Gbogbo igba ta a ba ti n lasepọ lọkọ mi maa n fidio rẹ-Taye

Spread the love

Ọpọ awọn ero to wa ni kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Ọwọ, ni wọn ya ẹnu ti wọn ko si lee pa a de bọrọ lasiko ti iyaale ile kan, Abilekọ Taye Ogunmọdẹde, n royin itu ti ọkọ rẹ n pa nigbakuugba ti wọn ba ti n lajọṣepọ.

 

Abilekọ ọhun lo mu ẹjọ ọkọ rẹ, Ọgbẹni Wande Ogunmọdẹde, wa si kootu naa, o ni ki wọn tu igbeyawo ọdun mejila to wa laarin awọn ka.

Lara ẹsun to fi kan olujẹjọ naa ni lilu gbogbo igba, fifi iku halẹ mọ ẹmi oun, owu jijẹ ati kikuna lati ṣe ojuṣe rẹ lori oun atawọn ọmọ toun bi fun un.

 

Eyi to ya awọn eeyan lẹnu ju ninu ẹsun to fi kan ọkọ rẹ ni bo ṣe lo maa n fi ọgbọn ka fidio awọn mejeeji silẹ nigbakuugba tawọn ba ti n ṣere ifẹ.

 

Taye ni alaye ti ọkọ oun ṣe lori fidio yii ni pe oun fẹẹ maa wo o lati mu nnkan ọmọkunrin oun le nigbakuugba ti ibalopọ ba ti n wu oun i ṣe ni.

 

Olupẹjọ naa jẹwọ ninu ẹjọ to ro ni kootu pe lati igba ti oun ti ṣalabaapade kọndọọmu ti wọn ti lo ri ninu palọ wọn loun ko ti fẹẹ maa fun ọkọ oun ni kinni ṣe mọ, eyi to si n dija silẹ laarin awọn mejeeji.

 

Obinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ọhun waa pari ọrọ rẹ pe ki kootu tu awọn ka, nitori oun ko fẹẹ ku iku aitọjọ latari lilu gbogbo igba ti olujẹjọ maa n lu oun.

 

Wande ni tirẹ juwe iyawo rẹ bii ẹnikan to gboye ijinlẹ ninu agbere ṣiṣe, o ni ohun to n dun oun ju ninu iwa olupẹjọ ni bo ṣe maa n gbe ounjẹ to tọ si oun lọ fun ọkunrin mi-in jẹ nita.

 

Awọn igbesẹ to sọ pe oun n gbe boya obinrin naa le jawọ ninu iwa to n hu yii lo ni ko so eso rere, leyii to si maa n fa ija ajaku akata laarin awọn mejeeji.

 

Ninu idajọ Alagba Dapọ Adebayọ to jẹ aarẹ kootu naa, o ni ki awọn mejeeji maa lọ lọtọọtọ, nitori o ti han gbangba ninu ẹjọ ti wọn ro pe ko si ifẹ mọ laarin wọn.

 

Aarẹ kootu ọhun paṣẹ pe ki meji ninu awọn ọmọ mẹta ti wọn bi wa lọdọ baba wọn, ki ẹni kan to ku si maa gbe pelu olupẹjọ.

 

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.