Gomina Ahmed ati Sẹnetọ Ibrahim yoo jọ dije fun ipo sẹnetọ

Spread the love

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed, ti saa rẹ yoo pari l’oṣu karun-un, ọdun to n bọ, ni yoo koju Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Ariwa Kwara, Rafiu Ibrahim, lati dupo ẹkun naa lọdun 2019.

Ṣe lọsẹ to kọja ni Ahmed kede erongba rẹ lati dupo sẹnetọ ni ẹkun idibo naa.

Ṣugbọn Sẹnetọ Ibrahim Rafiu naa ti  fifẹ han lati pada sile igbimọ aṣofin-agba l’Abuja lọdun to n bọ. Eyi tumọ si pe oun awọn mejeeji ni yoo jọ maa koju ara wọn ninu idibo abẹle to maa waye laipẹ yii.

ALAROYE gbọ pe awọn ara ẹkun idibo Kwara South ti ni Sẹnetọ Rafiu Ibrahim ni awọn nifẹẹ si lati dupo lẹẹkan si i, eleyii yoo si jẹ ko nira fun Gomina Ahmed lati gba tikẹẹti ọhun lasiko idibo abẹle.

Bo tilẹ jẹ pe ohun ta a gbọ ni pe igbakeji adari awọn oṣiṣẹ lọfiisi Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki, iyẹn Ọnarebu Peter Makanjuọla, naa ti fifẹ han lati dupo yii kan naa, ṣugbọn pẹlu awọn agba nidii oṣelu meji to n ja si ipo yii, o ṣee ṣe ki o jawọ ninu erongba rẹ.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.