Gboyega Oyetọla, kaabọ

Spread the love

Oriire Gboyega Isiaka Oyetọla ni gomina wa tuntun l’Ọṣun lati oni lọ. kan ni fun gbogbo ọmọ ipinlẹ yii, ati gbogbo Yoruba pata. Oriire ibẹ naa si ni pe o ṣoju wa, wọn ko ṣe e lẹyin wa. Ọpọlọpọ wa lo ri ibẹrẹ ijọba Alaaji Raufu Arẹgbẹṣọla ti wọn ko ri ipari rẹ, ṣugbọn awa ri ibẹrẹ ijọba Arẹgbẹ, a ri ipari rẹ, a si tun ri ibẹrẹ ijọba tuntun mi-in, adura ni ka gba ki Ọlọrun jẹ ki asiko Gomina Oyetọla dun, ko si tu gbogbo wa lara. Ki a rowo na, ki a ri ọna gbe e gba, ki nnkan wa gbogbo si dara ju tatẹyinwa lọ. Gomina Oyetọla gbọdọ mọ pe oun ki i ṣe gomina APC, tabi gomina awọn kan ninu ẹgbẹ naa, gomina ipinlẹ Ọṣun lapapọ ni. Ohun to maa n pa ọpọ awọn oloṣelu ni pe nigba ti wọn ba depo, ija ti wọn ja lati de ipo naa pẹlu awọn ẹgbẹ alatako ni wọn yoo maa ro: bo ba jẹ ọmọ APC ni, o le loun ko ni i ba awọn to ba jẹ PDP ṣe, bo si jẹ PDP ni o le loun ko ni i ba awọn ti wọn ba jẹ APC ṣe. Eleyii ki i jẹ ki ilu ni ilọsiwaju, nitori gomina naa ko ni i roju-raaye ṣe ohun to yẹ ko ṣe. Amọ bi gomina kan ba wa, to n ṣiṣẹ fun gbogbo ilu lapapọ, ti ko ya awọn kan sọtọ pe wọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oun, gbogbo ipinlẹ naa pata ni yoo fẹran rẹ, koda awọn ti wọn ki i ṣe ọmọ adugbo rẹ yoo maa fi tirẹ juwe bi wọn ba ri gomina wọn to n ṣe palapala kan. Nitori bẹẹ, Oyetọla to gbajọba yii, gbogbo ọmọ Ọṣun jakejado ni ko ṣiṣẹ fun. Ki gomina wa idagbasoke, iṣẹ ti ko ba si owo rẹ nilẹ, ti ko si ni i le pari, ko ma dawọ le e. Akọkọ ni lati wa ounjẹ fun awọn eeyan yii, ọna ti yoo si fi wa owo ounjẹ ni lati ṣeto iṣẹ ti awọn ọdọ le ṣe. Bi iṣẹ ba wa, owo yoo wa. Nigba ti owo ba de, a oo mọ ohun to yẹ ka fi i ṣe. Eeyan ki i ṣe ju ara rẹ lọ, ki Gomina Oyetọla ma ṣe ju ohun ti apa awọn ara Ọṣun ba ka lọ. Ko gbọdọ ranro o, bẹẹ ni ko gbọdọ fi oro yaro, nitori ka fi oro yaro ki i jẹ ki oro tan o. Alaafia lo ba wa, alaafia naa ni ko fi ṣejọba rẹ. Bo ba fi alaafia ṣejọba, awọn ọta rẹ ti ko fẹran rẹ bayii yoo pada waa fẹran rẹ ni. Ọlọrun yoo fun Gboyega Oyetọla ṣe. Igba rẹ yoo tu gbogbo Ọṣun lara. Nnkan wa yoo daa ju bayii lọ l’Ọṣun lasiko Oyetọla.

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.