Gomina Ahmed fofin de iwọde ati ikede ita gbangba …Awọn araalu tako igbesẹ naa

Spread the love

Ọsẹ to kọja yii ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed, fofin de ipade ipolongo ibo ati ikede ita gbangba kaakiri ipinlẹ Kwara, lati fopin si rogbodiyan to n bẹ silẹ.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro wọn, Tunde Aṣhaolu, gbe sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ẹgbẹ naa ni o jẹ ọna lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu, ati lati faaye gba alaafia kaakiri ipinlẹ Kwara.

 

Ṣe laipẹ yii lawọn janduku kan kọlu agboole Olori ile aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki, ni Agbaji, niluu Ilọrin, nibi ti wọn ti ba ọpọlọpọ dukia jẹ. Mọto to n lọ bii aadọta atawọn patako ipolongo Saraki to wa ni gbogbo agbegbe naa ni wọn bajẹ patapata.

Lẹyin ọjọ keji lawọn janduku mi-in tun da rogbodiyan silẹ lagbegbe Ode Aafa-Nda, nibi ti ẹnikan ti ba iṣẹlẹ naa lọ.

Eyi mu ki Gomina Ahmed pe ipade pajawiri lori eto aabo, o si gbe ikọ kan kalẹ lati tubọ mu ki aabo ilu gbopọn si i lasiko ipolongo ibo to n lọ lọwọ.

Yatọ si eyi, gomina naa paṣẹ pe ko gbọdọ si iwọde oṣelu kankan mọ kaakiri ipinlẹ Kwara. Eleyii lo ni yoo mu alaafia jọba.

Ṣugbọn awọn araalu ti tako igbesẹ naa pẹlu bi wọn ṣe ni ko si bi awọn yoo ṣe mọ erongba ati ohun ti awọn oludije ati ẹgbẹ oṣelu ni fun awọn bi wọn ko ba jade lati polongo.

Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara ni igbesẹ naa jẹ ọna lati pa awọn alatako lẹnu mọ.

Ṣugbọn ẹgbẹ PDP ti ni igbesẹ ti gomina gbe dara, ati pe o ba awọn lara mu.

 

Ẹgbẹ kan ti ki i ṣe ti ijọba, Kwara Must Change (KMC), ni ọkan lara ẹtọ araalu labẹ ofin ni lati ṣe ẹgbẹ, ati lati le rin kaakiri lasiko to wu wọn. Nitori naa, ijọba ko le loun fofin de wọn.

Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Yusuf Ọlatunji to jẹ adari ẹgbẹ gbe sita, o ni ofin fun gbogbo eeyan lẹtọọ lati le rin, nitori naa, ko si ẹnikan tabi ijọba kan to le gba ẹtọ naa.

 

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.