Gbogbo awọn oloṣelu nla nla ninu ẹgbẹ oṣelu APC lo pejọ si gbọngan…

Spread the love

Gbogbo awọn oloṣelu nla nla ninu ẹgbẹ oṣelu APC lo pejọ si gbọngan ti wọn n pe ni Banquet Hall, nile ijọba, niluu Abuja, ni Sannde, ọjọ Aiku, ọsẹ yii, nibi ti Aarẹ orileede yii, Muhammadu Buahri, ti fi erongba rẹ lati tun dupo aarẹ Naijiria han, to si fi iwe eto ipolongo rẹ to pe ni ‘Next Level’ han fun awọn eeyan naa ati awọn ohun to ni lọkan lati ṣe, to si rọ awọn ọmọ ilẹ yii lati dibo fun un.

Nigba to n ṣalaye awọn nnkan to ni lọkan lati ṣe yatọ si eyi to ti ṣe tẹlẹ, Aarẹ Buhari ṣalaye pe, ‘Ọdun mẹrin mi-in ta a fẹẹ mu yii ṣe pataki fun orileede wa. Ilẹ wa yoo ṣepinu boya lati ṣe agbekalẹ Naijiria tuntun, tabi ki a tun pada si oko aarọ, nibi ti awọn perete ti n jẹ anfaani ohun to yẹ ko jẹ fun gbogbo eeyan’

O ṣalaye pe ijọba oun ko ni i kaaarẹ nipa pipese awọn ohun amayederun, bẹẹ latunṣe yoo ba eto ọrọ aje, gbigbogun ti awọn alajangbila to n da ilẹ wa laamu ko ni i gbẹyin ninu ohun ti ijọba oun yoo mu ni pataki. Buhari ni ijọba oun yoo tun gbogun ti iwa ajẹbanu ju boun ṣe n ṣe tẹlẹ lọ. O ṣalaye pe ọna meji naa lo pin si, o ni yala ki awọn ọmọ Naijiria tun dibo yan oun ki oun le tẹsiwaju ninu gbigbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu, tabi ki wọn gba orileede yii laaaye lati tun pada si ẹsẹ aarọ.

Buhari  tako ohun ti awọn eeyan n sọ kiri pe ijọba oun ko ṣiṣẹ, o ni iṣẹ idagbasoke bii igba (200), ni ijọba oun ti gbekalẹ ti awọn araalu si n jẹ anfaani wọn lọna kan tabi omi-in titi di asiko yii.

O ṣeleri lati ri i pe awọn lo awọn ọrọ ati ohun alumọọni ilẹ wa fun anfaani awọn araalu. O ni, ‘Bi a ti n fi ipilẹ ijọba alaafia ati orileede ti o nitẹsiwaju lelẹ, a mọ pe iṣẹ ṣi pọ fun wa lati ṣe. Ipele ti o kan ninu iṣẹ wa bayii ni gbigbaju mọ ipese iṣẹ kaakiri gbogbo agbegbe ni orileede yii. Bakan naaa ni a maa ṣe imugbooro si eto ti ijọba ti ṣagbekalẹ rẹ ti wọn n ṣe, N-Power, leyii ti a tun maa nawo si imọ ẹrọ, eto ọgbin, bẹẹ lawọn olokoowo kereje kereje yoo ni anfaani si ẹyawo, ipese iṣẹ fun awọn bii miliọnu mẹẹẹdogun ko ni i gbẹyin.

“A maa ṣe atunṣe si awọn ileewe bii ẹgbẹrun mẹwaa, bẹẹ la si maa ṣe koriya fun awọn olukọ wa lati kọ awọn ọmọ ni iṣẹ ọwọ, imọ sayẹnsi, imọ ẹrọ, leyii ti wọn yoo maa lo oriṣiiriṣii ohun eelo ikẹkọọ igbalode lati ṣe bẹẹ.”

Bakan naa ni Aarẹ Buhari gba awọn oloṣelu nimọran pe ki wọn ṣọra lasiko ipolongo, ki wọn ma dana sun ilẹ Naijiria, Buhari ni, “Mi o ṣalaimo pe oni ni eto ipolongo fun ile igbimọ aṣofin ati ti aarẹ bẹrẹ, mo fẹẹ rọ awọn olupolongo ibo ki wọn ṣe pẹlẹpẹlẹ, ki wọn si gba alaafia laaye. A ko ni ilẹ tabi orileede mi-in, nitori eyi, ẹ ma ṣe jẹ ki a dana sun un nitori ọrọ oṣelu.”

