Gomina Amosun ati Oshiomhole sọko ọrọ sira wọn nitori oṣelu ipinlẹ Ogun

Spread the love

Alaga ẹgbẹ APC lapapọ, Adams Oshiomhole, lo kọkọ sọko ọrọ ranṣẹ si Gomina ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun. Ọsẹ to kọja yii ni Oshiomhole sọ nipa Amosun pe fagidijaye apaṣẹ ni.
O ni gomina to fa ogoji eeyan kalẹ latọwọ ara ẹ pe ki wọn dipo oṣelu mu ti tako ofin idibo ilẹ wa.
Ọrọ yii ni Amosun naa fesi si latọwọ kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Ogun, Ọtunba Dayọ Adenẹyẹ, pe Oshiomhole toun naa di alaga nipasẹ ilana fifakalẹ, ko ni ootọ ọrọ kan lẹnu, bẹẹ ni ko mọ bi wọn ṣe n ṣe nnkan letoleto, ko si yẹ lẹni to yẹ ko maa sọ pe oun fa eeyan kalẹ lati dupo oṣelu.
Oko ọrọ ti wọn n sọ sira wọn yii bẹrẹ latigba ti gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ naa ti sọ pe Dapọ Abiọdun ni ẹni ti yoo ṣoju APC ninu idibo 2019, eyi to tako Adekunle Akinlade ti Amosun fa kalẹ.
Amosun ni loootọ lo jẹ pe ilana fifa ọmọ oye kalẹ loun kọkọ fẹẹ lo fun Akinlade, ṣugbọn nigba ti wọn ni ilana pamari ni kawọn lọ, iyẹn naa loun tẹle, ko si yẹ ki Oshiomhole tun maa waa sọ isọkusọ pe oun fẹẹ fagidi gbe ẹni ti kinni naa ko tọ si debẹ.
Atẹjade yii ṣalaye pe Oshimohole loun ko gba esi idibo to kede Akinlade wọle, nitori ki i ṣe igbimọ amuṣẹṣe lati Abuja lo kede rẹ. O ni to ba jẹ eyi ni alaga APC naa fẹẹ tẹle, ko yẹ ko gba esi idibo abẹle ipinlẹ Eko naa wọle rara, nitori ki i ṣe igbimọ amuṣẹṣe naa lo kede Sanwo-olu ti wọn lo bori l’Ekoo.
Wọn ni bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki ko ṣe, abi nitori ‘Baba sọ pe, Cappo di tutti, iyẹn ọga to n dari ipinlẹ Eko ni Oshiomhole ko ṣe le sọrọ, to waa n fẹnu sọrọ kọrọ nipinlẹ Ogun nibi.
Amosun lawọn ṣa fẹ ki gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun mọ pe eletekete ni Adams Oshiomhole, ki gbogbo ọmọ Ogun si tete mọ eyi nipa ọkunrin kukuru naa, ki wọn ma faaye gba a lati ba nnkan jẹ nipinlẹ yii rara.

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.