Gomina ilẹ Yoruba to ba fun Fulani nilẹ, ẹ gbe e ṣepe, tiletile, tọmọtọmọ, tirantiran

Spread the love

Bi gomina tabi ọba ilẹ Yoruba kan ba fun ijọba Buhari laaye lati da abule Fulani, tabi abule maalu sibikibi nilẹ Yoruba, ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Benue ati Plateau, nibi tawọn Fulani ti n fi ojoojumọ paayan, ti wọn n bẹ ori ọmọde, ti wọn n ṣa awọn alaboyun ladaa pa toyuntoyun, ti wọn n yinbọn pa awọn arugbo to n gbiyanju ati sa lọ, iru ohun ti yoo pada ṣẹlẹ si wa niyẹn. Iyẹn lo ṣe jẹ ti ẹ ba gbọ ti gomina Yoruba kan ba loun yoo fun Buhari tabi Fulani nilẹ, ẹ ko ara yin jọ ki ẹ ṣe iwọde pe ẹ ko fẹ, ẹ pariwo pe ẹ ko gba, ẹ kilo fun gomina bẹẹ pe ko ma dan an wo. Bi ẹ ba sọ titi ti apa yin ko ka gomina bẹẹ, epe nla nla ni ki ẹ bẹrẹ si i gbe e ṣẹ o, tiletile rẹ, tirantiran, ati ti gbogbo ohun to ba ni. Ẹ ṣepe naa titi ti Ọlọrun yoo fi gbe adanwo to ga ju u lọ fun un, titi ti ipo agbara to wa yoo fi bọ lọwọ rẹ, nitori ẹni to ba ṣe bẹẹ fẹẹ ba ti Yoruba jẹ ni.

O fẹẹ ba ti Yoruba jẹ ni o, yoo ba ti iran ti a wa yii jẹ, ti awọn ọmọ wa ti wọn n bọ lẹyin ọla, o si ṣee ṣe ko jẹ nibẹ ni ogun ti wọn yoo fi gba ilẹ Yoruba patapata lọwọ wa yoo ti wa. Mo bẹ gbogbo gomina, mo bẹ gbogbo ẹyin agbaagba oloṣelu ilẹ yii, mo fi Ọlọrun bẹ ẹyin ti ọrọ mi ko ye paapaa, ẹ ṣe suuru gidi lori ọrọ yii, ẹ dakun, ẹ ma gba abule maaluu, ẹ ma gba oko maaluu, ẹ ma fun ijọba Buhari nilẹ lati ko awọn Fulani si o. Ilẹ ni awọn ara Benue-Plateau fun awọn Fulani, wọn gba wọn laaye ki wọn maa sin maaluu wọn lẹgbẹẹ kan ni, iyẹn lo pada di iṣoro fun wọn loni-in yii, ti wọn fẹẹ run wọn tọmọtọmọ. Loootọ ijọba n sọ pe bii ọgọrun-un eeyan lo ku ni awọn abule tawọn Fulani yii ti kọlu wọn lọsẹ to kọja, ṣugbọn awọn ti wọn wa niluu ti ọrọ ṣoju wọn, atawọn aṣofin ti wọn wa lati agbegbe yii ni awọn ti wọn ku le ni igba.

Ko si ẹni to gọ ju gomina to ba sọ pe oun yoo fun awọn Fulani ni ilẹ nitori ki wọn ma le maa fa wahala tabi ijangbọn pẹlu awọn agbẹ ati awọn araalu. Tọhun gọ, o fẹnu họra. Idi ni pe ibẹrẹ wahala gan-an ṣẹṣẹ niyẹn, ibẹrẹ ọtẹ ayeraye. Ẹ ko ni i fun Fulani onimaaluu laaye ko jokoo nibi ti ẹ ba fun un, paapaa to ba ni atilẹyin ijọba apapọ, yoo maa gba ilu lọ ni, yoo maa dana sunle, yoo maa paayan, nitori ẹmi eeyan ko ja mọ kinni kan loju wọn. Bo ba jẹ awọn eeyan ti wọn ṣee ba gbe ni, to jẹ awọn eeyan ti wọn fẹẹ ṣe owo ati iṣẹ aje, ko si ohun to buru nibẹ rara, nigba ti ki i ṣe ori ẹnikan ni wọn yoo duro le, to jẹ wọn yoo ji, wọn yoo maa ṣe iṣẹ wọn ni. Ṣugbọn ti Fulani onimaaluu ko ri bẹẹ. Fulani ki i dako, wọn ko si le e jokoo si oju kan, ijọba kan fẹẹ fi owo ti wọn ni awọn fẹẹ fi kọ abule maalu yii ṣofo ni, nitori Fulani ko ni i ṣiṣẹ kan nibẹ.

