Gbogbo ọna lawọn ọlọpaa n wa lati kogbo si mi lapo-Saraki

Spread the love

Ninu esi rẹ si awọn ẹsun yii,Senetọ Bukọla Saraki ti ni kawọn araalu dagunla si ohun tileeṣẹ ọlọpaa n sọ naa.O ni gbogbo ọna l’ọga ọlọpaa n wa lati ba oun lorukọ jẹ.

Saraki, ninu atẹjade kan to tọwọ oludamọran rẹ nipa eto iroyin, Yusuf Ọlaniyọnu, jade sọ pe nitori boun ṣe pe e ko waa ṣalaye tẹnu rẹ nile igbimọ lori iṣẹlẹ iṣekupani to waye nipinlẹ Benue ati lawọn ipinlẹ kan lorilẹ-ede Naijiria, pẹlu idaamu ti wọn ko ba Senetọ Dino Malaye, lawọn ọlọpaa ti n wa gbogbo ọna lati wa wahala soun lẹsẹ.

“Mo fẹẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ko si bi mo ṣe le maa ba awọn adigunjale ṣe papọ lati maa kogun ja awọn araalu mi. Nigba ti iṣẹlẹ idigunjale Ọffa ṣẹlẹ, emi ni akọkọ laarin awọn to ga ju nipo oṣelu to kọkọ ṣabẹwo sibẹ, loju ẹsẹ nibẹ laaafin kabiyesi ni mo ti pe Ọga Ọlọpaa, Idris Ibrahim lori foonu lati ṣeto aabo ni ibamu pẹlu ibeere awọn araalu.

“Gbogbo yin lẹ tun maa ranti pe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu to kọja ni mo ta ile igbimo aṣofin lolobo lori igbesẹ ti ọga ọlọpaa naa n gbe lati fa orukọ mi wọ ọrọ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan tawọn ọlọpaa ko nipinlẹ Kwara, ṣugbọn nigba ti wọn ri i pe iyẹn ko ṣiṣẹ ni wọn tun fẹẹ lo iṣẹlẹ idigunjale Ọffa lati lọ ọ mọ mi lọrun.

“Gẹgẹ bi ẹni to n bọwọ fun ofin nigba ti ipe ileeṣẹ ọlọpaa ba tẹ mi lọwọ maa yọju si wọn lai fi akoko ṣofo rara.”

 

(63)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.