Gbogbo yin n wo Wasiu Ayinde bayii, ẹ o sọrọ o

Spread the love

Bi eeyan kan ba ni iṣẹ kan lọwọ ti ko ba ni itẹlọrun nibẹ, ẹtẹ ati abuku ni yoo gbẹyin fun un. Ko si ipo giga kan ti ẹda le wa, ko si si ipo kekere ti eeyan le wa, itẹlọrun ni baba. Ṣugbọn bi ẹ ba  ri ẹni ti wọn fi jẹ ọba, to tun n wẹ ọṣẹ awure, aintẹlọrun ni, alaṣeju si ni pẹlu, bẹẹ ẹni to ba ṣe aṣeju yoo tẹ gbẹyin ni. Iyẹn ni ti ọkunrin olorin ti wọn n pe ni Wasiu Ayinde yii. Ohun ti ko dara ni pe gbogbo ẹyin ti ẹ jẹ araalu, gbogbo ẹyin ti ẹ fẹran orin rẹ, gbogbo yin lẹ n ri i nigba to n lọ sigbo anu bayii, ẹ ko si pe e ki ẹ ba a sọrọ, nigba to ba ṣẹlẹ, ti awọn oloṣelu to n sare lẹyin wọn yii ba yẹ igi nla mọ ọn lẹyin, yoo ṣoro ki ẹ too pariwo pe ki wọn fi i silẹ o. Lati ilẹ Naijiria titi de origun mẹrẹẹrin agbaye ni wọn ti ri olorin Fuji yii to n bu Gomina Ambọde, to n pe e ni were, to n pe awọn ti foro le e, ati awọn ọrọ alufanṣa mi-in bẹẹ yẹn. Asiko yii laraalu ṣẹṣẹ mọ pe gbogbo orin ti Wasiu n kọ, to n pe lagbaja kan ni ki wọn dibo fun, tamẹdu kan ni ki wọn dibo fun, o fi n tan awọn eeyan jẹ ni, owo ti oun yoo gba nibẹ lo n tori rẹ kaakiri. Ọlọrun kuku ṣe e bayii, oun funra ẹ lo sọ pe oun ko ri jẹ ninu ijọba Ambọde, bo ba jẹ pe o ri jẹ nibẹ ni, oun ni yoo kọkọ ko irinṣẹ rẹ sita, ti yoo maa ni ki gbogbo Eko dibo fun un, nitori yoo ṣe daadaa fun wọn, oun f’Ọlọrun ṣẹri, oun fi anọbi le e. Aṣe ki i ṣe nitori ifẹ ọmọ Yoruba tabi araalu, nitori apo ara tirẹ ni. Ọkunrin yii naa lo lọ si Oṣogbo laipẹ yii to n ṣepe fun ẹni to ba dibo fun PDP, ko si wo ti pe ọpọ awọn ololufẹ oun mi-in yoo wa ti yoo jẹ ẹgbẹ PDP ni wọn n ṣe. Nigba ti o ba jokoo si ibi kan ti o n bu odidi gomina to wa ni ipo, bii igba ti eeyan fẹẹ fi ọwọ ara rẹ tu gbogbo ohun to fi ọjọ aye rẹ ṣe ka ni, nitori awọn oloṣelu wọnyi ko kọ kilẹ mọ ni aila, ko si na wọn ni iṣẹju kan lati ba gbogbo ohun ti ẹda ba ko jọ jẹ. Wasiu Ayinde n gbe ninu ile gilaasi, o n ṣere okuta, ṣe ko mọ pe bi awọn ti oun n ba ṣe ba sọ okuta lẹẹkan, ile gilaasi oun yoo bajẹ ni. Ẹ n wo o nisinyii ẹ ko sọrọ o, ẹni to ba moju rẹ ko kilọ gidi fun un.

(189)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.