Bi ijọba ba kọ abule naa fun wọn, afi ki ijọba tun maa sanwo lọdọọdun fun wọn, tabi ki wọn gba awọn eeyan ti wọn yoo maa ba wọn da oko ti maaluu wọn yoo jẹ, Fulani ki i dako, bẹẹ ni wọn ko mọ iṣẹ meji ju ka ko maaluu jẹko lọ, ẹni to ba si da wọn duro si oju kan, to ni ki wọn maa jẹ, ki wọn maa mu nibẹ, bii ẹni to de wọn lẹsẹ mọlẹ lo maa n ri loju wọn. Bi wọn ba si fẹẹ dako tabi ṣe abule fun wọn, ko si ibi ti o dara ju lati ṣe eleyii si ju ilẹ Hausa, nibi ti papa ti pọ rẹpẹtẹ lọ. Lati fun Fulani loko nitosi ilu kankan ni ilẹ Yoruba, bii ẹni to fẹẹ sọ ilu naa di ahoro lasan ni. Ko si oko ti ẹ le da fun wọn ti wọn ko ni i wọ inu igbo tabi oko oloko, ko si ibi ti ẹ le fi wọn si ti wọn ko ni i jale lati wa ohun ti wọn yoo jẹ, boya ki wọn ji ẹran obukọ tabi ohun ti wọn yoo jẹ gbe, nitori wọn ko jẹ fọwọ kan maaluu wọn, eewọ ni.

Loni-in yii, ẹrin lo maa n pa mi, aanu si ṣe mi bawọn eeyan wa ṣe n ṣegbe, nitori wọn ko mọ itan kankan. Awọn kan ti bẹrẹ si i sọ bayii, wọn ni Dan Fodio lo gba ilẹ naa fun Fulani, ko si yẹ kawọn eeyan ba wọn ja tabi ki wọn fẹẹ le wọn kuro. Fun awọn ti wọn ba mọ itan, ọrọ naa yoo gba omije loju wọn. Ni gbogbo aye Dan Fodio ati tawọn ọmọ ẹ, ati ni gbogbo igba ti wọn fi jagun, igbo aiwọ ni gbogbo adugbo awọn Tiv, awọn Birom, awọn ti wọn wa ni ipinlẹ Benue ati Plateau yii jẹ fun wọn, agbara wọn ko debẹ, ogun Jihad ko debẹ, ko si Fulani kan ti wọn bi daadaa ti yoo jagun de ọdọ wọn. Nigba ti awọn ti wọn n jagun ẹsin naa de apa ọdọ wọn, ti awọn Tiv yọ si wọn, ija akọkọ ti wọn ja ni wọn ko ti duro mọ, awọn Tiv ati Birom yii le wọn pada sẹyin, koda, wọn gba awọn ilu mi-in ti ki i ṣe tiwọn ti wọn ti gba tẹlẹ lọwọ wọn.

Bi awọn ti wọn ko mọ mẹmẹ, tabi ti wọn ro pe awọn kan fẹẹ jale ba ko ara wọn jọ, ti wọn we lawani, ti wọn ni awọn fẹẹ lọọ ko wọn ni adugbo naa, alọ wọn lawọn eeyan n ri, ẹnikan ki i ri abọ wọn, afi bii ọtalenirinwo ẹja ti wọn lawọn n lọọ jagun niluu awọn igere, alọ lawọn eeyan yoo ri, ẹnikan ko ni i ri abọ wọn. Tabi ẹyin ti gbọ pe wọn jẹ Emir tabi ọba Fulani kan ni gbogbo adugbo naa ri ndan? Nibẹrẹ pẹpẹ, ko sẹni kan ti i weri ni gbogbo adugbo yii, ko si si ọba musulumi kan ninu awọn ọba wọn. Gbogbo agbara ti ẹ ri ti awọn Fulani n lo lagbegbe naa lasiko yii, awọn oyinbo lo gbe e le wọn lọwọ, ki i ṣe pe wọn jagun gba a, tabi pe Jihaadi Uthman Dan Fodio kankan ni. Awọn yii gan-an ni wọn da awọn ọmọ ogun Dan Fodio duro, itosi ọdọ wọn ni Jihaadi pin si, ṣugbọn ko wọ ilu wọn rara, wọn le Fulani danu ni tiwọn ni.

