gba owo lọwọ rẹ. Nigba ti ọrọ naa su awọn kan ni awọn oniroyin dẹ okun fun un, wọn ya a ni fidio ki ọrọ naa le jẹ aridaju, gbogbo eeyan si ri i nibi to ti n gba owo dọla. Gomina yii pariwo pe irọ ni, ṣugbọn oniroyin to gbe ọrọ naa jade ti wa siwaju awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin Kano, o si ti sọ bi awọn ti ri ọkunrin naa ya sori fidio, ati pe ootọ ni fidio ọhun, ki i ṣe agbelẹrọ rara, ko si si ibi ti wọn ko ti le wadii rẹ wo, Ganduje n gba owo ẹyin, owo dọla lo si fi n gba owo. Lara awọn olori-maṣanfaani ti a fi ṣe olori wa naa ree o, awọn ika, akoṣibero gbogbo. Iwọ ni gomina, iwọ lo n ṣejọba, iwọ lolori ijọba, iwọ lo n gbe iṣẹ fawọn agbaṣẹṣe, iwọ naa lo si n gba owo ẹyin lọwọ wọn. Iyẹn lo ṣe jẹ pe wọn ki i ṣe iṣẹ kan ni Naijiria ki wọn ṣe e yanju, iṣẹ ẹyọ kan ti wọn ba n ṣe ti ko yẹ ko ju ọdun meji si mẹta lọ, wọn yoo ṣe e fun ọdun mẹwaa, ojoojumọ si ni owo iṣẹ naa yoo maa le si i. Eyi naa lo fa a to jẹ titi ti wọn ba fi ẹgbẹrun mẹwaa Naira ṣe ni Ghana, ọgọrun-un ẹgbẹrun ni Naijiria yoo fi ṣe tirẹ, nitori awọn ti yoo ko owo jẹ yoo ti pọ ju iṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe lọ. Awọn oloṣelu yii si ni o. Ko si iyatọ ninu wọn, boya PDP, boya APC, ọmọ ole to yẹ ki wọn yẹgi fun, tabi ki wọn wa nisalẹ ẹwọn lo pọ ninu wọn. Ẹ ṣa ma jẹ ki Ganduje yii ṣe tirẹ ni aṣegbe o, kawọn aṣofin Kano yii tete yọ ọ danu, bi wọn ba si ti yọ ọ tan, ki awọn agbofinro gbe e, ẹwọn lo yẹ ki ọrọ rẹ pari si, ko le jẹ ẹkọ fun gbogbo awọn oloṣelu ole akowo-ijọba-jẹ.

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.