Gomina Ahmed ba ẹbi asofin Kwara, Funkẹ Adedoyin, ti aisan jẹjẹrẹ pa kẹdun

Spread the love

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ba mọlebi, ọrẹ ati ojulumọ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to n ṣoju ipinlẹ Kwara ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnarebu Funkẹ Adedoyin, kẹdun iku to pa ọkan ninu wọn. Lọsan-an ọjọ Eti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni wọn ni obinrin naa dakẹ sileewosan kan niluu Abuja lẹni ọdun mẹrinlelaaadọta.

Adedoyin lo ti fi asiko kan ṣiṣẹ gẹgẹ bii minisita keji feto ilera labẹ ijọba Oluṣẹgun Ọbasanjọ.

Obinrin naa ni wọn sọ pe aisan jẹjẹrẹ ti n ba finra lati ọdun 2016, Ẹnikan to sun mọ mọlẹbi oloogbe yii sọ pe aṣofin ọhun lọọ ṣe iṣẹ-abẹ jẹjẹrẹ ni nnkan bii ọdun meji sẹyin, ọpo igba lo si maa n lọ si oke-okun fun itọju. Akọroyin wa gbọ pe ara rẹ ti n ya diẹdiẹ ko too di pe aisan naa tun ṣadeede pada si i lara ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin, eyi to mu un lọ si oke-okun fun itọju. Ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja lo dagbere faye, niluu Abuja.

Ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe naa, Ọmọọbabinrin Ọmọlọla Olubayọ, ẹni to fi idi iku aṣofin naa mulẹ, sọ pe Funkẹ lọọ ṣayẹwo ara rẹ loke okun ni.

Awọn mọlẹbi rẹ ni wọn ko ti i tufọ iku rẹ fun baba to bi i lọmọ, iyẹn Oloye Samuel Adedoyin.

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed, ti ba ẹbi oloogbe naa kẹdun. O ṣapejuwe Funkẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ ipinlẹ naa to fakọyọ julọ.

Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin rẹ, Abdulwahab Ọba, fi sita l’ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, o ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bii ẹni to ni itara lati sin awọn araalu rẹ, to si nifẹẹ lati mu igbega ba ẹkun to n ṣoju lọkan. A ri i gbọ pe Adedoyin tun ti n palẹmọ lati tun dije-dupo pada sile igbimọ aṣoju-ṣofin naa lẹẹkan si i, koda, wọn lo ti n lẹ posita rẹ kaakiri ko too di pe o ọlọjọ de. Oun lo n ṣoju ẹkun Irẹpọdun/Oke-Ẹrọ/Isin/Ekiti, nile-igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.