Gomina Ahmed gbe eto isuna 2019 kalẹ nile igbimọ aṣofin

Spread the love

Lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Gomina Abdulfatah Ahmed ti ipinlẹ Kwara yoo gbe eto iṣuna ọdun 2019 kalẹ nile igbimọ aṣofin lati buwọ lu.

Bakan naa ni eto pataki ni iranti abẹnugan akọkọ ile igbimọ aṣofin Kwara, Oloogbe Shehu Usman, yoo waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ bi atẹjade ti akọwe iroyin fun abẹnugan ile naa, Ọgbẹni Abdul Rahman Sanni, gbe jade, aago mọkanla aarọ ni eto naa yoo bẹrẹ.

Ṣaaju ni Ahmed ti kọwe ranṣẹ sile igbimọ naa lati gba a lalejo lọjọ yii. Nibi to ti sọ pe ni imurasilẹ fun iṣejọba ọdun 2019, ijọba oun ti pari gbogbo eto iṣuna ọdun naa, toun si ti ṣetan lati gbe e kalẹ niwaju awọn aṣofin lati gbe e yẹwo.Lẹta ọhun ni Igbakeji Abẹnugan ile, Mathew Ọkẹdare, ka sita lasiko wọn.

 

Bakan naa ni atẹjade ọhun rọ awọn ẹbi, ara ati ọrẹ Oloogbe Usman lati pejọ sile igbimọ naa ni Ọjọruu, Wẹsidee, ti wọn yoo ṣeto pataki lati fi ṣẹyẹ fun abẹnugan akọkọ nipinlẹ Kwara to papoda naa.

Ọnarebu  Hassan Oyeleke to jẹ Adari eto ile igbimọ naa sọ pe ijokoo pataki tawọn fẹẹ ṣe fun oloogbe yii ṣe pataki nitori ipa to ti ko ninu iṣẹ aṣofin lorilẹ-ede Naijiria.

Sẹnẹtọ Shehu Usman ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin Kwara laarin ọdun 1979-1983, oun lo ṣoju ẹkun Lafiagi labẹ asia ẹgbẹ oṣelu National Party of Nigeria (NPN), nigba naa lọhun-un. Ọjọ Aje, Mọnde, to kọja lo jade laye, ti wọn si ti sin oku rẹ nilana Musulumi ni ilu rẹ, Lafiagi.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.