Ni 1900, nigba ti wọn fẹẹ bẹrẹ ijọba oyinbo ti wọn pe ni Northern Nigeria, Lord Lugard ati awọn oyinbo to ran an wa ṣepade, wọn ni ko si bi wọn yoo ṣe jẹ ko jẹ ijọba Eko, iyẹn Lagos Colony, ni yoo maa paṣẹ Odo Ọya, iyẹn River Niger, nitori tẹlẹtẹlẹ, ijọba Eko lo n kọnturoolu, awọn ni wọn n ṣe akoso lati Eko titi wọ ẹnu River Niger yii, iyẹn ni pe labẹ Eko ni Lokoja ati gbogbo agbegbe rẹ pata wa. Lugard lo sọ pe oun ko le jẹ ko jẹ ijọba Eko ni yoo maa paṣẹ foun, nitori awọn ti oun ti mọ, ti wọn ko si gba tawọn ni wọn wa nibẹ, oun naa fẹẹ da nijọba toun ni. Wọn waa ni bi eyi ba ri bẹẹ, a jẹ pe gbogbo agbegbe River Niger lọtun-un ati losi, wọn yoo kuku fi i si akoso ẹni kan, akoso naa si bọ si abẹ Northern Nigeria, nitori wọn ni River Niger yii pọ si ilẹ Hausa ju bo ti pọ si ilẹ Yoruba lọ.

Titi di asiko ti mo n wi yii, abẹ akoso Yoruba ni Lokoja wa, bi awọn eeyan ṣe n pe e ni “Ilu Oke Ọja”, bẹẹ lawọn mi-in n pe e ni “Ilu Oko ẹja” nitori nibẹ ni wọn ti n ri ẹja nla nla pa, nitori odo River Niger to wa nibẹ. Ọdun 1900 ni ijọba ibẹ ati ti Benue Plateau ṣẹṣẹ bọ si abẹ awọn ijọba North, to si di tawọn Hausa. Loootọ, oyinbo ti kọkọ fi ibẹ ṣe ibudo wọn, ti wọn da ileewe ati ṣọọṣi silẹ, to jẹ ibẹ ni Lugard ti gba awọn ṣọja akọkọ, sibẹ, wọn ko ti i si labẹ akoso Northern Nigeria daadaa. Eyi lawọn mi-in ko mọ, ti wọn ṣe n ro pe awọn Hausa ni ṣọja akọkọ ni Naijiria. Awọn Hausa kọ o, awọn Yoruba ati Tiv, awọn ara Benue, Niger, Kogi, Plateau titi de Taraba ni wọn kọkọ ṣe ṣọja nilẹ yii, ki i ṣe awọn Hausa rara. Lẹyin ti oyinbo fi awọn ara Benue ati Plateau yii si abẹ Northern Nigeria lawọn Fulani too ribi wọle si ọdọ wọn.

Ọrọ naa di ija gidi nigba awọn oloṣelu, iyẹn nigba ti ijọba bọ si ọwọ awọn eeyan wa. Awọn Sardauna ni tawọn ni Benue-Plateau, ṣugbọn awọn yẹn lawọn ki i ṣe Hausa, iran baba awọn ko si foribalẹ fun Fulani ri. Sardauna lo agbara oṣelu, agbara ṣọja, ati awọn ọlọpaa lati tẹ ori wọn ba. O ko ogun lọ si gbogbo agbegbe naa, o si fi ṣọja pa wọn nipakupa. Awọn Fulani ti wọn ti tọrọ ilẹ, ti wọn n gbe agbegbe ibẹ, ti wọn n sin maaluu wọn jẹẹjẹ bẹrẹ si i gbeja awọn Sardauna, wọn ni awọn lawọn ni ilẹ gbogbo ni North. Lati igba naa ni ija laarin awọn Fulani ati awọn ara agbegbe yii ti bẹrẹ titi doni. Iyẹn lo ṣe jẹ pe ẹni to ba gba Fulani si adugbo rẹ fẹẹ pa agbegbe naa run ni. Ẹ ma dan an wo.

(7471)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.