Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ti sọ lanaa, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).

Spread the love

O sọ eleyii di mimọ lẹyin to bura fun Jerome Shimbe gẹgẹ bii Oludamọran Pataki lori ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ni olu ilu ipinlẹ naa to wa ni Markurdi.

Gomina naa ṣalaye pe niwọn igba ti ẹgbẹ oṣelu APC ti juwe ile foun pẹlu iwa ati iṣe wọn, ti ko si si ajọṣepọ to dan mọran mọ laarin oun ati ẹgbẹ ti oun ti wọle sipo gomina lọdun 2015 yii, ko si ohun to kan ju ki oun wa ẹgbẹ oṣelu ti erongba awọn jọ papọ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe Ortom ko ti i sọ inu ẹgbẹ oṣelu to n lọ, ṣugbọn awọn eeyan woye pe igbesẹ ti gomina gbe yii ko sẹyin oriṣiiriṣii iṣekupani ati ikọlu to n waye nipinlẹ rẹ, eyi ti ẹgbẹ oṣelu to ti kuro ko ri nnkankan ṣe si i. Ko ti sẹni to mọ ẹgbẹ oṣelu ti ọkunrin naa fẹẹ darapọ mọ.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe ko si ani ani nibẹ, igbesẹ gomina yii yoo ṣakoba fun ẹgbẹ oṣelu APC, nitori ko si bi awọn ara ipinlẹ yii ko ṣe ni i tẹle gomina wọn lọ sinu ẹgbẹ to ba n lọ

 

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.