Bakan naa ni igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Atiku Abubakar, naa bẹrẹ ipolongo ibo rẹ ni Sannde, ọjọ Aiku, ọsẹ yii, kan naa, nibi to ti ṣalaye awọn ohun to ni lọkan lati ṣe bi wọn ba dibo yan an gẹgẹ bii aarẹ orileede Naijiria.  Nibẹ lo si ti ṣafihan iwe alakalẹ awọn eto rẹ ti yoo lo fun ipolongo ati ti yoo ṣe amulo lẹyin ti wọn ba dibo yan an tan, eyi to pe akọle rẹ ni “Ẹ jẹ ka jọ tun Naijiria ṣe, ko le ṣiṣẹ lẹẹkan si i’’

Ọna mẹta ni Atiku pin awọn koko iṣẹ to fẹẹ ṣe nile ijọba ti wọn ba dibo yan an si. Akọkọ ni lati wa iṣọkan Naijiria, ẹẹkeji ni lati ṣeto aabo to gbopọn fun araalu, nigba ti ikẹta iṣẹ to fẹẹ ṣe jẹ lati pese ọrọ rẹpẹtẹ. O ja si pe IṢỌKAN, AABO ati ỌRỌ RẸPẸTẸ ni awọn koko mẹta ti ijọba Atiku yoo da le lori.

Atiku ṣeleri pe oun yoo sọ ibi ifọpo ilẹ wa mẹrẹẹrin ta a ni ti ko ṣe daadaa di ti alaadani ti oun ba di aarẹ. O ṣalaye pe agbara kaka ni awọn ileeṣẹ ifọpo ta a ni yii fi n ṣe ida mẹwaa iṣẹ to yẹ ki wọn ṣe. Bakan naa lo ṣeleri pe lati le ṣe igbelarugẹ ileeṣẹ to n pese epo ati atẹgun idana, o ni awọn yoo gbe ẹka kan ninu ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo nilẹ yii, NNPC, fun awọn alaadani, lati le ri i pe akoyawọ wa lori ọrọ ileeṣẹ yii. Bẹẹ lawọn yoo ṣe eto idokoowo ti ko ni i ga ni lara, ti  yoo mu awọn eeyan waa ba awọn dowo pọ ni awọn ẹka ileeṣẹ yii.

Eyi nikan kọ, igbakeji aarẹ yii tun sọ pe awọn ohun eelo igbalode lawọn yoo maa lo lati maa ṣọ awọn ọpa epo wa, bẹẹ lawọn yoo ṣe amulo awọn eeyan agbegbe ti wọn ti n fọpo yii fun eto aabo paapaa.

Igbakeji aarẹ tẹlẹ yii ni awọn ijọba ibilẹ yoo wa lominira gẹgẹ bii ẹka ijọba, bẹẹ nijọba yoo maa ran wọn lọwọ lati ri i pe wọn ṣeto to yẹ fawọn araalu.

Lara awọn ileri ti Atiku tun ṣe faraalu ti wọn ba dibo yan an ni ọrọ atunto ilẹ wa. Ọkunrin naa ni awọn yoo maa pin ọrọ Naijiria ni ọna tuntun ti awọn ba ṣẹṣẹ ṣe agbekalẹ rẹ, leyii ti ko ni i mu irẹjẹ lọwọ mọ. O ni oriṣiiriṣii ọna to le mu owo wa sapo ijọba lawọn yoo gbe eto ọrọ aje ilẹ wa gba, awọn iṣẹ akanṣe ti yoo si ṣe anfaani fawọn araalu nijọba oun yoo gun le.

Ni ti awọn ọdọ ati awọn obinrin, o ni gbogbo awọn idiwọ ti ko jẹ ki awọn obinrin ni aṣeyọri to yẹ, boya nigba ti wọn wa ni ọdọmọbinrin abi nigba ti wọn ti dagba nijọba oun yoo mu kuro ti wọn ba yan oun sipo. O ni o jẹ ohun to ṣe ni laaanu pe bo tilẹ jẹ pe obinrin ko ida bii aadọta ninu eeyan ilẹ yii, sibẹ, wọn ko ro wọn lagbara nipa eto inawo, oṣelu, ọrọ aje ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ilẹ yii ati loke okun.

Atiku ni awọn yoo pese eto ẹyawo alabọọde pataki  ti yoo wa fun awọn ọdọ ati awọn obinrin. Bẹẹ lo ni awọn yoo ṣe agbekalẹ ile-ẹjọ pataki kan ti yoo maa ri si lilo obinrin nilokulo tabi ifiya jẹ obinrin lọna yoowu ko ri. Eleyii ko ni i yọ ifipabanilopọ ati ibalopọ lọna ti ko tẹ obinrin lọrun silẹ. O ṣeleri eto ẹkọ imọ sayẹnsi, imọ ẹrọ, iṣiro ati iṣẹ ọwọ fun awọn obinrin. O fi kun un pe awọn ọdọ ni ẹlẹka jẹka, boya awọn to ti kawe jade, awọn to kọṣẹ ọwọ ati awọn to n ṣowo ni ijọba oun yoo mojuto.

Siwaju si i, o ṣeleri pe awọn yoo ṣe afikun awọn obinrin ninu eto ijọba, ọrọ aje ati oṣelu. O ni, “A maa ṣe afikun awọn ọdọ ati obinrin ti wọn n gba si iṣẹ.”

Ọpọlọpọ awọn oloṣelu to jẹ ọmọ ẹgbẹ mejeeji yii lo peju sibẹ

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.