Gbogbo ọmọ Ibadan ṣadaro Aminatu Abiọdun, Iyalode Ibadan to jade laye

Spread the love

A fi bii igba ti ẹru n ba awọn eeyan lati tufọ iku iyalode ilẹ Ibadan, Alhaja Aminat Abiọdun. Nigba ti ahesọ iroyin ọhun kọkọ lu sita pe obinrin naa ti jẹ Olọrun nipe, awọn oniroyin bẹrẹ si i pe awọn to sun mọ ọn, ṣugbọn ko si ẹni to fidi iroyin naa mulẹ titi dori awọn ijoye akẹgbẹ iya naa laafin Olubadan, afigba ti ọkan ninu awọn oniroyin pe mọlẹbi ẹ kan ni Idi-Arẹrẹ, iyẹn lagboole ti wọn ti gbe Alhaja Aminat niyawo, oun lo ṣẹṣẹ waasọ pe iya agba ẹni odun mẹrinlelaaadorun-un naa ti teri gbaṣọ.

 

Lati aarọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja lo ti ku, ṣugbọn o to aago mejila ọsan ọjọ naa ki awọn eeyan too mọ nigboro, awọn ọmọ oloogbe ti tọju oku pamọ si yara ìṣòkú-lọ́jọ̀ to wa nileewosan UCH, n’Ibadan, paapaa nigba naa.

 

Ni nnkan bii aago marun-un kọja iṣẹju mẹrindinlọgbọn (5:26), irọlẹ ọjọ naa ni wọn sinku Alhaja Aminat sinu ọgba ile ẹ to wa laduugbo Ikọlaba, n’Ibadan, nilana musulumi, labẹ akooso Sheik Abdulganiyy Agbọtọmọkekere ti i ṣe Imaamu agba ilẹ Ibadan.

 

Ṣaaju, iyẹn ni nnkan bii aago mẹta ọsan Sannde ọhun nijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣeto akanṣe adura fun oloogbe naa ninu ọgba ileeṣẹ igbohun-safẹfẹ wọn ti gbogbo aye mọ si Ile-Akede, l’Orita Baṣọrun, n’Ibadan.

 

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi lo gba gbogbo awọn eeyan pataki lawujọ to kopa nibi eto ọhun lalejo.

Ajimọbi pẹlu diẹ ninu awọn igbimọ ijọba ẹ ti kọkọ lọọ ṣabẹwo ibanikẹdun si idile oloogbe ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ Satide ti iya naa jade laye. Alhaja Aṣagidigbi to jẹ akọbi Iyalode lo gba wọn lalejo nile oloogbe.

 

Gomina ṣapejuwe agba ijoye to oloogbe yii gẹgẹ bii ẹni ti iru ẹ ṣọwọn to bẹẹ ti yoo ṣoro diẹ lati ri ẹni di alafo to fi silẹ lawujọ, nitori iya rere lo jẹ fun gbogbo ọmọ ilẹ Ibadan ati nilẹ Yoruba lapapọ.

 

Ninu iwaasu rẹ nibi adura ikẹyin fun oloogbe, Sheik Agbọtọmọkekere rọ gbogbo eeyan lati gbele aye ṣe rere, nitori iku n bọ waa fopin si gbogbo kirakita ẹda laye, ati pe ohun teeyan ba gbele aye ṣe lỌlọrun yoo fi ṣedajọ oluwarẹ bo dọrun.

Iwọnyi ni diẹ ninu ohun ti awọn ẹbi sọ ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu akọroyin wa:

 

 

Ọmọọbabinrin Adeyọọla‎ Adeyẹmọ (ọmọ Ọba Adeyẹmọ Ọpẹrinde Kin-in-ni, Olubadan nigba kan ri)

 

Ipa ribiribi ti mama ko inu aye mi pọ, ṣugbọn eyi ti mi o le gbagbe lae ni tọdun 2003 ti wọn mu mi lọ siluu Abuja. Ẹnikan wa ta a ti jọ sọrọ nipa kọntiraati kan ni Abuja lọdun naa. Ẹni yẹn ò waa fẹẹ gbeṣẹ yẹn fun mi mọ, iṣẹ olowo nla si ni. Bi mo ṣe sọ fun Mama ni wọn ni ki n niṣo nibẹ. Baalu la wọ lọ. Ọkan ninu awọn otẹẹli to daa ju niluu Abuja la sun. Àtowó baalu, atowo otẹẹli, atowo ounjẹ ta a jẹ, Mama lo san gbogbo ẹ, yara ọtọọtọ ni wọn si gba fun awa mejeeji. Mọlẹbi kan naa ni wa. Iya ni wọn jẹ si mi, ‘Mama mi, Mama mi’ naa ni mo si n pe wọn. ‘Baba mi, Baba mi’ lawọn naa maa n pe baba mi nitori bii ọmọ lawọn naa jẹ si baba mi. Igba ti baba mi maa jọba, Alhaji Sikiru Ayinde Barryster la fẹẹ pe lati waa kọrin, ṣugbọn Barrister loun ko ni i le wa nitori oun ni ere e ṣe niluu kan lagbegbe Ondo, oun si ti gbowo ere lọwọ wọn. Mama sọ fun Barrister pe ṣebi ọmọ Ibadan loun naa. Wọn ni ti ko ba ti le waa ṣere yẹn, ko gbagbe pe ọmọ Ibadan loun, ko si gbọdọ wa s’Ibadan waa ṣere mọ. Nitori Mama ni Barry ṣe waa ṣere fun Olubadan lọdun yẹn.

Igbesi aye rere ni Mama gbe, eeyan ko kan le tẹ ọmọ araye lọrun ni. Mama ti ṣe iwọn tiwọn.

 

 

Hammed Razak Lawal (Ọmọọmọ Oloogbe)

Ọdọ Iya ni gbogbo wa gbe nigba ta a wa ni kekere. Nnkan to maa n jọ mi loju ninu ọrọ wọn ni pe Iya ki i na owo ti ko tuntun, owo agánrán ni wọn maa n na ni gbogbo igba ṣaa. Wọn ni itẹriba pupọ. Wọn si jẹ oloootọ eeyan. Bi wọn ba ṣe sọrọ naa lẹ maa ba a.

 

 

Ọlajumọkẹ Mustapha (ọmọọmọ)

 

Wọn nifẹẹ ọmọ. Awọn ni wọn tọju wa ni kekere. Lẹyin ta a kuro lọdọ wọn tan, ti eyikeyii ninu wa  ba de ọdọ Mama, wọn aa tun maa kẹ ẹ bii ọmọ tuntun ni. Wọn aa maa beere pe ṣe nnkan kan o ṣe ẹ, ṣe ko si wahala kankan? Ki lo de to o jinna si mi, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ko si bi iṣoro ti eeyan le gbe de ọdọ Mama ṣe le tobi to ti wọn ko ni i yanju ẹ.

 

Ọdun mẹtalelaaadọrun-un ni Alhaja Aminat lo loke eepẹ, to si fi ọpọ ọmọ ati ọmọọmọ saye. O ku ọsẹ meji ko pe ọdun mẹrinlelaaadọrun-un niku mu un lọ, nitori lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun 2018 yii, ni iba ṣe ayajọ ọjọọbi ẹ fun tọdun yii.

 

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.