Gomina Abdulrahman fa awọn ọmọ ilẹ Turkey ti wọn bọ lọwọ awọn ajinigbe le aṣoju ilẹ wọn lọwọ

Spread the love

Lẹyin ọjọ mẹfa ti wọn lo lahaamọ awọn to ji wọn gbe, awọn ọmọ ilẹ Turkey mẹrin kan ti wọn ji gbe nijọba ibilẹ Edu, nipinlẹ Kwara, ti gba ominira. Gomina Abdulrahman Abdulrasaq si ti fa awọn eeyan naa le aṣoju ilẹ Turkey lorilẹ-ede Naijiria lọwọ niluu Abuja lọjọ Ẹti, Furaaide, ọsẹ to kọja yii.

Abdulrahman ni inu ijọba ipinlẹ Kwara dun pẹlu bi awọn agbofinro ṣe ṣiṣẹ takun-takun, ti wọn si ri awọn oyinbo ọhun gba pada lọwọ awọn to ji wọn gbe, lai farapa.

O nijọba yoo tubọ mu ki ofin to n gbogun ti iwa ijinigbe gbopọn si i, lati le dẹkun iṣẹlẹ naa nipinlẹ Kwara. O ke si awọn araalu lati maa ṣọra lagbegbe wọn, ki wọn si tete maa fi to awọn agbofinro leti nigbakuugba ti wọn ba kẹẹfin awọn ajeji atawọn ti irin ẹsẹ wọn ko mọ.

Labule Gbale, nijọba ibilẹ Edu, lawọn ajinigbe ti ji awọn ara Turkey mẹrin naa gbe nibi ti wọn ti n gbafẹ. Awọn ti wọn ji gbe ọhun ni: Yasin Colak, Senerapal, Ergun Yurdakul ati Seyit Keklik.

Awon omo ile Turkey ti won bọ lahaamọ ajinigbe

Awọn ọlọpaa atawọn fijilante ilu ni wọn jọ pawọ-pọ lati tọpinpin awọn eeyan naa de ibi ti wọn ti gba wọn silẹ labule Gbugbu.

Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa, niluu Ilọrin, Ọga ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Kayọde Ẹgbẹtokun, ni latigba tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lawọn ko ti loju oorun, awọn ajinigbe naa lawọn n lepa lojoojumọ. O fi kun un pe ikọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, awọn to n gbogun tiwa idigunjale, awọn ẹgbẹ darandaran, Miyyeti Allah atawọn fijilante lawọn jọ ṣiṣẹ naa.

O ni ọwọ tẹ ọkan lara awọn ajinigbe naa laarin ọsẹ tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ pẹlu ibọn AK47 kan labule Gbugbu, nibi tawọn afurasi naa farapamọ si.

Ọga ọlọpaa naa ni ọwọ tun pada tẹ awọn mẹta mi-in ati ẹni to n dunaa-dura lori owo irapada ọgọrun-un miliọnu kan Naira ti wọn fẹẹ gba.

O ni nigba tawọn agbofinro ya bo wọn, ṣe lawọn ẹgbẹ wọn yooku ti wọn jọ n ṣiṣẹ laabi naa sa lọ, ti wọn si fi awọn ti wọn ji gbe naa silẹ si ibudo wọn.

Ni nnkan bii aago meje ku iṣẹju mẹẹẹdogun alẹ ọjọ Ẹti lawọn oyinbo naa de olu ileeṣẹ ọlọpaa. Bi wọn ṣe de lawọn eleto ilera nibẹ ti ṣe itọju wọn.

Adari oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Alhaji Aminu Adisa Logun, ati akọwe iroyin fun gomina, Rafiu Ajakaye, pẹlu awọn alaṣẹ ijọba mi-in ni wọn waa tẹwọ gba awọn mẹrẹẹrin ni olu ileeṣẹ ọlọpaa.

Ẹgbẹtokun ni ko si owo irapada kankan tawọn san fawọn ajinigbe naa

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.