Gbese biliọnu mẹtadinlọgọsan-an: Mo fa Fayoṣe le Ọlọrun lọwọ—Fayẹmi Ekiti ko jẹ iru owo bẹẹ, awawi ni Fayẹmi n ṣe—Fayoṣe

Spread the love

Bo ṣe ku bii oṣu kan ki Ọmọwe Kayọde Fayẹmi gbajọba nipinlẹ Ekiti, ija ọrọ ti bẹ silẹ laarin oun ati Gomina Ayọdele Fayoṣe latari gbese biliọnu mẹtadinlọgọsan-an (177,000,000,000) Naira ti Fayẹmi ni Ekiti jẹ lọwọlọwọ.

Lopin ọsẹ to kọja ni Fayẹmi sọrọ naa lasiko to n ṣagbeyẹwo abọ iṣẹ igbimọ to n ṣeto igbajọba rẹ lọwọ Fayoṣe.

Gẹgẹ bi Fayẹmi ṣe sọ, o loun fa Fayoṣe le Ọlọrun lọwọ lori bo ṣe na owo Ekiti lẹnu ọdun mẹrin to lo. Eyi waye lẹyin iroyin atẹjade ileeṣẹ to n mojuto gbese nilẹ yii, nibi ti wọn ti ni gbese Ekiti gbera lati biliọnu mejidinlogun Naira ti Fayoṣe ba lọdun 2014, si biliọnu mẹtadinlọgọsan-an.

Gomina ti wọn dibo yan naa ni gbese yii tun yatọ si owo awọn

oṣiṣẹ, awọn oṣiṣẹ-fẹyinti atawọn agbaṣẹṣe. Eyi lo jẹ ko pe fun

ofin ti yoo de igbajọba, eyi ti yoo ṣalaye awọn nnkan tijọba to n lọ

gbọdọ ṣe ko too gbejọba silẹ gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe ni Ghana,

Kenya, South Afrika atawọn orilẹ-ede mi-in.

O fi kun un pe awọn nnkan kan wa tawọn n beere lọwọ ijọba Fayoṣe tawọn ko ti i ri, awọn si nireti pe wọn yoo ṣe e ko too di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu to n bọ, ti saa naa yoo pari. O waa ni oun mọ pe ko si bi ijọba ko ṣe ni i jẹ gbese, gbogbo afojusun oun si ni bi awọn eeyan Ekiti yoo ṣe jẹgbadun ijọba toun ni gbogbo ọna.

Ṣugbọn ijọba Ekiti ti fesi si ẹsun yii, wọn si ṣapejuwe ọrọ naa bii ọna lati wa awawi fun ijọba to ti kuna lati ibẹrẹ. Lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta ni oluranlọwọ Gomina Ayọdele Fayoṣe, Lere Ọlayinka, sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ ti Fayẹmi n sọ.

Ọlayinka ni ijọba apapọ gan-an lọ mọ-ọn-mọ kuna lati san owo to le bi biliọnu mejidinlogoji (38.8b) Naira to yẹ ki wọn fun Ekiti. O ni owo yii nijọba gbojule lati sanwo awọn oṣiṣẹ, ṣugbọn ijọba apapọ ti n gbero lati da a duro di oṣu kọkanla, ọdun yii, ti Fayẹmi yoo ti wa nipo.

O fi kun un pe awọn gba Fayẹmi nimọran lati lo owo naa fun owo oṣu awọn oṣiṣẹ, eyi ti ijọba Fayoṣe ṣeleri lati lo o fun.

Oluranlọwọ gomina naa waa sọ pe ko si bi ̀Fayẹmi ṣe le ṣe awọn nnkan ti Fayoṣe ṣe laarin ọdun mẹrin, ati pe Fayoṣe pe ileeṣẹ to n mujuto gbese nija lati sọ ibi ti Ekiti ti yawo to pọ to bẹẹ.

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.